Ogún èèyàn tún kú nínú ìkọlù tuntun àwọn afurasí darandaran ní Benue

Gomina ipinlẹ Benue, Hyacinth Iormem Alia

Oríṣun àwòrán, @HyacinthAlia

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan, eeyan ogun mi-in lo tun ti di oloogbe bayii ninu ikọlu tuntun kan to waye lagbegbe Logo ati Gbagir, nijọba ibilẹ Ukum, ipinlẹ Kogi.

Ikọlu to waye ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ Ọjọbọ naa ni a gbọ pe awọn darandaran lo wa nidii rẹ.

Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinle Benue, CSP Anene Sewuese Catherine, buwọ lu, ṣalaye, pe lasiko ti ìró ibọn n dun lati le awọn agbebọn naa lọ ni awọn eeyan naa bẹrẹ si i yinbọn bo ṣe wu wọn.

O ni lasiko naa ni wọn yinbọn lu awọn agbẹ to n rin lọ jẹjẹ wọn.

Alukoro ọlọpaa Benue sọ pe awọn ko mọ pe bawọn ṣe n gbiyanju lati le awọn darandaran lọ ni ikọlu mi-in tun n waye lagbegbe Logo.

"O ṣe ni laaanu pe ikọlu asiko kan naa ti a ko fura si n waye ni Logo, wọn si pa eeyan mejila"

Anene lo sọ bẹẹ ninu atẹjade naa.

Ninu ọrọ rẹ to sọ lori amohunmaworan, Gomina ipinlẹ Benue, Ẹniọwọ Hyacinth Alia, sọ pe, "Ni bayii, a ti fidi iku ogun eeyan mulẹ lagbegbe Sankera.

"A ti kọkọ ri oku marun-un ni Gbagir, a gbe wọn lọ sile igbokusi. Lẹyin ẹ ni awọn eeyan to n wa ẹni wọn tun ri oku meji si i. "

"Bakan naa ni awọn ọlọpaa ri oku eeyan mejila, ti iye eeyan to ti ku fi jẹ ogun.''

Gomina koro oju si iṣẹlẹ yii, o ni baba, iya, ọmọ, ẹgbọn ati aburo awọn eeyan kan lo di oloogbe lojiji yii.

Èèyàn tó le ni àádọ́jọ ló ti kú nínú ìkọlù

Laaarin ikọlu to ṣẹṣẹ waye yii si ọsẹ meji sẹyin, ko din ni eeyan aadọjọ (150) to ti doku ninu awọn ikọlu to waye ni Plateau, Kebbi, Katsina ati ipinlẹ Benue.

Ikọlu meji to waye ni Benue leralera yii, waye laaarin ọsẹ meji ti Aarẹ Bola Tinubu fi wa lorilẹede France fun iṣẹ ilu.

Ipaniyan to lagbara to ti waye yii lo mu ọpọ awọn alẹnulọrọ ni Naijiria lati maa pe Aarẹ Tinubu pe ko pada sile lati koju ai si aabo to n pa awọn ọmọ Naijiria ku.

Ṣugbọn nigba ti wọn n fesi, ileeṣẹ Aarẹ sọ pe Tinubu ti sọ ohun ti awọn ẹṣo alaabo rẹ yoo ṣe lati yanju iṣoro yii, bo tilẹ jẹ pe Aarẹ ko si nile.

Ọjọ Aje ni Aarẹ Tinubu yoo pada si Naijiria, gẹgẹ bi atẹjade to ti ileeṣẹ rẹ jade ṣe sọ.