Trump fẹ́ẹ́ fagilé àjọ olùrànlọ́wọ́ àgbáyé,USAID

Aworan awọn olufẹhonuhan ti ko fẹ ki wọn fagile ajọ USAID. Iwaju Olu ileeṣẹ naa ni wọn tẹ pẹpẹ ifẹhonuhan naa si l'America.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Maria Zaccaro
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Aworan ajọ United States Agency for International Development (USAID) to han lorii ẹrọ ibaraẹnisọrọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kinni kan to tun n mu ibẹru ba awọn eeyan bayii ni ti ajọ oluranlọwọUSAID, iyẹn United States Agency for International Development, ti iroyin sọ pe Aarẹ Donald Trump ati oludamọran agba rẹ, Elon Musk, fẹẹ fagile.

Ero ọpọ eeyan ni pe bi Trump ba fi le fagile USAID, ipa aburu ni yoo ni kaakiri agbaye.

Ajọ USAID yii lo ti n ṣeto iranwọ, oju aanu fun awọn eeyan, ati gbigbe awọn eto aanu kalẹ lọfẹẹ lati ibẹrẹ ọdun 1960. Ajọ naa n ṣe eyi lorukọ ijọba ilu America.

Ṣugbọn lọsẹ to kọja yii, Elon Musk sọ pe ni erongba ati wọgile ajọ to n pese iranwọ naa.

Loju opo X to jẹ ti Elon Musk, o pe ajọ naa ni ''ajọ aburu'', " ileeṣẹ ọdaran" ati ileeṣẹ ọlọtẹ to n dibọn.

Bakan naa ni Aarẹ Trump sọ pe awọn eeyan ti arun ọpọlọ n da laamu lo n dari ajọ USAID, ti wọn si n ko owo nla sapo wọn lai jẹ pe ẹnikẹni ri wọn mu.

Ṣugbọn Trump ko darukọ awọn to n ba wi gan-an, ko si la ọrọ naa delẹ.

Ọrọ yii ti di ohun ti wọn n gba bi ẹni gba igba ọti lagbo oṣelu America bayii, awọn eeyan si n sọ nipa rẹ kaakiri.

Kí ló dé tí USAID fi ń mú àríyànjiyàn wá lágbò òṣèlú ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aarẹ Trump ti jẹ ko di mimọ, pe America ni nnkan akọkọ tioun yoo maa gbọ na koun too ronu ati nawo fun ilẹ okeere kankan.

O ni gbogbo owo ti yoo ba jade lọ silẹ okeere, gbọdọ wa ni ibamu pẹlu ọrọ akọmọna oun ti i ṣe 'America First', iyẹn America ni akọkọ.

Bẹẹ si ni Akọwe ipinlẹ rẹ, Marco Rubio, ti sọ pe bi dọla kan yoo ba jade kuro l'America, aridaju gbọdọ wa pe yoo ṣe anfaani fun America ni.

Awọn anfaani ti yoo mu America ni aabo to daa si i, ti yoo ro o lagbara ti yoo si bu kun ọrọ̀ rẹ lo pe e.

" Fun idi eyi, bo ṣe loun yoo ri si awọn ajọ ijọba apapọ yii tumọ si pe o n mu ileri to ṣe ṣẹ ni o" Thomas Gift, Oludasilẹ UCL Centre lori oṣelu America lo sọ bẹẹ.

O fi kun un pe awọn to gbe eto 'Make America Great Again' kalẹ, ri USAID bii ohun ti ko mu ilọsiwaju wa to si ti pẹ ju bo ṣe yẹ lọ.

O ni ajọ naa n fi America si ipari, o si n mu idagbasoke ba awọn orilẹ aye yooku, bẹẹ lo si n gbọn owo awọn ẹni ẹlẹni to n fi dọla sanwo ori danu.

Gifts sọ pe ọrọ America lo jẹ Trump logun ju ti ibikibi laye lọ. O ni Aarẹ Trump fẹẹ igbayegbadun fun awọn ọmọ America, idi niyẹn to fi f'America ṣaaju ibikibi.

O ni bi wọn ba fagile USAID, ilọsiwaju nla ni yoo mu ba awọn ọmọ oniluu l'America.

