Iléẹjọ́ dájọ́ ikú fún èèyàn márùn ún tó lu obìnrin kan pa lórí ẹ̀sùn pé àjẹ́ ni

Aworan ẹni ti wọn fi ma mu garri si lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileẹjọ kan niluu Kano ti dajọ wi pe ki wọn yẹgi fun eeyan marun un ti wọn ṣeku pa obinrin kan lọdun 2023 lori ẹsin pe ajẹ ni.

Awọn ọkunrin ti wọn dajọ iku fun yii ṣe ikọlu si oloogbe Dahare Abubakar ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin nigba to n ṣiṣẹ ninu oko rẹ.

Ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe ninu oko yii ni awọn ọkunrin marun un yii ti bẹrẹ si ni lu u ti wọn si n gun lọbẹ titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

Ẹbi oloogbe lo fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti tawọn agbofinro si fọwọ ofin mawọn ọkunrin marun un naa ni abule kan ti ko jina si ilu Kano.

Ẹjọ yii di nnkan ti ọpọ eeyan lori itakun ayelujara bẹrẹ si ni sọ nipa rẹ papaa julọ nipa bawọn eeyan to n gbe igberiko ni Naijiria ṣe n ṣeku pa awọn eeyan ti wọn n fẹsun kan wi pe ajẹ wọn.

Awọn eeyan to n fẹsun ajẹ kan awọn eeyan mii ko ni ẹri lati fidi ẹsun yii mulẹ, amọ, wọn maa n gbagbọ pe awọn ti wọn n pe ni ajẹ yii lo wa nibi iku ẹbi tabi eeyan wọn to ku.

Ọjọ ti wọn pa mama mi lọjọ to buru julọ laye fun mi - Ọmọ oloogbe

Nigba ti o n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Usman N''abba fidi rẹ mulẹ pe awijare ikọ olupẹjọ fẹsẹ mulẹ, o si mu ọgbọn dani.

Olupẹjọ Abba Sorondiki sọ pe o yẹ ki idajọ ri jẹ arikọgbọn fawọn eeyan to n fẹsun ajẹ kan awọn alaiṣẹ ti wọn si maa n ṣe idajọ ọwọ ara wọn.

Ile ẹjọ sọ pe awọn ọkunrin marun un yii lu arabinrin Abubakar pa lẹyin ti iyawo ọkan lara awọn ọkunrin naa, Abdulaziz Yahaya, to n ṣaisan loun la ala pe oloogbe naa n le oun kiri pẹlu ọbẹ lọwọ loju ala.

Lẹyin naa ni Yahaya ko awọn ọkunrin mii jọ ti wọn si jọ lu obinrin naa pa.

''A ti ri iru idajọ bayii ri, ṣugbọn igba akọkọ ree ti ile ẹjọ yoo dajọ iku fun eeyan marun un lori ẹsun ṣiṣe iku pa eeyan lori ẹsun pe wọn ni ajẹ,'' Sorondiki lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, ọmọ obinrin ti wọn ṣeku pa, Musa Yahaya, sọ pe ọjọ ti wọn pa mama oun lọjọ to buru julọ laye foun.

Amọ, Yahaya ni inu oun dun wi pe idajọ ododo waye lori iṣẹlẹ naa.

Ninu ọrọ tiẹ, agbẹjọro awọn ọkunrin marun un naa, Maáruf Yakasai, ni awọn ọkunrin naa n gbero lati pẹjọ kotẹmilọrun.

Ṣiṣe iku pa awọn ti ileẹjọ ti dajọ iku fun ko wọ pọ ni Naijiria, ọgba ẹwọn ni iru awọn eeyan ti maa n saba lo gbogbo ọjọ aye wọn.