"Wọ́n fẹ́ pààyàn ni" - BBC ṣe ìdánimọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tó yìnbọn p'àwọn tó ṣèwọ́de tako owó orí tuntun ní Kenya

- Author, Bertram Hill & Tamasin Ford
- Role, BBC Africa Eye
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
BBC ti ṣe idanimọ awọn ẹṣọ eleto abo lorilẹede to yinbọn awọn oluwọde tako owo ori tuntun lorilẹede Kenya lọdun 2024.
Iwadii BBC lori fọto bii ẹgbẹrun fi han pe ko si nnkan ija oloro kankan lara awọn ti wọn yinbọn pa naa.
Iwe ofin Kenya faye gba ṣiṣe iwọde wọọrọwọ, ipaniyan to waye naa si ti fa awuyewuye bayii.
Bo tilẹ jẹ pe ile aṣofin agba Kenya ti paṣẹ pe ki igbimọ IPOA to n ri si ọrọ awọn ọlọpaa ṣe iwadii iṣẹlẹ naa, wọn ko tii gbe esi iwadii naa sita lori iṣẹlẹ ọhun.
Iwadii BBC lori iṣẹlẹ to waye nile aṣofin agba Kenya fidi rẹ mulẹ pe ọta ibọn ọlọpaa kan ati sọja kan lo pa awọn oluwọde.
Bayii ni BBC Africa Eye ti ṣe itọpinpin awọn nnkan to ṣẹlẹ bẹrẹ pẹlu bawọn aṣofin ṣe wọle lati dibo lori ofin owo ori tuntun to fi dori bawọn oluwọde ṣe yabo oju popo ti wọn ti n ṣe ifẹhonuhan.
Ikilọ: Aworan oku eeyan wa ninu iroyin yii
Awọn ọdọ ti ọpọ mọ si Gen Z ko ara wọn jọ lori itakun ayelujara ti wọn si yabo oju popo ni igboro ilu Nairobi ti i ṣe olu ilu Kenya laarọ kutu fun iwọde lati tako owo ori tuntun ti ijọba kede rẹ.
Boniface Mwangi to jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan sọ pe ''ọpọ awọn ọdọ lo jade pẹlu omi lọwọ wọn, ni ṣe lo dabi ẹni pe ajọdun la n ṣe.''




Iwọde tawọn ọdọ n ṣe lo jẹ ki ile aṣofin fagile owo ori ti araalu n san lori burẹdi, ororo, foonu ati ọkọ to fi mọ iledii ọmọ ikoko ati paadi tawọn obinrin maa n lo fun nnkan oṣu.
Awọn ọna mii ti ijọba fẹ gba lati ṣe akojọ $2.7bn lati mu adinku ba owo yiya lati ilẹ okeere ati ṣiṣe afikun owo ori ọja to n wọ Kenya.
Mwangi ni igba akọkọ ree tawọn araalu n tako awọn to n ṣejọba lori wọn.
Ibikan ṣoṣo tawọn oluwọde naa ni lọkan lati lọ naa ni ile aṣofin nibi ti wọn ti n ṣofin to kan araalu.
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn oluwọde lo yabo ile aṣofin lati origun mẹrẹẹrin ilu Nairobi.

