'Àwọn ọkọ, mọ̀lẹ́bí ló ń ṣokùnfà ikú ọ̀wọọ̀wọ́ àwọn obìnrin lọ́dọọdún'

Àkọlé fídíò, ‘Àwọn ọkọ, mọ̀lẹ́bí ló ń ṣokùnfà ikú ọ̀wọọ̀wọ́ àwọn obìnrin lọ́dọọdún’
'Àwọn ọkọ, mọ̀lẹ́bí ló ń ṣokùnfà ikú ọ̀wọọ̀wọ́ àwọn obìnrin lọ́dọọdún'

Ní wákàtí kọ̀ọ́kan, kò dín ní obìnrin mẹ́fà tí àwọn èèyàn ń pa. Àwọn èèyàn tó ń ṣekúpa àwọn obìnrin wọ̀nyí lè jẹ́ ọ̀rẹ́, olólùfẹ́ tàbí ẹni tó súnmọ́ wọn lọ́nà kan tabí òmíràn.

Gẹgẹ bi ajọ iṣọkan agbaye ṣe sọ, eyi tum si pe ni gbogbo iṣẹju mẹwaa-mẹwaa to n ro, ẹmi obinrin kan n lọ sii.

Ni ọdun 2023, awọn obinrin to ti balaga atawọn ọmọbinrin ti iye wọn jẹ ẹgbẹrun marundinlaadọrun (85, 000) ni awọn amokunṣika kan mọọmọ ṣekupa. Ninu wọn, ẹgbẹrun mọkanlelaadọta lo jẹ wi pe ọkọ tabi eeyan kan ninu mọlẹbi wọn lo ṣokunfa iku wọn.

Ninu gbogbo rogbodiyan yii, ilẹ adulawọ ni ọwọ iwa buruku yii gogo si julọ.