Iṣẹ́ Káfíńtà ni mo kọ́ níbẹ̀rẹ̀ ayé mi, àmọ́ mo ń pá tó N20m láàrin ọ̀sẹ̀ kan lórí Tiktok - Peller

Oríṣun àwòrán, Pulse Nigeria
Gbajugbaja ọdọmọkunrin to gbajumọ lori Tiktok, Habeeb Hamzat ti sọrọ nipa irinajo aye rẹ, ko to di pe o di ilumọka lori ikanni itakun agbaye Tiktok.
Hebeeb Hamzat, ẹni ti ọpọ mọ si Peller, sọ eyi fun ileeṣẹ iroyin abẹle Channels lasiko ifọrọwerọ kan to se, to si jẹ ko di mimọ pe iṣẹ Kapẹnta ni oun kọ saaju ko to di ilumọka.
O ni ki se pe oun nifẹ si iṣẹ Kapẹnta ti oun kọ ṣugbọn oun n kọ lasiko naa lati ti fi tẹ awọn obi oun lọrun.
"Mo ti kọkọ sisẹ nibi ileeṣẹ atẹwe kan (Printing Press) nigba ti mo wa ni ọmọ ọdun mẹtala ṣugbọn mo ma n sa nibẹ, lọ gba bọọlu.
"Mo n pa to ẹgbẹrun meji dọla si ẹgbẹrun mẹta dọla laarin ọgbọn isẹju ti mo ba se Live, owo ti mo pa wọle julọ jẹ ẹgbẹrun mẹwaa dọla"
"Nigba ti mo n kọ Kepẹnta, ni mo bẹrẹ si ma se Tiktok, ti mo si pade ọmọbinrin Jarvis"
Peller tun jẹ ko di mimọ pe o le ni ogun milọnu bayii ti oun n pa wọle lọsẹ lori ikanni Tiktok,
Pẹlu bi o ṣe ti ni ọpọ eeyan to n tẹle lori ikanni Tiktok, Peller ṣalaye pe pipa owo wọle rẹ lo da lori ohun to ba gbe sita fun awọn eeyan.
O ni bi awọn eeyan se n darapọ mọ lori ikanni igbohunṣafẹfẹ rẹ ni Tiktok ,ni owo n wọle.
"Mo n pa to ẹgbẹrun meji dọla si ẹgbẹrun mẹta dọla laarin ọgbọn isẹju ti mo ba se Live.
Owo ti mo pa wọle ju lo jẹ ẹgbẹrun mẹwaa dọla."
"Gbogbo ọrọ ti wọn sọ nipa mi pe mo n gba igba milọnu lo jẹ irọ to jina si otitọ.
N ko darapọ mọ ikanni Tiktok nitori mo fẹ gba owo .
Mo lọ sibẹ nitori mo fẹ ki wọn ma se 'Tap Tap' fun mi"
"Mo fẹ fẹ Jarvis ṣugbọn n ko le lọ Benin lọ pade awọn obi rẹ"

Oríṣun àwòrán, Others
Peller sọrọ nipa ajọsepọ rẹ pẹlu gbajumọ agbetosita lori Tiktok miran, Jarvis, ati bi ajọsepọ awọn mejeeji se n tẹsiwaju.
Ninu ifọrọwerọ naa, Peller jẹ ko di mimọ pe lati igba ti oun ti pade Jarvis, ni oun ti nifẹ rẹ ,
"Lati ọjọ ti mo ti foju ba Jarvis ni mo ti nifẹ rẹ."
Nigba ti wọn bi pe se o seese ki igbayawo waye laarin awọn mejeeji, Peller jẹ ko di mimọ pe, o wu oun lọkan lati jẹ pe igbeyawo waye laarin awọn mejeeji.
O ni awọn gbaradi bayii pe ki idile awọn mejeeji pade ara wọn.
Bakan naa lo sọrọ lori idi ti ko se fi irinajo lọ si ilu Benin lati lọ mọ awọn obi Jarvis.
"Mo fẹ fẹ Jarvis ṣugbọn n ko le lọ Benin bayii lati lọ ba awọn obi rẹ nitori igbakẹyin ti mo lọ, n se ni mo ri eewo lori mi, to si jẹ pe igba akọkọ ree.
Fun idi eyi , mo ni lati sọ fun wọn pe ki wọn wa si Lekki.