Ademba Allans to jẹ akẹkọọ akọroyin sọ pe ọjọ ti iwọde ọhun waye ko yatọ si awọn ọjọ miran foun.
Bi ifẹhonuhan naa ṣe n lọ lawọn eeyan n gbe sori itakun ayelujara bii TikTok and Instagram, nigba tawọn ileeṣẹ tẹlifisan naa gbe iwọde ọhun sori afẹfẹ.
Awọn ẹṣọ eleto abo kọkọ yin tajutaju sawọn oluwọde naa kawọn ọlọpaa to bẹrẹ si ni maa yinbọn ti ọta rẹ ko pa eeyan.
O le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan to wa loju popo ni nnkan bi ago kan ọsan fun iwọde naa.
Allans sọ pe bayii lawọn eeyan n pọ si i tawọn ọlọpaa si n ti wọn sẹyin.
Amọ, awọn aṣofin ko da eto idibo wọn duro bawọn oluwọde ṣe pọ to nita.
Ki o to di ago meji, awọn oluwọde ti ti awọn ọlọpaa de ila oorun ile aṣofin agba Kenya.
Ni nnkan bii ago meji kọja iṣeju mẹrin ni awọn buwọlu ofin owo ori tuntun naa nibi ti aṣofin 195 ti faramọ aba naa ti eeyan 106 si tako o.
Bayii ni awọn aṣofin alatako jade ti awọn olufẹhonuhan si mọ pe ile aṣofun ti buwọlu ofin owo ori tuntun naa.
Allans ṣalaye pe ''nigba tawọn eeyan bẹrẹ si ni sọ pe awọn ṣetan lati ya wọ inu ile aṣofin lati le jẹ kawọn ọmọ ile aṣofin mo erongba wọn lori ofin ti wọn ṣẹṣẹ buwọlu.''
Ni nnkan bi ago meji kọja ogun iṣẹjẹ lawọn oluwọde fi ipa fo awọn nnkan tawọn ọlọpaa fi di wọn lọna ti wọn si bẹrẹ si ni lọ si ile aṣofin.
Wọn sọ ina si ọkọ nla ti wọn gbe siwaju ile aṣofin agba ni Nairobi, awọn eeyan bi ọgba ile aṣofin lulẹ, wọn si bẹrẹ si ni lọ sinu ile aṣofin.
Amọ, ko pẹ ko jinna tawọn ẹṣọ ilu ile aṣofin fi le wọn bọ sita.
Bi gbogbo eleyii ti n ṣẹlẹ lawọn akọroyin n ka gbogbo rẹ silẹ pẹlu ẹrọ kamẹra.
Ọkan lara awọn fidio tawọn eeyan ri ṣafihan bi ọlọpaa kan ti n pariwo ''uaa!'' ede Swahili eyi to tumọ si ''ẹ yinbọn pa wọn.''
Lẹyin naa ni ọlọpaa kan kunlẹ, tawọn eeyan si n gbọ iro ibọn, bayii ni oluwọde meje ṣubu laari ero.
David Chege, onimọ ẹrọ ẹni ọdun 39 ati Ericsson Mutisya, alapata ẹni ọdun 25 fara gbọta, wọn gba ibẹ ku.
Awọn eeyan marun un mii fara pa, koda, ọkan lara wọn rọ lẹsẹ.

Fidio kan ṣafihan bi Allans ṣe fẹ sun mọ Chege ati ẹnikan ti ẹjẹ n da lara rẹ lẹyin ti ibọn ti ba wọn.
Amọ, awọn wo lo yinbọn fun wọn?
Ninu fidio to ṣafihan ọlọpaa to n pariwo ''uaa!'', ẹni to yinbọn naa kọ ẹyin si kamẹra.
BBC ṣe afiwe ihamọra ati koto ti ọlọpaa naa wọ pẹlu irufẹ ihamọra tawọn ọlọpaa mii wọ nibi iṣẹlẹ naa.
BBC ṣe iwadii lori ẹni to yinbọn naa, a si ri pe o fi oju rẹ pamọ ki o to yinbọn saarin awọn oluwọde. BBC kọ mọ orukọ rẹ bakan naa.
Lẹyin to yinbọn si aarin ero tan ni ọlọpaa naa tun sọ fawọn akẹgbẹ rẹ lati maa yinbọn pa awọn eeyan lọ.
Ọpọ eeyan lo ti fọ fun BBC pe agọ ọlọpaa to wa ni aarin gbungbun ilu Nairobi ni ọfiisi ọlọpaa naa.
BBC sọrọ yii fun ileeṣẹ ọlọpaa Kenya, ṣugbọn wọn ni awọn ko le ṣe iwadii ara wọn wi pe ajó IPOA lo le ṣe iwadii lori iwa ibajẹ ọlọpaa.
Wọn ko tii mu ẹnikankan fun iku Chege tabi Mutisya titi di akoko yii.


