Wo àwọn okoòwò sogúndogójì tó ti lulẹ̀ ní Naijiria láti ọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn

Aworan okowo sogundogoju

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oniruuru okowo sogundogoji lo ti lulẹ ni Naijiria laarin ọdun mẹwaa sẹyin eyi to si ti ko ọpọ eeyan si gbese.

Lopin ọsẹ to kọja ni ọpọ ọmọ Naijiria bẹrẹ si ni sọrọ lori itakun ayelujara wi pe awọn ti padanu owo rọgun-rọgun nibi okowo ki wọn pe orukọ rẹ ni CBEX.

Ohun tawọn eeyan to dokowo pẹlu CBEX kọkọ ṣe akiyesi ni pe awọn ko le ri owo gba jade lori itakun ayelujara eto okowo naa mọ.

Nigba to ya ni wọn wa ri pe ko si nnkan kan ninu akaunti wọn ti wọn ni pẹlu CBEX mọ.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe owo to le ni N1.3 trn to jẹ $809,000 ni owo tawọn ọmọ Naijiria padanu sibi okowo CBEX.

Nnkan to jẹ kawọn eeyan to dokowo pẹlu CBEX pọ ni pe awọn to n ṣagbatẹru okowo naa sọ fun wọn iye ti wọn ba fi dokowo naa ni ere ti wọn yoo ri laarin oṣu kan.

Lẹyin eyi lawọn ọdọ kan binu ti wọn yabo ọfiisi CBEX to w ani Oke Ado niluu Ibadan nibi tawọn eeyan ti ji oriṣiiriṣii nnkan gbe lọ.

Lọdun 2018, Ọmọwe Jackson Tamunosaki Jack ni ile ẹkọ giga fasiti ni Otuoke ati Ọmọwe Christopher Chimaobi ti ile ẹkọ giga fasiti Nnamdi Azikwe sọ lẹyin iwadii ti iwadii u wọn ṣe wi pe bi eto ọrọ aje ṣe dẹnu kọlẹ ni Naijiria lo jẹ ki ọpọ eeyan maa ṣe okowo sogundogoji.

Esi iwadii naa tun fidi rẹ mulẹ pe okowo sogundojoji bẹrẹ si ni pọ ni Naijiria lẹyin asiko ti ọrọ aje Naijiria lulẹ lọdun 2016.

Wọnyii ni awọn okowo sogundogoji to ti lulẹ ni Naijiria ni nnkan bi ọdun mẹwaa sẹyin:

Mavrodi Mondial Moneybox (MMM)

Aworan MMM

Oríṣun àwòrán, MMM/Facebook

Okowo Mavrodi Mondial Moneybox aka MMM gbaju gbaja ni Naijiria fun bi ọdun meji ti ọpọ eeyan si kowo si i.

Okowo MMM ti w ani orilẹede Russia fun bii ogoji ọdun, amọ, loṣu Kọkanla ọdun 2016 lo wọ Naijiria.

Owo to to biliọnu mejila naira ni iroyin sọ pe awọn ọmọ Naijiria padanu nigba ti okowo MMM lulẹ.

Ere gọbọi lawọn eeyan n ri lori okowo MMM loṣooṣu papaa julọ nigba tie to naa kọkọ bẹrẹ.

Lọjọ kẹfa oṣu Kẹrin ọdun 2018 ni wọn kede pe MMM ti pari lẹyin iku baba isalẹ okowo ọhun, Sergie Marvodi, to bẹrẹ rẹ.

XIMA FX

Awọn olokowo XIMA FX polowo okowo wọn ni Naijiria lọdun 2020 pe ere ida 15% lo wa lori okowo awọn.

Nigba to di oṣu Kẹrin ọdun naa ni wọn kede pe ere ori okowo naa ti di ida 10%.

Wọn o ti gbe nnkankan jade lori eto naa lati ọdun 2020, ko si nkankan lori itakun igbọrọkaye wọn.

