Kí ló dé tí Nnamdi Kanu fàbínú yọ níbi ìgbẹ́jọ́ rẹ̀?

Aworan Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Adajọ agba ti ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Abuja, Binta Nyako ti sun igbẹjọ olori ikọ IPOB, Nnamdi Kanu siwaju, ti wọn ko si kede pato ọjọ ti igbẹjọ naa yoo pade si ile ẹjọ.

Ni ọjọ Aje, ọjọ Kẹwaa, oṣu Keji, ọdun 2025 ni adajọ Nyako sun igbẹjọ siwaju lai mu ọjọ kan pato, lẹyin ti Nnamdi Kanu yari pe oun ko fẹ ki adajọ naa tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ oun.

Lati ọdun 2021 ni Kanu ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ State Securuity Service, SSS.

Niṣe ni ọrọ di ere ori itage nile ẹjọ nigba ti agbẹjọro Nnamdi Kanu, Aloy Ejimakor sọ fun adajọ Binta Nyako pe ko yẹba kuro nibi igbẹjọ naa.

"O ti han daju pe ile ẹjọ n sisẹ tako mi, eyi to mu ki wọn maa fi igbẹjọ mi wọlẹ"

Ejimakor ni oun n gba ẹnu onibaara oun sọrọ naa ni nitori Kanu ko ni igboya kankan ninu adajọ naa mọ.

Idasilẹ orilẹ ede Biafra ni Nnamdi Kanu ati ikọ IPOB n ja fun.

Kanu sọ fun awọn akọroyin lẹyin ti adajọ sun igbẹjọ naa siwaju pe o ti han daju pe ile ẹjọ n sisẹ tako oun eyi lo si fa a ti wọn fi n fi igbẹjọ oun wọlẹ.

Ṣaaju ni adajọ Nyako ti yẹbaa lori igbẹjọ Nnamdi Kanu nigba to beere lọwọ ile ẹjọ loṣu Kẹsan-an ọdun 2024 pe oun ko fẹ ki adajọ Nyako gbọ ẹjọ naa mọ.

Ki lo ṣẹlẹ nile ẹjọ lọjọ Aje?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti igbẹjọ bẹrẹ lọjọ Aje, agbẹjọro fun ijọba, Awomolo sọ fun ile ẹjọ pe ki awọn tẹsiwaju lori igbẹjọ naa ati pe awọn ẹlẹrii awọn ti wa nikalẹ.

Amọ agbẹjọro Kanu, Ejimakor ni oun ko gba nitori onibaara oun ti ni oun ko ni jẹjọ niwaju adajọ naa mọ.

Ejimakor ni onibaara oun ṣi duro lori ọrọ rẹ pe oun ko fẹ ki adajọ naa tẹsiwaju.

Ṣugbọn nigba to n fesi, adajọ Nyako ni adajọ agba ile ẹjọ naa ko gba ibeere Kanu wọle, ti wọn si ti da ẹjọ naa pada fun oun.

Adajọ Nyako ni ti Kanu ba ṣi duro lori ọrọ rẹ, ko kọ iwe ranṣẹ sile ẹjọ pe oun ko fẹ ki oun gbọ ẹjọ naa mọ dipo ọrọ to sọ ṣaaju.

Eyi lo mu Kanu fi ibinu sọrọ nile ẹjọ pe ki lo de ti wọn fi gbe ẹjọ oun siwaju adajọ naa.

O ni gbogbo nnkan ti adajọ naa n sọ ko ni itumọ si oun.

O ni ibọwọ ti oun ni fun ilana ofin lo jẹ ki oun yọju sile ẹjọ ati pe oun gbagbọ pe adajọ naa ti yẹba lori ẹjọ naa.

Kanu ni inu oun ko dun si ipinnu adajọ agba ile ẹjọ ọhun, to gbe ẹjọ oun pada sọdọ adajọ Nyako, to si tẹnumọ pe Naijiria ko le da ẹjọ oun.

O tẹmpẹlẹ mọ pe Adajọ Nyako n ṣe oju ṣaaju lori igbẹjọ oun.