Natasha Uduaghan bèèrè ààbò lọ́wọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tí àwon agbébọn kọlu ilé rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti-Uduaghan/ Facebook
Natasha Akpoti-Uduaghan, sẹnetọ to n ṣoju aarinbGbungbun Kogi tẹlẹ, ti rọ ọga agba ọlọpaa Naijiria lati da awọn agbofinro to n ṣọ ọ tẹlẹ pada fun un.
Natasha sọrọ yii l'Ọjọbọ, lẹyin ti ikọ agbebọn kan kọlu ile mọlẹbi rẹ to wa ni Obeiba-Ihima, nipinlẹ Kogi.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin aṣofin tẹlẹ naa fi sita ni wọn ti ṣalaye, pe lasiko ti aburo Natasha to jẹ ọkunrin, lọ si ilu rẹ pẹlu awọn agbaṣẹṣe kan ni awọn agbebọn ọhun ṣọṣẹ.
Gẹgẹ bi Natasha ṣe ṣalaye, o ni awọn agbebọn ọhun ro pe oun wa nibi abẹwo naa ni.
O ni idi niyẹn ti wọn fi kọlu ile ti wọn ro pe oun wa naa.
Ninu iṣẹlẹ to waye lọjọ Iṣẹgun naa ni wọn ti ba ile mọlẹbi Natasha jẹ, eyi ti i ṣe ile baba to bi aṣofin tẹlẹ naa.
Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?
Gẹgẹ bi Natasha funra ẹ ṣe ṣalaye, o ni:
"N'ijẹta, aburo mi ọkunrin mu awọn agbaṣẹṣe kan lọ si ilu mi; Ihima, lati wo aaye ti wọn yoo lo fun awọn iṣẹ kan ti mo gba fun agbegbe mi.
"Awọn agbebọn yen ro pe mo ti de sile ni, wọn si waa kọlu ile mọlẹbi mi lalẹ ọjọ naa.
"Ọpẹlọpẹ awọn ikọ Aabo ara ẹni laabo ilu (Civil Defence) atawọn araalu to le wọn lọ.
"A ti fi iṣẹlẹ naa to agọ ọlọpaa agbegbe leti, a si dupẹ pe wọn ko ṣe ẹnikẹni leṣẹ.
''A rọ ọga agba ọlọpaa lati tete da awọn ẹṣọ mi pada kia."
Natasha ni kawọn araalu ma mikan lori iṣẹlẹ yii, o ni ki wọn ṣaa maa ṣe atilẹyin fun idajọ ododo.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta 2025 ni wọn ko awọn ẹṣọ to n ṣọ sẹnetọ tẹlẹ naa kuro lẹyin rẹ .
Wọn da a duro lẹnu iṣẹ fun oṣu mẹfa, wọn si tun mu adinku ba owo oṣu rẹ.
Gbogbo eyi waye latari ẹsun ifi-ilọkulọ-lọ-ni nipa ibalopọ, eyi ti Natasha fi kan Godswill Akpabio, olori ile igbimọ aṣofin agba.
Ọrọ naa lo di ohun ti wọn kọwe ifisun oriṣiiriṣii nipa ara wọn, to si wa nilẹ titi di asiko yii.














