IBEDC sọ ilé ìwòsàn UCH sínú òkùnkùn birimù lórí gbèsè ₦495m, àwọn èèyàn gbarata

Ìta UCH

Oríṣun àwòrán, screenshot

Òdú ni ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn fásitì Ibadan, University College Hospital, UCH, Ibadan, kìí ṣe àìmọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ló gbàgbọ́ pé bí àìsàn bá dé ojú ẹ̀, tí wọ́n kò rí ìwòsàn ní àwọn ilé ìwòsàn mìíràn mọ́, UCH ni wọ́n máa ń dà á gbà.

Ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn ni pé ìrírí àwọn dókìtà àti onímọ̀ ìlera UCH lẹ́nu iṣẹ́ ìwòsàn ní Nàìjíríà, kò sí ilé ìwòsán mìíràn tó lè bá wọn forígbárí.

Ní ogúnjọ́, oṣù Kọkànlá ọdún 1957 ni wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ ilé ìwòsàn yìí, òhun sì ni ilé ìwòsàn olùkọ́ni àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà.

Àmọ́ níṣe ni àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ń kọminú lórí ipò tí ilé ìwòsàn UCH Ibadan wà báyìí lórí ọ̀rọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí ilé ìwòsàn náà ṣe ń bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ lórí gbèsè owó iná gọbọi tí wọ́n jẹ.

IBEDC já iná ilé ìwòsàn UCH lọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kẹta, ọdún 2024

Ilé ìwòsàn náà ní àwọn adarí rẹ̀ tó ti ṣe ìjọba kọjá ló ṣokùnfà gbèsè owó ₦328m tó wà lọ́rùn ilé ìwòsàn ọ̀hún.

Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, inú òkunkùn birimù birimù ni ilé ìwòsàn UCH wà.

Ìdí ni pé iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná ní ìlú Ibadan, Ibadan Electricity Distribution Company (IBEDC) ti já iná ilé ìwòsàn náà láti ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kẹta, ọdún 2024.

Àwọn ènìyàn tó bá iléeṣẹ́ ìròyìn DAILY POST sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ iná yìí ní ó jẹ́ ohun tó máa ń da omi tútù sí àwọn lọ́kàn lórí ọ̀rọ̀ iná yìí pẹ̀lú iye tí àwọn ènìyàn o’rilẹ̀ èdè ń pa lójúmọ́.

'Kìí ṣe ohun tuntun pé kò sí iná ní UCH'

Obìnrin kan tó fi ìlú Ibadan ṣe ibùjókòó ní àìsí iná ní ilé ìwòsàn UCH kìí ṣe ohun tuntun.

Arábìnrin náà ṣàlàyé pé ní ọ̀rọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná ló mú òun tètè gbé ọmọ òun kúrò ní ilé ìwòsàn náà, lọ sí ilé ìwòsàn aládàni ní ọdún tó kọjá.

Ó ní nínú oṣù Kẹsàn-án ni òun bímọ ní ìpínlẹ̀ Eko àmọ́ tí wọ́n ní kí òun máa lọ sí UCH nítorí ìpèníjà tí ọmọ òun ní.

Ó sọ pé ọmọ òun nílò láti gba ẹ̀jẹ̀, kó sì máa wà lábẹ́ iná ní gbogbo ìgbà ṣùgbọ́n kò sí iná ní ẹ̀ka tí ọmọ òun ti yẹ kó gba ìtọ́jú fún odidi ọjọ́ kan.

“Mo ní kí wọ́n dá wa sílẹ̀ láti máa lọ sílé nígbà tí kò sí iná mọ̀nàmọ́ná, mo sì gbé ọmọ mi lọ sí ilé ìwòsàn láti gba ìtọ́jú.

“Ó jẹ ohun ìbànújẹ́ fún mi pé irú nǹkan báyìí ṣì ń wáyé ní ọdún 2024, ó jẹ́ ohun tó burú gbáà.”

"Ilé ìwòsàn UCH gbọdọ̀ ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń fi owó tí wọ́n ń pa wọlé lójúmọ́ ṣe tí wọn kò fi rí owó iná san"

Ẹlòmíràn tó tún sọ̀rọ̀ ní ó yẹ kí ilé ìwòsàn UCH ṣàlàyé ohun tí wọ́n ń fi owó tí wọ́n ń pa wọlé lójúmọ́ ṣe tí wọn kò fi rí owó iná san.

Ó ní ó hàn gbangba pé ìwà àjẹbánu àwọn adarí ilé ìwòsàn náà ló fa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.

“Ìbéèrè tó yẹ ká máa bèrè ni pé kí ló dé tí wọ́n ń jẹ owó, kí ni wọ́n ń fi owó gọbọi tí àwọn èèyàn n san fún wọn ṣe?

Àwọn mìíràn tó tún sọ̀rọ̀ ní ó yẹ kí wọ́n ṣe ìwádìí ìdí tí ilé ìwòsàn náà fi ń jẹ iléeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná ni adurú owó tó pọ̀ bẹ́ẹ̀ àti pé àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn ní ẹjọ́ láti jẹ́.

Wọ́n gbàgbọ́ pé ìwà ìjẹkújẹ ló ṣokùnfà àìsí iná tó ń wáyé ní ilé ìwòsàn UCH.

Owó tí à ń pa kò tó láti yanjú àwọn gbèsè tó wà lọ́rùn wa – Agbẹnusọ UCH

Ẹ̀wẹ̀, agbẹnusọ ilé ìwòsàn UCH, Funmi Adetuyibi ní owó tí ilé ìwòsàn náà ń pa wọlé lóṣù kò tó nǹkan tí àwọn ń ná jáde ló fa gbèsè owọ iná náà.

Adetuyibi ní gbèsè owó iná ₦328m ni adarí ilé ìwòsàn náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Jesse Otegbayo bá nílẹ̀ nígbà tó gbapò rẹ̀ lọ́jọ́ Kìíní, oṣù Kẹta ọdún 2019.

Ó ní IBEDC ní gbèsè tí ilé ìwòsàn náà jẹ ti wọ ₦495m báyìí.

Ó ṣàlàyé pé kìí ṣe pé àwọn kìí san owó rárá ní oṣooṣù, pé àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn náà ń gbìyànjú láti fi owó tí wọ́n pa wọlé san-án.

“Mílíọ̀nù mẹ́rìnlá náírà la máa ń gbà gẹ́gẹ́ bí owó níná láti ọ̀dọ̀ ìjọba, gbogbo rẹ̀ náà sì la máa ń ná lórí omi, iná àtàwọn ohun èlò míì.

“A ti kọ lẹ́tà láti bèèrè fún ìrànlọ́wọ́, a ò kọ̀ tí a bá rí àwọn ènìyàn ràn wá lọ́wọ́, owọ tí à ń pa wọlé kò tó wa.”