Mohbad ló já ìbálé mi, n kò ní ṣàyẹ̀wò DNA fún ọmọ mi - Wunmi ìyáwò Mohbad

Oríṣun àwòrán, @_c33why_/INSTAGRAM
Níṣe ni ọ̀rọ̀ tún bá ìbòmíràn yọ lórí ọ̀rọ̀ ikú Mohbad tí ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́ lórí rẹ̀.
Wunmi, ìyàwó Ilerioluwa Oladimeji Aloba, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad ti yarí kanlẹ̀ pé òun kò ní ṣe àyẹ̀wò láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Mohbad ló ni ọmọ ọwọ́ òun, Liam.
Láti ìgbà tí Mohbad ti jáde láyé nínú oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 ni àwọn ènìyàn kan tó fi mọ́ bàbá Mohbad, Joseph Aloba ti ń pè fún àyẹ̀wò láti mọ bóyá Mohbad ló ni ọmọ tí òun àti ìyàwó rẹ̀, Wunmi bí fun lóòótọ́.
Ọ̀rọ̀ náà ló ti ń fa awuyewuye nítorí bàbá Mohbad ní òun kò ní sin òkú Mohbad lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá hú òkú rẹ̀ fún àyẹ̀wò àyàfi tí àwọn bá ṣe àyẹ̀wò DNA fún ọmọ rẹ̀.
Ṣáájú ni Wunmi ti sọ pé òun kò bẹ̀rù láti ṣe àyẹ̀wò DNA tí bàbá Mohbad bá ti ṣetán.
Ó ní kí bàbá Mohbad lọ gba àṣẹ láti ilé ẹjọ́ láti pa òun láṣẹ láti ṣe àyẹ̀wò náà fún ọmọ òun ṣùgbọ́n tí bàbá Mohbad kò ìtíì gba àṣẹ náà títí di àsìkò yìí.
"Èmi ni mo bí ọmọ mi, kò sí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fún mi láti ṣe àyẹ̀wò DNA àyàfi tó bá wù mí láti ṣe"
Àmọ́ Wunmi tún ti yí ohùn padà báyìí pé òun kò ní ṣe àyẹ̀wò náà mọ́ nítorí kò sí ẹni tó lè sọ fún òun láti ṣe àyẹ̀wò náà tí òun kò bá ṣetán.
Ó ní ọkọ òun tó ti di olóògbé nìkan ló ní àṣẹ láti ṣe àyẹ̀wò DNA fún ọmọ rẹ̀ tó bá jẹ́ pé ó ṣì wà láyé ni.
Ó sọ pé Mohbad lọ já ìbálé òun àti pé òun kò mọ ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ọkọ òun títí tó fi jáde, tí òun sì lè fi ògún rẹ̀ gbárí àmọ́ kò sí ẹni tó lè fi ipá mú òun láti ṣe DNA.
“Èmi ni mo bí ọmọ mi, kò sí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fún mi láti ṣe àyẹ̀wò DNA àyàfi tó bá wù mí láti ṣe.”
“Mi ò ní gbà kí wọ́n dójú lé ọmọ mi bíi ti bàbá rẹ̀.”
Wunmi ti ṣáájú fẹ̀sùn kan bàbá ọkọ rẹ̀ pé ó ń lépa ẹ̀mí òun nítorí tó fẹ́ gba ọmọ òun, Liam ṣùgbọ́n òun kò ní gbà nítorí òun ti ṣetán láti jà fún ọmọ náà.
Ó ní bàbá tó ń sọ pé òun fẹ́ ṣe àyẹ̀wò DNA kọ̀ láti lọ gba àṣẹ nílé ẹjọ́ láti jẹ́ kí àyẹ̀wò náà yá ní kíákíá.
Ó fẹ̀sùn kan bàbá Mohbad pé ó ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìdádúrò àyẹ̀wò náà kó fi parí ilé àti ilé ìjọsìn tó ń kọ́ lọ́wọ́ nítorí àwọn àǹfàní tó ń jẹ lórí ọ̀rọ̀ ọmọ rẹ̀.
Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àtẹ̀j;ade kan tó wà lórí ayélujára pé ẹ̀ṣẹ̀ tí òun rò pé òun ṣẹ bàbá ọkọ òun kò ju pé òun lọ sí ọ̀dọ̀ àgbà ọ̀jẹ̀ agbẹjọ́rò nnì, Femi Falana láti le gba ìdája òdodo lórí ikú ọkọ òun.

Oríṣun àwòrán, @_c33why_/INSTAGRAM
"Gbogbo ibi tí mo bá le tẹsẹ̀ bọ̀ láti wá ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọkọ mi ni mo ti ṣetán láti tẹsẹ̀ bọ̀ báyìí"
Wunmi tẹ̀síwájú pé nítorí òun rí bí Femi Falana ṣe dìde sí ẹjọ́ Timothy Adegoke títí tí wọ́n fi gba ìdájọ́ ni òun ṣe tọ agbẹjọ́rò náà lọ àmọ́ bàbá ọkọ òun lòdì sí ìgbésẹ̀ yìí.
Ó ní gbogbo nǹkan tí bàbá náà ti ń sọ nípa Mohbad ló jẹ́ irọ́ nítorí ọmọ dada ló jẹ́ sí àwọn òbí rẹ̀ nígbà tó wà láyé.
Ó tẹ̀síwájú pé gbogbo ìgbà ni òun fi máa ń sunkún ṣùgbọ́n òun ti gbọnra jìgì báyìí ní òun ti ṣara gírí láti jà fún ọmọ òun.
“Gbogbo ibi tí mo bá le tẹsẹ̀ bọ̀ láti wá ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọkọ mi ni mo ti ṣetán láti tẹsẹ̀ bọ̀ báyìí.
“Mi ò ní dákẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ọmọ mi mọ́, tí kìí bá ṣe ọmọ kékeré ni, gbogbo àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe fún mi lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kò sí ẹni tí yóò máa dan wò.
“Èmi nìkan ni òbí tí Liam ní báyìí, bàbá kò gba àṣẹ ilé ẹjọ́ láti ṣàyẹ̀wò DNA, ẹ bá mi bẹ bàbá Mohbad kó fi ọmọ mi lọ́rùn sílẹ̀.
“Mi ò kọ̀ kí ẹ̀mí bọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí àmọ́ ẹ má jẹ̀ ẹ́ kí nǹkankan ṣe ọmọ mi gbogbo abiyamọ ayé., gbogbo abiyamọ tòótọ́, ẹ gbà mí.”

Oríṣun àwòrán, @_c33why_/INSTAGRAM