Amọ, kii ṣe awọn eeyan yii nikan lo ku tori awọn oluwọde tun mori le ile aṣofin leyin tawọn ọlọpaa ti yinbọn pa awọn eeyan kan.
Ọpọ eeyan lo kawọn wọn soke bi wọn ti n wọ ile aṣofin lọ pada, awọn mii mu asia orilẹede Kenya lọwọ.
Awọn ọlọpaa tun yinbọn soke lati kilọ fawọn eeyan, awọn oluwọde naa kọkọ fara balẹ diẹ, amọ, wọn ya bo inu ile aṣofin tawọn mii ninu wọn si n ka nnkan to n ṣẹlẹ pẹlu foonu wọn.
Bi wọn ṣe wọle tan ni nnkan daru, awọn oluwọde kan fi ipa ja ilẹkun, wọn si tun sọna si apa kan ile aṣofin naa eyi to mu kawọn aṣofin to ku ninu ile fẹsẹ fẹẹ.
Ni nnkan bii ago mẹta ọsan ni ibọn to ro tawọn oluwọde si bẹrẹ si ni fo ọgba ile aṣofin naa.
Lẹyin ti eruku ati eefin lọọlẹ tan ni fidio kan ṣafihan eeyan mẹta nilẹ.
Eeyan meji ti fara pa, ẹnikan ninu wọn nawọ soke amọ ko le dide.
Iwadii BBC tun fi han pe awọn eeyan to ṣubu lulẹ naa ko ni nnkan ija oloro lara bii ti Chege ati Mutisya.
BBC Africa Eye yanana fọto 150 tawọn kan ya ṣaaju ati lẹyin igba ti wọn yinbọn fun Shieni.
A ṣe idanimọ sọja kan to yinbọn, amọ, a o mọ orukọ rẹ bakan naa.
Faith Odhiambo to jẹ aarẹ igbimọ to n ri si ọrọ ofin ni Kenya sọ pe ko si aniani ninu fidio to ṣafihan ohun to ṣẹlẹ.
''Erongba wọn ni lati paayan, wọn le fọwọ ofin mu ẹni ti wọn yinbọn pa.
Bi wọn ṣe yinbọn fun un lori fidi rẹ mulẹ pe wọn ni erongba lati paayan.
Ileeṣẹ ologun Kenya KDF sọ fun BBC pe ajọ IPOA ko tii sọ fawọn lati ṣewadii lori ẹnikankan ninu awọn ẹṣọ eleto abo to ṣiṣẹ nile aṣofin lọjọ ti iwóde naa waye.
Lẹyin ti wọn ti yinbọn ni a ri Allans nibi to ti gbe ẹni ti ibọn ba ti ẹjẹ n da lara rẹ.
O ni ''ẹru ba mi, mo ti kọkọ ro pe awọn obi mi ko ni ri mi mọ ni.
Bakan naa ni mi o tun fẹ kawọn ku nigba ti mo le ṣe iranwọ.''
Lẹyin ti ifẹhonuhan ti waye fun ọsẹ kan, ajọ to n ri si ẹtọ ọmọniyan ni Kenya, KNCHR kede pe eeyan 39 lo ku ti 361 si farapa kaakiri orilẹede Kenya.
Lalẹ ọjọ naa ni Aarẹ William Ruto gboṣuba fawọn ẹṣọ eleto abo lori bi wọn daabo bo orilẹede naa lọwọ awọn ''ọdaran'' to fẹ ja iwọde ti araalu ṣe gba.
Ni ọjọ keji ni ijọba paṣẹ idaduro ofin owo ori tuntun naa.
Aarẹ Ruto sọ lori tẹlifisan wi pe oun ti gbọ nnkan tawọn eeyan Kenya n sọ wi pe awọn o fẹ ofin lori owo ori tuntun, o si ni oun ko ni buwọ lu u.
Amọ, to fi di akoko yii, ijọba ko tii gba ẹsọ eleto abo kankan mu lori ẹni to yinbọn pa awọn oluwọde.
Bakan naa, esi iwadii lori iṣẹlẹ ipaniyan lasiko iwọde ọhun ko tii jade titi di oni.















