Kà nípa ohun tó yẹ kí o ṣe bí o kò bá rí oorun sùn lálẹ́

Aworan ẹni to dubulẹ lori ibusun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oorun dara fun ara. Yatọ si pe isinmi lo jẹ, o tun wa fun alaafia ọpọlọ ati gbogbo ara pẹlu.

Ṣugbọn fun awọn idi kan, awọn eeyan mi-in ki i ri oorun gidi sun tilẹ yoo fi mọ.

Bi wọn ṣe n ka igi àjà inu yara wọn ni wọn yoo maa yilọ yibọ titi ti ilẹ yoo fi mọ. Eyi ko daa fun ilera wọn.

Ki lo wa n fa aile sun dọkan tabi ai tiẹ ri oorun sun rara?

Ki si ni awọn ohun ti o le ṣe bi o ba n koju iṣoro yii?

Iroyin ti BBC ko jọ pẹlu imọran awọn dokita yii yoo ran ọ lọwọ lati mọ ohun to yẹ ni ṣiṣe ati awọn eyi ti o gbọdọ yago fun bi o ba n koju ailesun ti oloyinbo n pe ni Insomnia.

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nínú ọpọlọ tó ń fa àìlè sùn?

Aworan ọpọlọ ti wọn fi ọwọ aago si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dokita Faith Orchard, olukọ nipa irori eeyan lati Yunifasiti Sussex, ṣalaye fun BBC pe awọn nnkan meji kan wa to le mu ki eeyan sun ko si tun ji pada.

Akọkọ ni awọn ẹya ara to n mu ki oorun kun eeyan(sleep hormones) ikeji ni ki o maa ṣe eeyan bii pe ki onitohun sun.

Dokita Orchard ṣalaye pe nnkan meji yii gbọdọ ṣiṣẹ pọ bi eeyan yoo ba sun asunwọra oorun.

"Bi wọn ko ba ṣiṣẹ pọ, fun apẹẹrẹ, boya eeyan sun oorun ọsan abi ti irọlẹ, awọn ẹya ara meeji naa le maa ṣiṣẹ pọ, oorun yẹn si le ma wa daadaa.

"Nnkan mi-in to le ma jẹ ki eeyan sun ni wahala ti eeyan ti fi ara ṣe to si ti kojọ pọ sinu ara'' (stress)

Bakan naa ni Ọjọgbọn to kẹkọọ nipa oorun, Colin Espie, lati Oxford Yunifasiti, ṣalaye pe, " bi kinni kan ba wa lọkan rẹ, ti o gbe sọkan, ọpọlọ rẹ yoo maa sọ fun ara pe ẹni yii fẹẹ ronu lori ohun to wa lọkan rẹ yẹn, oorun ko si ni i wa mọ"

Ọjọgbọn Espie sọ pe ọjọ ori naa le fa aile sun daadaa.

O ni bi ara ṣe n dagba ni oorun yoo maa dinku lara rẹ pẹlu ọjọ ori to n lekun si i.

Kí ló yẹ kí o ṣe bí o kò bá lè sùn?

Aworan ọkunrin to fi ọwọ kan le aago orii tabili to si gbe ọwọ keji siwaju ori rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ṣee ṣe ki o ti sun tẹlẹ ki o si deede taji loru, ki oorun ma kun ọ mọ.

Ọjọgbọn Espie ṣalaye pe oorun maa n dinku lọwọ igba ti ilẹ ba n mọ lọ laaarọ.

"Nigba yẹn ni wa a maa ro o lọkan rẹ pe boya 'mo ṣi le ri oorun yii sun diẹ si i.

"Ọkan lara awọn ohun ti oorun ko si fẹ niyẹn, oorun lo maa n wa funra rẹ, lo fi jẹ pe bi o ba ronu rẹ ju bẹẹ lọ, o ṣi maa laju silẹ lai sun naa ni. "

Dokita Orchard sọ pe ọna to rọrun lati maa fi ri oorun sun deede ni pe ki eeyan ri i pe aago toun n sun lalẹ ko yipada, asiko ti yoo si ji laaarọ naa ko yipada.

Bi apẹẹrẹ, to ba ṣe pe aago mẹsan-an alẹ lo fẹẹ maa sun, to o si fẹẹ maa ji laago mẹfa owurọ, ri i daju pe o duro ti akoko naa lai yi i pada.

Ikeji ni lati jẹ ki ọpọlọ mọ ibi ti eeyan n sun.

Gbiyanju lati ma ṣe maa rẹju lori aga, lọ sori ibusun.

Ma ṣe maa ṣiṣẹ lorii bẹẹdi rẹ pẹlu.

Dokita Orchard lo sọ bẹẹ.

Dokita Hare to fi kun ọna abayọ yii, sọ pe, "bi o ba ji ti o ko si le sun mọ, ma ṣe dide lati maa ṣe nnkan mi-in fun wakati kan tabi aabọ wakati, dubulẹ sibẹ.

Afi ti o ba mọ pe o ko fẹẹ sun oorun naa mó ni ki o dide."

Àwọn nǹkan mí-ìn tó lè fa àìrí oorun sùn

Bi obinrin ko ba ṣe nnkan oṣu mọ

Dokita Hare ṣalaye pe aiṣe nnkan oṣu mọ le mu adinku ba igba ti obinrin yoo fi sun.

Ọti mimu

Dokita Orchard sọ pe ọti mimu le yi asiko ti eeyan yoo lo ko too sun pada, o si le jẹ ki eeyan maa jitọ lori.

O ṣee ṣe ko mu ki eeyan sun ju, ko si maa han oorun pẹlu.

Áwọn oniṣẹ alẹ

Dokita Hare gba awọn to ba n ṣiṣẹ alẹ mọju nimọran lati sun lasiko to ba ṣee ṣe fun wọn, ti ko ni i pa iṣẹ lara.