Ṣé mìmì kankan ń mi APC bí Atiku, Obasanjo àtàwọn àgbà òṣèlú míì ti ń ṣèpàdé kiri?

Atiku ati Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @Atiku

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn agbaagba ninu ẹgbẹ oloselu tun ti n ko ara wọn jọ, ti oniruuru ipade ọsan ati our si ti n waye.

Bi o tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ ohun ti awọn ipade yii n da le lori amọ awọn onwoye ni kuru-kẹrẹ awọn oloselu ko le sẹyin eto idibo lọ.

Ni Ọjọ Aiku, iroyin kan ni gomina tẹlẹ nipinlẹ Kano ati oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu NNPP, Rabiu Kwankwaso se ipade pọ pẹlu gomina ana nipinlẹ Osun, Raufu Aregbesola lati fa a mọra feto idibo to n bọ.

"Abẹwo ni mo wa se, n ko setan lati sọrọ oselu - Atiku

Bakan naa, oludije sipo aarẹ tẹlẹ ati igbakeji aarẹ tẹlẹ, Alhaji Abubakar Atiku ti lewaju ikọ alagbara kan lọ se abẹwo si ọga rẹ tẹlẹ, Oloye Olusegun Obasanjo nile iyawekawe rẹ to wa nilu Abeokuta.

Lara awọn ikọ alagbara to tẹle Atiku lẹyin ni gomina tẹlẹ nipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal, gomina tẹlẹ nipinlẹ Rivers, Senator Liyel Imoke, atawọn oloselu jankan miran,

Agba oselu, Otunba Oyewole Fasawe si lo ki awọn alejo naa kabọ.

Nigba to n sọrọ lori koko ohun to fa abẹwo naa, Atiku ni abẹwo ni oun wa se, oun ko si setan lati sọrọ oselu.

O ni koko oun to wa lọkan ikọ oun bayii ni bi yoo se bori ibo gomina to n bọ nipinlẹ Anambra lọjọ Kẹjọ osu Kọkanla ọdun yii.

Se ẹru bawọn oselu se n ba sepade kiri yii n dẹru ba ẹgbẹ APC bi?

Niwọn igba to jẹ pe oye ni agba n wo, ẹgbẹ oselu APC ti wa kede iwoye rẹ nipa oniruuru awọn ipade tawọn oloselu n se kiri naa.

Nigba to n sọrọ lorukọ ẹgbẹ oselu APC, akọwe apapọ fẹgbẹ naa, Sẹnatọ Ajibola Basiru ni o see se ki ajọsepọ oselu wa laarin Oloye Olusegun Obasanjo ati Abubakar Atiku saaju eto idibo ọdun 2027.

Amọ APC ni baba ni baba n jẹ lọjọkọjọ nitori naa, mimi kankan ko mi oun lori ipade tawọn oloselu yii n se kiri.

APC ni igi imu jina sori, Atiku Abubakar ko si le bori aarẹ Tinubu tọrọ ba di ti eto idibo.

A fẹ́ kí wọ́n bá wa dá ilé ẹjọ́ tí yóò máa gbọ́ ẹ̀sùn ìdìbò nìkan sílẹ̀ - INEC

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ eleto idibo Naijiria, 'Independent National Electoral Commission', (INEC) ti pe fun idasilẹ ile-ẹjọ ara ọtọ ti yoo maa gbọ ẹsun to ba jẹ mọ magomago tabi iwa ọdaran ninu idibo nikan.

Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, Alaga INEC, pe fun kootu naa nibi ipade awọn akọroyin to waye l'Abuja. O ni o ṣe koko lati ni ile ẹjọ yii ti a ba wo bi iwa to lodi sofin ṣe maa n waye ninu idibo ni Naijiria.

Alaga INEC sọ pe idasilẹ kootu naa yoo yanju awọn iṣoro ati iwa ọdaran to rọ mọ idibo lorilẹede yii.

Bakan naa ni Hajiya Zainab Aminu Abubakar, agbẹnusọ INEC, ṣalaye fun BBC pe idasilẹ ajọ yii ni ipa rere lori ilana idibo ni Naijiria.

O ni iṣoro ti INEC n koju ko ju ti awọn to sọ ibo didi di wahala lọ.

"Bi wọn ba da kootu to n gbọ ẹsun idibo silẹ, o maa ran wa lọwọ gan-an, nitori ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o n huwa ọdaran yoo tete gba ijiya to tọ si i.

"Lọwọ yii, bi wọn ba mu ọdaran lasiko idibo, ile ẹjọ majisreeti ni wọn n mu wọn lọ, tabi ile ẹjọ giga to ba wa ni ipinlẹ naa.

Ṣugbọn nitori awọn ẹjọ bẹẹ ti pọ niwaju ile ẹjọ, o maa n pẹ gan-an fun awọn ọdaran naa lati gba idajọ ati ijiya to tọ si wọn lasiko."

"Fun idi eyi, o ṣe pataki lati gba ohun ti Alaga INEC n sọ lori idasilẹ kootu ti yoo maa gbọ ẹjọ iwa ọdaran nibi idibo nikan.

O daa ki wọn tete da a silẹ, ko le maa gbọ ẹsun awọn to ba huwa ọdaran ninu ibo."

Agbẹnusọ INEC, Hajiya Zainab Aminu Abubakar lo sọ bẹẹ fun BBC.

O fi kun un pe bi wọn ba da kootu silẹ fun igbẹjọ ẹsun idibo nikan, yoo tun jẹ kawọn oṣiṣẹ INEC to ba n gbabọde tabi huwa aitọ naa gba idajọ ododo ti yoo fiya jẹ wọn labẹ ofin.