Ilẹ̀ ru ní China, èèyàn kan kú, 28 di àwátì

Oríṣun àwòrán, XINHUA/AP
O kere tan, eeyan kan padanu ẹmi, awọn mejidinlọgbọn (28) si di awati lẹyin iṣẹlẹ ilẹ ríru to waye ni Guusu-Iwọ-Oorun orilẹede China.
Gẹgẹ bi ẹka iroyin China ṣe ro o, iṣẹlẹ naa waye ni Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Keji ọdun 2025.
Abule Jinping, lagbegbe Sichuan, la gbọ ilẹ ti ru, ni nnkan bii aago mejila ọsan ku iṣẹju mẹwaa.
Ọpọ ile lo parẹ si abẹ ilẹ riru naa bi wọn ṣe wi, bẹẹ ni awọn eeyan si wa nibẹ ti wọn ko ti i ri wọn yọ.
Aarẹ China, Xi Jinping, ti paṣẹ pe ki wọn ṣe gbogbo iṣẹ idoola ẹmi to ba yẹ nibẹ, ki wọn si gbe awọn to ha si abẹ ilẹ jade.
Atẹjade kan lati ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni China, sọ pe ọgọrun-un oṣiṣẹ lo ti wa lẹnu iṣẹ idoola ẹmi naa.
Wọn ni o to eeyan igba ti wọn ti ri yọ.
Gẹgẹ bi iroyin abẹle agbegbe naa ṣe sọ, awọn araalu ṣalaye pe o ti to oṣu mẹfa ti apata nla ti maa n jabọ lati ori oke lagbegbe yii.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn agbegbe kan naa wa ni Guusu-iwọ oorun China to tun wa ninu ewu ilẹ riru.
Ni oṣu Kin-in-ni ọdun 2024, ilẹ riri waye lagbegbe Yunnan, ọpọ eeyan lo si pa nigba ti apata kan ṣubu le wọn lori, to si ba apa kan abule naa jẹ.
O si kere tan, eeyan mejidinlogun lo ku ninu iru iṣẹlẹ yii mi-in to waye lọdun mọkanla sẹyin lagbegbe ọhun.














