Àwọn afurasí agbébọn tún ṣekú pa èèyàn 40 míì ní Plateau nínú ìkọlù tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan ogoji eeyan lawọn afurasi janduku agbebọn tun ti ṣeku pa nipinlẹ Plateau ninu ikọlu mii to ṣẹṣẹ waye nipinlẹ naa.
A gbọ pe ọpọ eeyan to fara gbọta lo n gba itọju bayii nile iwosan.
Ikọlu yii waye lẹyin bi ọsẹ meji tawọn agbebọn ṣeku pa eeyan mejilelaadọta lawọn awujọ kan nipinlẹ Plateau.
Ikọlu tuntun yii waye niluu Zike to wa ni ijọba ibilẹ Bassa eyi ti a gbọ pe awọn obinrin ati ọmọde lo fara gba julọ nibẹ.
Gẹgẹ bi awọn olugbe ileto Kwall ṣe ṣalaye, awọn janduku naa ya wọ abule ọhun ni aarọ kutu oni ọjọ Aiku, wọn si bẹrẹ si ni yinbọn lati dẹru bawọn eeyan.
Ajagun fẹyinti Shipi Gakji to jẹ oludamọran fun gomina ipinlẹ Plateau lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC.
''Otitọ ni ikọlu naa waye, a fẹẹ ṣe akojọpọ iye eeyan to ku ninu iṣẹlẹ naa.
O ṣee ṣe kawọn to padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ọhun to bii ogoji,'' Gakji ṣalaye fun BBC.
Lọsẹ to lọ lawọn agbebọn ṣe ikọlu sawọn ilu kan ni ijọba ibilẹ Bokkos nibi ti wọn ti gbẹmi eeyan to le ni aadọta ti ọpọ eeyan si fara pa.
Oniruuru ikọlu lo ti n waye nipinlẹ Plateau eyi to ni ṣe pẹlu ija ẹlẹsin mẹsin ati ẹlẹya mẹya.
Ikọlu si tun n ṣẹlẹ nipinlẹ Plateau, bo tilẹ jẹ pe ijọba n fi da araalu loju pe awọn n ṣiṣẹ lori ati pese abo fawọn eeyan.
Yatọ si awọn ikọlu to ṣẹlẹ laipẹ yii, o ti pẹ ti ija ti n ṣẹlẹ laarin awọn agbẹ atawọn darandaran ni ipinlẹ naa.