MBA Forex

Aworan afurasi tu wọn n wa

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu kede pe awọn n wa Maxwell Chizi Odum to jẹ ọga agba okowo MBA Forex fun jibiti $518.3m.

MBA Forex forukọ silẹ pẹlu ajọ CAC to n ri si ọrọ dida ileeṣẹ silẹ ati ajọ to n gbogun ti jiji owo ko lọ ile okeere.

Okowo yii siṣẹ fun ọdun mẹrin ki wọn to kogba sile loṣu Kejila ọdun 2020.

Ajọ SEC to n ri si pasipaarọ owo ni Naijiria naa ṣalaye pe ileeṣẹ MBA Forex ko forukọ silẹ pẹlu.

Adari ajọ to n ṣewadii ni ajọ niluu Port Harcourt, Enebeli Sulukwe loṣu Karun un ọdun ṣalaye pe MBA Forex gbiyanju lati forukọ silẹ pẹlu awọn ṣugbọn wọn o koju oṣunwọn.

Wọn wa lara awọn ileeṣẹ ti ajọ SEC forukọ wọn lede pe wọn n ṣiṣẹ lọna aitọ ni Naijiria.

Wọnyii ni awọn okowo sogundogoji 58 ti EFCC lo n ṣiṣẹ lọna aitọ ni Naijiria:

  • Wales Kingdom Capital
  • Bethseida Group of Companies,
  • AQM Capital Limited,
  • Titan Multibusiness Investment Limited,
  • Brickwall Global Investment Limited,
  • Farmforte Limited & Agro Partnership Tech,
  • Green Eagles Agricbusiness Solution Limited,
  • Richfield Multiconcepts Limited,
  • Forte Asset Management Limited, (Biss Networks Nigeria Limited, S Mobile Netzone Limited, Pristine Mobile Network),
  • Letsfarm Integrated Services,
  • Bara Finance & Investment Limited,
  • Vicampro Farms Limited,
  • Brooks Network Limited,
  • Gas Station Supply Services Limited,
  • Brass & Books Limited, (Annexation Biz Concept & Maitanbuwal Global Venturescrowdyvest Limited,) and
  • Crowdyvest Limited,
  • Jadek Agro Connect Limited,
  • Adeeva Capital Limited,
  • Oxford International Group and Oxford Gold Integrated,
  • Skapomah Global Limited,
  • MBA Trading & Capital Investment Limited,
  • TRJ Company Limited,
  • Farm4Me Agriculture Limited,
  • Quintessential Investment Company,
  • Adeprinz Global Enterprises,
  • Rockstar Establishment Limited,
  • SU.Global Investment,
  • Citi Trust Funding PLC,
  • Farm Buddy,
  • Eatrich 369 Farms & Food,
  • Globertrot Farmsponsors Nigeria Limited,
  • Farm Sponsors Limited,
  • Cititrust Credit Limited,
  • Farmfunded Agroservices Limited,
  • Adamakin Investment & Works Limited,
  • Cititrust Holding PLC,
  • Green Eagles Agribusiness Solutions Limited,
  • Chinmark Homes & Shelters Limited,
  • Emerald Farms & Consultant Limited,
  • Ovaioza Farm Produce Storage Limited,
  • Farm 360 & Agriculture Company,
  • Requid Technologies Limited,
  • West Agro Agriculture & Food Processing Limited,
  • NISL Ventures Limited & Estate of Laolu Martins,
  • XY Connect Investment Limited,
  • River Branch Unique Investment Limited,
  • Hallmark Capital Limited,
  • CJC Markets Limited,
  • Crowd One Investment,
  • Farmkart Foods Limited,
  • KD Likemind Stakeholders Limited,
  • Holibiz Finance Limited,
  • Ifeanyi Okpe Oil & Gas Services,
  • Servapps Nigeria Limited,
  • Barrick Gold Mining Company and
  • 360 Agric Partners Limited.