Èrò àwọn ọmọ olùdìbò

Iwadii fi han pe awọn oludibo l'America faramọ ki wọn din owo ti America n na silẹ okeere ku.

Bi eyi ba ri bẹẹ, o ṣee ṣe ki wọn faramọ wiwọgile USAID.

Ṣugbọn Ọmọwe Paul Clist, lati Yunifasiti East Anglia, sọ pe awọn eeyan maa n ri owo tijọba n na fun ilẹ okeere bii pe o pọ ju bo ṣe yẹ lọ.

O ni bi wọn ba fagile USAID, gbogbo owo ti wọn ti na lori awọn eto wọn to n lọ lọwọ yoo ja si ofo ni.

USAID ni iṣuna $40bn (£32.25bn), to fi diẹ ju idaji iye to fẹẹ na fun ilẹ okeere lọ.

Ni 2022 orilẹede America ya $70.3bn sọtọ, eyi to jẹ ida kan owo to fẹẹ na fun ilẹ okeere, gegẹ bi akọsilẹ ijọba ṣe sọ.

Lapapọ, lati oṣu Kẹwaa ọdun 2023, si oṣu Kẹsan-an ọdun 2024, ijọba America na $6.75 trillion (£5.3 trillion), gẹgẹ bi akọsilẹ ibi ikowo si wọn ṣe fidi ẹ mulẹ.

Aarẹ Donald Trump ati Elon Musk.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Donald Trump ati Elon Musk. Musk lo wa nidii akoso bi ijọba yoo ṣe kunju oṣuwọn nipa inawo. ( Department of Government Efficiency(Doge), eyi to da lorii bi wọn yoo ṣe maa ṣọ owo ijọba na.

Kí ni USAID maá ń ṣe ?

  • Iṣẹ USAID ni:
  • Pinpin biliọnu iranlọwọ si awọn ajọ ti ki i ṣe ti ijọba, ajọ alaanu ati awọn ti wọn ko reti ere kankan lẹnu iṣẹ wọn, to jẹ iṣẹ aanu ati itọrẹ ni wọn n ṣe.
  • Fifi owo ṣe iranlọwọ fun awọn ti ogun n ja niluu wọn, pipese abẹrẹ ajẹsara nibi ti ajakalẹ arun ba ti n waye.
  • Wọn ni ileeṣẹ lorilẹede to ju ọgọta lọ, wọn si ni awọn oṣiṣẹ to le ni ẹgbẹrun mẹwaa.
Aworan awọn olufẹhonuhan ti ko fẹ ki wọn fagile ajọ USAID. Iwaju Olu ileeṣẹ naa ni wọn tẹ pẹpẹ ifẹhonuhan naa si l'America.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn olufẹhonuhan ti ko fẹ ki wọn fagile ajọ USAID. Iwaju Olu ileeṣẹ naa ni wọn tẹ pẹpẹ ifẹhonuhan naa si l'America.

Kí ló kàn?

Bi wọn yoo ba fagile USAID patapata, yoo gba ki wọn jokoo ipade lori rẹ na.

Ọkan lara awọn ohun ti ijọba Trump n ro ni pe boya ki wọn so ajọ yii mọ ẹka ijọba ipinlẹ.

Akọwe Rubio ti sọ pe pupọ ninu iṣẹ ti USAID n ṣe yoo maa tẹsiwaju, wọn yoo si jẹ lara ofin ilẹ America.

Bakan naa ni awọn aṣofin ọmọ ẹgbẹ Democratic ti sọ pe o lodi sofin lati fagile USAID.

Wọn ni igbesẹ ti yoo pa awọn alaini lara kaakiri agabye ni, yoo koba aabo awọn orilẹede, yoo si din ipa ti America n ni lara awọn ilu ku bi wọn ba fagile USAID.

Lọjọ Iṣẹgun, ajọ USAID kede pe awọn oṣiṣẹ awọn kaakiri agbaye yoo maa lọ fun isinmi lọjọ Ẹti ọsẹ yii, awọn to si wa nilẹ okeere yoo pada wa si America

Ajọ naa sọ pe awọn ti iṣẹ wọn jẹ ko ṣee ma ṣe nikan ni yoo ṣi maa ṣiṣẹ lọ.