Ṣé lóòótọ́ ni ọkọ̀ tó kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú aya Ààrẹ pa ọmọ ọdún méje l'Akure?

Oríṣun àwòrán, X/Oluremi Tinubu
Ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹrin ọdun 2025 ni iroyin kan jade lori ayelujara pe ọkan ninu ọkọ akọwọrin to n tẹle Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Sẹnetọ Oluremi Tinubu, ṣekupa ọmọdebinrin kan, Saratu Lawal niluu Akure, nipinlẹ Ondo.
Iroyin naa ni iṣẹlẹ naa waye ni Mọsalasi Oba Ile nigba ti iyawo aarẹ n bọ lati papakọ ofurufu ilu Akure.
Remi Tinubu lo ṣe abẹwo si nipinlẹ Ondo lati ṣe ifilọlẹ South West Renewed Hope Initiative, ajọ kan to wa labẹ ileeṣẹ aarẹ eyi to n pese iranlọwọ fun awọn obinrin ati ọdọmọbinrin.
Sahara Reporters ni awọn ba osojumikoro sọrọ, to si sọ fun wọn pe Saratu, akẹkọọ ile ẹkọ Islamiyar ni agbegbe Shasha, ni wọn ni ọkọ akọwọrin iyawo aarẹ Hilux gba, to si jade laye.
Bakan naa, iroyin naa ni Baba Saratu, Malam Lawali, ni oun ti fa ọrọ naa le Ọlọrun lọwọ.
Kii se ọkọ aya aarẹ lo gba ọmọdebirin naa, ọkọ ayọkẹle mii ti ko ni nọmba lara, lo gba ọmọ ọdun meje naa, to si jade laye lẹsẹkẹsẹn - Ọlọpaa
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti kede pe iroyin ẹlẹjẹ pọnbele ni iroyin ti SaharaReporters gbe sita lọjọ Kẹtadinlogun oṣu kẹrin ọdun 2025.
Wọn ni iroyin naa lo n tọka si pe ọkan ninu ọkọ to nnkọwọrin pẹlu iyawo aarẹ, Oluremi Tinubu ṣekupa ọdọmọbinrin, ọmọ ọdun meje lasiko to ṣe abẹwo si ipinlẹ naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii oun fihan pe ọkọ ayọkẹle mii ti ko ni nọmba lara lo gba ọmọ ọdun meje naa, to si jade laye lẹsẹkẹsẹ.
Oṣojumikoro to ba ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ ni awọn ọlọkada agbegbe naa fi ọkada le ọlọkọ to ṣekupa ọmọdebinrin naa ni kete ti isẹlẹ naa waye.
Iṣẹlẹ yii ni ọpọ awọn eeyan ti jẹri si , to fi mọ awọn obi oloogbe ati awọn eeyan mii to wa ni agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye, gẹgẹ bii ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ṣalaye.
Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ṣe abẹwo si idile oloogbe, to si fi da wọn loju pe iwadii yoo bẹrẹ lati ṣawari ẹni to ṣekupa ọmọ wọn.
"Ọkọ to n kọwọrin tẹle iyawo aarẹ kọ lo ṣekupa ọmọdebinrin, ọmọ ọdun meje lẹyin iwadii wa."
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa tun fẹsun pinpin iroyin ẹlẹjẹ kiri kan ileeṣẹ iroyin SaharaReporters lẹyin to gbe iroyin kan jade pe ileeṣẹ ijinigbe kan waye ni agbegbe Ugbogui ni ẹgbẹ Ohosu, ti iwadii si fihan pe ipinlẹ Edo ni iṣẹlẹ naa ti waye ki n ṣe ipinlẹ Ondo.
"Bi Sahara Reporters ṣe n kọ iroyin ni ko dara to, to si jẹ ohun ituju.
"Ileeṣẹ ọlọpaa n kesi wọn bayii pe ki wọn yọ iroyin naa, ki wọn si tọrọ aforijin lọwọ gbogbo awọn ti ọrọ kan.
Otitọ ni ileeṣẹ ọlọpaa n di mu, ti a si fẹ ki awọn araalu si mọ pe aabo ati alaafia wọn lo jọ wa loju."















