Princess ké gbàjarè, káfíntà tó fipà bá ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lò pọ̀ l'Ekoo di èrò ẹ̀wọ̀n

Aworan Damilola Adekoya (Princess)

Oríṣun àwòrán, Damilola Adekoya (Princess)/Instagram

Àkọlé àwòrán, Damilola Adekoya (Princess)
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile ẹjọ Majisireeti kan l'Ebute Meta, ipinlẹ Eko, ti paṣẹ pe ki ọkunrin kafinta kan ti wọn lo fipa ba ọmọ ọdun mẹsan-an lo pọ maa lọọ naju lọgba ẹwọn Kirikiri.

Atẹjade ti ajọ to n ri si ifiyajẹni labele ati ifipabanilopọ nipinlẹ Eko, Domestic and Sexual Violence Agency (DSVA) fi sita lọjọ Aiku, ṣalaye pe mọlẹbi ni Kafinta ati ọmọbinrin to fipa ba lo pọ.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, Ayobo, nipinlẹ Eko ni Kafinta ti wọn ko darukọ rẹ naa n gbe pẹlu ọmọ to ṣe erekere pẹlu rẹ.

Nipa bi ẹjọ naa ṣe de kootu, ajafẹtọọ ọmọniyan, Damilola Adekoya ti awọn eeyan mọ si Princess, lo fi iṣẹlẹ naa lede bo ṣe ṣẹlẹ.

Ninu fidio kan to wa lori ayelujara ni Princess ti n sunkun yọbọ nipa iṣẹlẹ yii, to si n bẹ awọn eeyan lati ba oun lọ si Ayobo.

O sọ ninu fidio naa pe Baba Micheal ni wọn mọ Kafinta naa si nile to n gbe lopopona Ademola.

Lẹyin fidio yii ni wọn fi ọwọ ofin gbe ọkunrin naa, to si foju bale-ẹjọ lọjọ Ẹti, ọjọ keje, oṣu Keji ọdun 2025.

Nigba to n dahun ibeere kootu, olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi.

Igbẹjọ mi-in di ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji, 2025.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Princess lo fi ẹsun biba ọmọbinrin to n gbe lọdọ rẹ ṣe erekere, kan Baba Ijesa, iyẹn oṣere tiata Yoruba ti orukọ rẹ gan-an n jẹ Lanre Omiyinka.

Ọdun 2022 ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Ọrọ naa de kootu, Adajọ sọ pe oṣere naa jẹbi ẹsun, wọn si ju Baba Ijesa si gbaga nibi to wa titi di asiko yii.