Ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ Sharia lè da àlàáfíà ilẹ̀ Yorùbá rú, àtúntò ìjọba lọ̀nà àbáyọ - Gani Adams

Oríṣun àwòrán, The Office Of Ààre Onakakanfo Of Yoruba Land Iba Gani Adams/Facebook
Ẹgbẹ Yoruba One Voice (YOV) to n pe fun iyapa ẹya Yoruba lara orilẹede Naijiria eyi ti Aare Onakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, jẹ adari wọn ti tako bawọn musulumi kan ṣe n pe fun idasilẹ igbimọ Sharia kaakiri ilẹ Yoruba.
Ẹgbẹ YOV ni idasilẹ igbimọ Sharia le da omi alaafia ilẹ Yoruba ru, o si tun le ṣakoba fun orilẹede Naijiria lapapọ.
Ẹgbẹ YOV sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lẹyin apero kan ti wọn ṣe eyi ti wọn pe akori rẹ ni ''Ofin Sharia nilẹ Yoruba: Atunto ijọba lọna abayọ.''
Apero naa ti Iba Gani Adams dari rẹ ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ YOV kaakiri agbaye atawọn alẹnulọrọ ọmọ Yoruba wa nibẹ.
Ẹgbẹ naa sọ ninu atẹjade to fi sita wi pe atunto ijọba ti yoo mu ijọba ẹlẹkunjẹkun wa ni ọna si alaafia ati idagbasoke orilẹede Naijiria.
Awọn olukopa nibi apero naa sọ pe ko si igba ti Yoruba ko ni beere fun ominira lara Naijiria, ti awọn alaṣẹ ijọba ba tẹsiwaju lati maa kọ eti ikun si ipe fun atunto iṣejọba.
Ninu ọrọ rẹ, Iba Adams ni igbiyanju lati da igbimọ Sharia silẹ nilẹ Yoruba lọwọ oṣelu ninu.
Aarẹ Onakakanfo ilẹ Yoruba sọ pe igbesẹ yii le da rukerudo silẹ, o si tun le jẹ kawọn alakata ẹsin dide gẹgẹ bi o ti n ṣẹlẹ lapa ariwa Naijiria.
''Idasilẹ Sharia ko ni ṣe anfani kankan fun ọrọ aje, aṣa tabi eto oṣelu.
Koda, o le da omi alaafia ilẹ Yoruba ru, Sharia tun le jẹ kawọn ọdọ di apanle eyi to n ṣẹlẹ lawọn ibikan ni Naijiria,'' Aarẹ Onakakanfo ilẹ Yoruba.
Imọran fun ijọba lati ibi apero ẹgbẹ YOV
Lara awọn imọran ti ẹgbẹ YOV gba ijọba nibi apero wọn ni pe ki ijọba ṣe atunṣe iwe ofin Naijiria lọna ti yoo ro awọn ijọba ibilẹ lagbara.
Ẹgbẹ YOV tun gba ijọba ni imọran lati maa pin ere ọrọ aje Naijiria daadaa laarin awọn ẹka ijọba.
YOV ni ko yẹ ki ile ẹjọ kankan jẹ dandan fun ọmọ Naijiria, ẹni to ba wu lo yẹ ko maa lo ile ẹjọ lai tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ.
Ninu ọrọ apilẹko rẹ, Ọjọgbọn Oluwafemi Obayori, ṣalaye pe ẹsin musulumi ti de ilẹ Yoruba lati ọjọ to ti pẹ, ṣugbọn o ni igbesẹ lati sẹ idasilẹ igbimọ Sharia tabuku aṣa Yoruba.
Ọjọgbọn Obayori ni idasilẹ igbimọ Sharia ati titabuku Iṣẹṣe mu ewu dani fun aṣa ati iṣọkan orilẹede Naijiria.
Ọjọgbọn Kolawole Raheem to jẹ oludamọran ẹgbẹ YOV sọ pe awọn musulumi Yoruba nilo igbimọ ti yoo maa bawọn yanju aawọ ninu ẹsin wọn, amọ, wọn o gbọdọ jẹ ki o pa ẹtọ ẹlomiran lara.
Ọjọgbọn Raheem ni awọn tik ii ṣe musulumi lawọn ipinlẹ ti wọn ti n lo ofin Sharia lapa ariwa Naijiria maa n koju iṣoro idẹyẹsi eleyii to ni ko gbọdọ ṣẹlẹ nilẹ Yoruba.
Akọwe agba ẹgbẹ YOV, Ọmọba Adedokun Ademiluyi, pe fun ibaṣepọ laarin ẹgbẹ naa atawọn ẹkun mii bii Middle-Belt ati South South tawọn naa n beere fun atunto ijọba.
Bakan naa ni o sọ pe ijọba gbọdọ ri pe eto abo fẹsẹ mulẹ daadaa lati le koju awọn aṣawọ to n da ija ẹlẹsin-mẹsin silẹ.















