Àlàyé rèé lórí ìdí tí ń kò fi ṣe àtìlẹyìn fún Peter Obi - Wike

Aworan Peter Obi ati Nyesome Wike

Oríṣun àwòrán, RVSG

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Minisita fun olu ilu Abuja, Nyesome Wike, ti ṣalaye idi ti ko fi ṣe atilẹyin fun oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi lasiko eto idibo ọdun 2023.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja, Wike ni oun gbagbọ pe Obi ko ni agbara to yẹ lati fi bori eto idibo na, to si ṣapajuwe rẹ gẹgẹ bii oludije ayelujara.

"Rara, ko le bori eto idibo.

"N ko ki n lọ agbo awọn oludije ayelujara. N ko ki n tẹle oludije ayelujara."

Wike ni gẹgẹ bi oloṣelu, oun to n gbajumọ ni agbara oludije lati bori eto idibo, ti oun ko ki n tẹle awọn oloṣelu to fẹ di olokiki lori ayelujara.

Mo ni gẹgẹ bi oloṣelu, mo n yanayana olujide to le bori ibo.

Wike ni eto idibo lorilẹede ju ki eeyan ni okiki nikan, tabi ko jẹ olokiki lori ayelujara.

"Ninu oṣelu, ọrọ ki n ri bẹ, pe eyi oludije to yanranti. Rara, rara, rara.

Ọpọ nnkan lo so mọ oṣelu orilẹede Naijiria."

"PDP ko ni ohun to tọ lati bori idibo lọdun 2027"

Minisita naa ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ko ni igbaradi to tọ lati bori eto idibo lọdun 2027

Wike ni PDP ko ni ifọwọsowọpọ to tọ lati koju ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress lọdun 2027.

Saaju ni iroyin kan gbode pe awọn ẹgbẹ oṣelu alatako fẹ parapọ lati gba ijọba lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC lọdun 2027.

"PDP ko ti ṣetan fun eto idibo ọdun 2027. O han gbangba. Fun apẹẹrẹ, mo ni idanwo, mo n lọ iya kawe lati kawe. Bẹẹni mo n kawe? O ko ni lati tan arawa jẹ pe a n kawe. O kan igbiyanju pe ki awọn eeyan ri iwọ naa pe oun gbe baagi lọ ile ikawe ni."