Ó yẹ káwọn ètò ìṣèṣe kan ṣáájú kí Ọba tó dá Olóyè dọ̀bálẹ̀ níta gbangba tó fojú balé ẹjọ́ - Ààrẹ ẹgbẹ́ Yorùbá YCW

Oríṣun àwòrán, Others
Ààrẹ ẹgbẹ ọmọ Yoruba lagbaaye YCW, Ọgbẹni Dọtun Hassan, ti sọ pé o yẹ kawon eto kan waye lọna ibilẹ ki Ọba Abdulsemiu Ogunjobi, Olorile ti Orile Ifo to da Oloye Abraham Areola dọ̀bálẹ̀ ni ita gbangba to foju ba ile ẹjọ.
Aarẹ ẹgbẹ YCW fìdí ọrọ yìí múlẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu iwe iroyin Punch.
Ihuwasi kabiyesi naa ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọrọ le lori kaakiri ori itakun ayelujara.
Eyi si ti mu ki ijọba ipinlẹ Ogun pàṣẹ pé kí orí adé naa lọ rọkun nile fún oṣu mẹfa gbako.
Lẹyìn eleyii ni Kabiyesi Ogunjobi tun foju ba ile ẹjọ ti adájọ majisireeti si paṣẹ pe ki wọn gbe ori ade naa lọ si ọgba ẹwọn niluu Ilaro titi ti yoo fi ṣe awọn nkan ti ile ẹjọ n beere lati gba beeli rẹ.
O yẹ ki igbimọ lọbalọba ti gbe igbesẹ lori ọrọ yii - YCW
Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Hassan àjọ YCW bu ẹnu ẹtẹ lu iwa ti kabiyesi naa hu.
O ni iwa buruku gbaa ni eyi ti ko yẹ ọmọluabi rara.
"Amọ, a gbagbọ pe o yẹ ki igbimọ lọbalọba ipinlẹ Ogun ti gbe igbimọ kan dide lori ọrọ naa tori ki itẹ ọba ba ma baa di nnkan tàwọn eeyan n tabuku láwùjọ.
Iru igbesẹ yìí ni ko ba ti waye ki Ọba Ogunjobi to de ile ẹjọ rara.
Bo ya lati igba yẹn ni wọn o ba ti yọ kabiyesi naa loye, nitori pe ko yẹ ki ori ade sun ẹwọn.
Abuku nla ni eleyi jẹ si ipo ọba àti igbimọ lọbalọba ni Naijiria,'' Hassan lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Hassan ni kii ṣe igba akọkọ ree ti iru iṣẹlẹ bayii yoo waye, o ni ohun ti ko dara ni pé àwon igbimọ lọbalọba ko ni eto tabi ọna ti wọn le lo lati ba kabiyesi to ba hu iru iwa bayii wí.
O ni awọn igbimọ lọbalọba to wa ni ipinlẹ Yoruba kọọkan ní ko sisẹ wọn bí iṣẹ ni gbogbo iru iṣẹlẹ bayii fi n ṣẹlẹ.
Ọgbẹni Hassan wa pe fún agbekalẹ Iwe Ofin Yoruba eyi ti yoo sọ iru iya to ba tọ sí ẹnikẹ́ni to ba hu iru iwa ti kabiyesi Ogunjobi hu yìí.
O ni ko si nkan to buru ninu bi won ṣe gbe kabiyesi naa ile ẹjọ tori bi won se fiya jẹ baba Oloye Abraham ko dara rara.
O ni idajọ ododo gbọdọ waye lori ọrọ naa.
"Àmọ, nkan ti awa n sọ ni pe o yẹ káwọn ètò ibilẹ kan ti waye ni Orile Ifo gangan an nibi ti iṣẹlẹ yìí ti waye ki ọrọ naa to de ile ẹjọ.
Kii ṣa ṣe wí pe ọba yìí lo gbe ara rẹ sori itẹ.
O yẹ ki awọn Oloye bíi Otunba, Oluwo, Iyalode, Iyaloja atawon mii ti ṣepade pọ, ki wọn sì da ẹjọ to ba yẹ fun kabiyesi lori ọrọ naa."
''Nnkan to ṣẹlẹ si Ọba Abdulsemiu Ogunjobi yii le lẹyin''
Aarẹ ẹgbẹ YCW tun sọ pe ọrọ to ṣẹlẹ yìí ati bi kabiyesi Ogunjobi ti dero ile ẹjọ le lẹyìn.
O ni ko sí ẹni to mọ bo ya eewọ ni iru nnkan to ṣẹlẹ yìí jẹ fun Orile Ifo.
O le jẹ nnkan to le fa iṣẹlẹ ibi fún ìlú Orile Ifo nitori apere ọba Orile Ifo nii ṣe pẹlu awọn Alalẹ ilu naa.
Ọgbẹni Hassan ṣàlàyé siwaju sí pe lati ọjọ ti Ọba Ogunjobi ti gori apere awọn baba nla rẹ l'awọn oso, ajẹ at'awọn alagbara àwùjọ naa ti ko gbogbo agbara wọn le e lọwọ.
Aarẹ YCW ni o si le jẹ pe kabiyesi nikan atawon ẹbi rẹ ni yoo faragba ohun to ba tidi iṣẹlẹ yìí jáde tori oun lo ṣẹ.
O ni idi niyii ti orisiirisii iṣẹlẹ buruku fi n ṣẹlẹ kaakiri l'awọn ibikan.















