Wo ìgbésẹ̀ mẹ́jọ láti gba ìwé ìrìnnà láì dé iléeṣẹ́ àjọ tó ń rí sí ìwọlé-wọ̀de

Àwòrán ìwé ìrìnnà

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àjọ tó ń rí sí ètò ìwọlé-wọ̀de ní Nàìjíríà, Nigeria Immigration Service, NIS ti kéde pé ètò gbígba ìwé ìrìnnà rẹ̀ láì dé ọ́fíìsì wọn ti bẹ̀rẹ̀ fáwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Yúróòpù.

Mínísítà fọ̀rọ̀ abẹ́lé ní Nàìjíríà, Olubunmi Tunji-ojo níní àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ìkànnnì X rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Keje, oṣù Kejì ọdún 2025 sọ pé ètò náà ti gbérasọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Ní oṣù Kẹwàá, ọdún 2024 ni Immigration ti kéde àwọn ìgbésẹ̀ tuntun tí èèyàn nílò láti fi gba ìwé ìrìnnà rẹ̀ láì dé ọ́fíìsì wọn.

Ìgbésẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí àjọ náà ṣe sọ yóò mú àdínkù bá bí àwọn èèyàn ṣe máa ń tò sí ọ́fíìsì rẹ̀ lásìkò tí wọ́n bá fẹ́ gba ìwé ìrìnnà, pàápàá fáwọn tó jẹ́ pé kìí ṣe pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fá gba ìwé ìrìnnà tuntun.

Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé tí èèyàn bá fẹ́ gba ìwé ìrìnnà, ònítọ̀hún kò ní nílò láti dé ọ́fíìsì wọn, orí ayélujára ni yóò ti ṣe gbogbo nǹkan tó nílò láti ṣe.

Bákan náà ni wọ́n yóò tún fi ìwé ìrìnnà náà ránṣẹ́ sí onítọ̀hún nígbà tó bá ti jáde.

Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ìwọlé-wọ̀de ṣe sọ lójú òpó X wọn, orílẹ̀ èdè Canada ni ìgbésẹ̀ náà yóò ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kìíní, oṣù Kọkànlá, ọdún 2024.

UK, USA àti Italy ni yóò tẹ̀lé ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Kọkànlá, kó tó wá kan àwọn tó ń gbé ní orílẹ̀ èdè Naijiria lọ́jọ́ kìíní, oṣù Kejìlá.

Tunji-Ojo ní ètò ti bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Yúróòpù báyìí.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Kí ni àwọn ìgbésẹ̀ tí èèyàn yóò tẹ̀lé?

Gẹ́gẹ́ bí fídíò tí NIS fi léde, èèyàn nílò láti kọ́kọ́ gba áàpù àjọ NIS sórí fóònù rẹ̀ látorí Play Store, App Store, Windows Store tàbí láti ojú òpó www.passport.immigration.gov.ng.

Lẹ́yìn tí ó bá gba áàpù náà tán ni èèyàn máa tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́jọ yìí:

  • Ìforúkọsílẹ̀: Ó máa nílò láti ṣe ìforúkọsílẹ̀ lórí áàpù náà pẹ̀lú ímeelì rẹ
  • Àyẹ̀wò: Ó máa ṣe àyẹ̀wò láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni ìwé ìrànnà rẹ ti tó láti pààrọ̀.
  • Fífi nọ́mbà ìdánimọ̀ sílẹ̀: Lẹ́yìn tí o bá ti ṣe àyẹ̀wò tán, ni o máa nílò láti fi nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN àti nọ́mbà ìwé ìrìnnà tí o fẹ́ pààrọ̀ sílẹ̀ lórí áàpù náà.
  • Àwọn ìwé ẹ̀rí: Ìgbésẹ̀ tó kàn ni láti fi àwọn sátìfíkéètì rẹ bíi ti ìwé ìgbà tí wọ́n bí ọ, ìwé ẹ̀rí ìjọba ìbílẹ̀ tí o ti wá àti káàdì nọ́mbà ìdánimọ̀ sórí áàpù náà.
  • Títẹ̀ka: Ohun tó kàn ni láti tẹ̀ka pẹ̀lú lílo ààyè ìtẹ̀ka lórí fóònù rẹ
  • Ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn nǹkan tí o ti kọ sórí áàpù náà fún ìgbà ìkẹyìn àti bíbuwọ́lùú pé wọ́n jẹ́ òótọ́.
  • Ìgbésẹ̀ owó sísan ló kàn, òun náà sì ni ìgbésẹ̀ tó kẹ́yìn láti fi gba ìwé ìrìnnà láì dé ọ́fíìsì àjọ tó ń rí sí ìwọlé-wọ̀de.
  • Lẹ́yìn èyí ni wà á fi gbogbo àwọn nǹkan tó ti kọ sílẹ̀ yìí ránṣẹ́ lórí ayélujára, tí wà á sì máa retí èsì láti ọ̀dọ̀ àjọ ọ̀hún.

Àdírẹ́sì tí o bá fi sílẹ̀ ní iléeṣẹ́ ìwọ́le-wọ̀de yóò fi ìwé ìrìnnà rẹ ránṣẹ́ sí.

NIS jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn tó bá fẹ́ gba ìwé ìrìnnà mìíràn ni ètò yìí ṣì wà fún, ní èyí tó túmọ̀ sí pé ẹni tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ gba ìwé ìrìnnà fún ìgbà àkọ́kọ́ ṣì nílò láti dé iléeṣẹ́ Immigration fún gbígba ìwé ìrìnnà wọn.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2