Eniola Badmus àti Laide Bakare fìjà pẹ́ẹta níbi ìfilọ́lẹ̀ fíìmù Eniola Ajao

Laide Bakare àti Eniola Badmus

Oríṣun àwòrán, Laide Bakare/Eniola Badmus/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Níṣe ni gbas gbos tún bẹ́ sílẹ̀ lágbolé òṣèré tíátà bí àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà méjì, Laide Bakare àti Eniola Badmus ṣe gbo ewúro sójú ara wọn ní òpin ọ̀sẹ̀.

Níbi ìfilọ́lẹ̀ fíìmù gbajúmọ̀ òṣèré Eniola Ajao, Owambe Thieves tó wáyé ní agbègbè Lekki, ìpínlẹ̀ Eko ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹrin, ọdún 2025 ni fídíò kan gba orí ayélujára tó ṣàfihàn báwọn òṣèré méjéèjì náà ṣe ń kojú oro síra wọn níbi ayẹyẹ náà.

Nínú fídíò náà, Laide Bakare, tí ó jọ pé inú ń bí gidi, ń bú Eniola, tó sì ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé si.

Fídíò náà ti ń fa onírúurú àríwísí àti awuyewuye lórí ayélujára táwọn èèyàn sì ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tó fa ìkùnsínú láàárín àwọn gbajúmọ̀ òṣèré méjéèjì.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà tí Laide Bakare wù nínú fídíò náà nítorí Eniola Badmus kò sọ ohunkóhun sí àwọn èébú tó ń bú u.

Lẹ́yìn náà ni Laide Bakare gbé àwọn àwòrán nípa àjọsọ òun àti Eniola Badmus síta níbi tó ti ní ó sọ pé òun ń ṣe bíi ẹranko tó sì ní kó jìnà sí òun réré.

Lábẹ́ àwòrán náà ni Laide Bakare sọ pé òun nìkan ni òun fún Eniola Badmus ní ààyè láti kópa nínú sinimá lásìkò táwọn èèyàn kò fẹ́ máa lò ó nínú eré látàrí bí ó ṣe tóbi nígbà nígbà náà.

"Èmi ni mo fún ẹ ní ipa tó fi ẹ́ hàn gẹ́gẹ́ bí òṣèré nígbà tí ẹnikẹ́ni kò fẹ́ lò ẹ́ nítorí bí o ṣe tóbi.

"Mo ná owó mi lórí aláìmoore bíi tìrẹ, ohun tí o fi san fún mi ni kí ó pè mí ní ẹranko."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Jẹ́jẹ́ mi ni mo ta kété níbi ayẹyẹ kí Eniola Badmus tó wá tọ́ mi – Laide Bakare

Lẹ́yìn náà ni Laide Bakare ṣe fídíò láti ṣàlàyé ohun tó ṣokùnfà ìfaǹfà láàárín wọn níbi ayẹyẹ náà.

Laide Bakare ní jẹ́jẹ́ ni òun wà ní ààyè ara níbi ayẹyẹ náà kó tó di pé Eniola Badmus tó wà bá kọlu òun láti mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ kí òun tara sọ̀rọ̀.

Ó ní òun ṣe fídíò náà láti fọ ara òun lórí báwọn èèyàn ṣe ń fẹ̀sùn kan òun pé òun ni oníwàhálà tó sì jẹ́ pé Eniola ló wá tọ́ òun níbi tí òun dúró sí.

Ó ṣàlàyé pé láti ọdún méjì sẹ́yìn ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín àwọn nítorí àwòrán kan tí àwọn jọ ya tí òun fi sórí ayélujára.

Ó ṣo pé Eniola Badmus kọ àkọráńṣẹ́ sí òun lẹ́yìn tí òun fi àwòrán náà síta níbi tó ti ń bú òun pé òun kò dára tó nínú àwòrán náà, pé kí òun gbé àwòrán náà kúrò lórí ayélujára.

Ó fi kun pé Eniola Badmus pé òun ní ẹranko nítorí òun kò gbé fóònù lásìkò tó ń pe òun àmọ́ tí kò sí fóònù lọ́wọ́ òun.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ìfaǹfà ń wáyé láàárín àwọn méjéèjì

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ìfaǹfà ń wáyé láàárín àwọn gbajúmọ̀ òṣèré méjéèjì yìí. Lọ́dún 2023, Eniola àti Laide ní ìfaǹfà nígbà tí Eniola fi aṣọ tí Laide Bakare wọ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ ìwé rẹ̀ kan tó kọ wé aṣọ Pásítọ̀ Ajidara.

Laide Bakare nígbà náà fẹ̀sùn kan Eniola àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ mìíràn pé wọn kìí kan sáárá sí òun nígbà tí òun bá ṣe àṣeyọrí, tó jẹ́ pé àṣìṣe èèyàn nìkan ni wọ́n máa ń rí.

Eniola nígbà náà fèsì pé Laide fi ọmọ bu òun, tó sì tún bu ẹnu àtẹ́ lu òun nítorí pé òun ṣe àtìlẹyìn fún ààrẹ Bola Tinubu lásìkò ètò ìdìbò.

Ìfaǹfà láàárín Eniola Badmus àtàwọn òṣèré mìíràn

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni awuyewuye kan wáyé láàárín Eniola Badmus àti gbajúmọ̀ òṣèré tíátà míì, Opeyemi Aiyeola.

Opeyemi Aiyeola nínú fídíò kan tó ṣe fẹ̀sùn kan pé Eniola Badmus tàbùkù òun pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kan tó kọ sí fídíò tí òun fi sórí ayélujára.

Eniola Badmus bèèrè lọ́wọ́ Opeyemi Aiyeola ní abala àríwísí lábẹ́ fídíò náà pé níbo ni àwọn irun iwájú orí rẹ̀ wà?

Àmọ́ ìbéèrè yìí gbòdì lára Opeyemi Aiyeola bí ó ṣe fẹ̀sùn kàn pé Eniola Badmus ń fi òun ṣe yẹ̀yẹ́, tó sì ń fi èébú ara bu òun.

Nínú fídíò náà ni Opeyemi Aiyeola tún ti fẹ̀sùn kàn Eniola Badmus pé kìí sọ̀rọ̀ sáwọn àwòrán tàbí fídíò nǹkan dada tí òun bá fi sórí ayélujára nítorí náà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa bu òun.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Eniola Badmus padà tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Opeyemi Aiyeola lórí ọ̀rọ̀ náà, pé òun ń ba ṣeré lásán ni, Opeyemi Aiyeola ní òun kò gba àforíjì náà wọlé nítorí òun àti ẹ kìí ṣe aláwàdà.