FBI mú èèyàn 22 ní Naijiria fún ẹ̀sùn fífi àwòràn ìhòhò lu jìbìtì lórí ayélujára

Aworan oṣiṣẹ FBI ati eeyan meji miran

Oríṣun àwòrán, FBI

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹka Federal Bureau of Investigation (FBI), to n tọpinpin ti mu eeyan mejilelogun ni Naijiria, lori ẹsun pe wọn n fi aworan ihoho awọn eeyan lu wọn ni jibiti lori ayelujara.

Gẹgẹ bi FBI ṣe wi loju opo wọn, awọn ọmọde ilu America ni awọn eeyan naa n lu ni jibiti ọhun ju.

Wọn fi kun un pe eto "Operation Artemis," tawọn bẹrẹ ni 2023 lati gbogun ti awọn ọmọ Naijiria to n huwa yii lo jẹ kawọn ri eeyan 22 mu bayii.

Ajọ EFCC ilẹ Naijiria ati FBI ni iroyin sọ pe wọn jọ ṣiṣẹ pọ lati fi oju awọn ọmọ Naijiria to n lu jibiti naa han.

FBI fidi ẹ mulẹ, pe idaji awọn tọwọ bayii ni awọn to lugbadi wọn ti pa ara wọn danu.

O ni iku awọn ọdọkunrin America ti ọjọ ori wọn ko ju mẹrinla si mẹtadinlogun lọ n pọ si i, awọn onijibiti lati Naijiria to n ba wọn dowopọ lo si fa a.

Báwo ni wọ́n ṣe ń fi fọ́to ìhòhò lu jìbìtì?

Bi FBI ṣe ṣalaye, iwa ọdaran nla ni fifi fọto ihoho lu jibiti lori ayelujara.

Ajọ naa sọ pe nigba ti ẹnikan ba ni fọto ihoho ẹnikeji lọwọ, to si n dunkooko lati ju fọto naa si ori ayelujara bi ẹni to ni fọto naa ko ba fun un lowo ni a mọ si jibiti ori ayelujara.

Wọn fi kun un pe onijibiti naa tun le maa dunkooko lati ṣe ijamba fun awọn ẹbi tabi ará ẹni ti wọn ni fọto ihoho rẹ lọwọ.

Afi bi wọn ba fi owo nla tabi ẹbun olowo nla ranṣẹ si onijibiti naa.

Lẹyin ti onijibiti ba gbowo tabi ẹbun tan, yoo tun pada fi fọto naa si ori ayelujara.

Eyi ni wọn lo n fa a ti ọpọ ọmọde America to ba ko si wọn lọwọ fi maa n pa ara wọn nitori itiju ati idẹyẹsi.

FBI loun bẹrẹ iwadii lori iwa yii nigba ti olobo ta oun lori ọna ọgbọn tawọn onijibiti naa n gba ṣiṣẹ ni Naijiria, laaarin oṣu Kẹwaa ọdun 2024 ati oṣu Kẹta 2025.

Ẹka ifisun wọn ti gba aroye ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn (34,000) ni 2023, ọmọde ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta (54,000) ni wọn lo foriko jibiti naa ni 2024.

Laaarin ọdun meji sẹyin, owo to to $65 lo ti wọgbo, nigba ti awọn ọdọ to le ni ogun (20) si ti pa ara wọn, gẹgẹ bi iwadii FBI.

Bi àwọn oníjìbìtì ṣe n fa ikú àwọn tó bá kó sí wọn lọ́wọ́

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ibanidọrẹẹ lori ayelujara ni ọna akọkọ ti awọn onijibiti oju opo naa maa n gba wọle si eeyan lara.

Wọn yoo ṣe bii pe ẹgbẹ ni awọn atẹni ti wọn fẹẹ mu, wọn le purọ ẹya ti wọn jẹ pẹlu, ki ọkunrin sọ pe obinrin loun.

Lọgan ti ibadọrẹ ba ti bẹrẹ, ti wọn ti n fi atẹjiṣẹ ṣọwọ sira wọn, onijibiti yoo tan ẹnikeji, pe ko fi aworan ihoho rẹ ranṣẹ.

Yoo sọ fun alaimọkan naa pe oun pẹlu yoo fi toun ranṣẹ si i.

O le fi ranṣẹ loootọ, ṣugbọn ofege ni.

Kete ti fọto naa ba sọlẹ si onijibiti lọwọ, yoo bẹrẹ si i dunkooko mọ ẹni to pe lọrẹ yii, yoo ni oun yoo ju fọto naa si ori ayelujara fun gbogbo aye, afi to ba fowo nla tabi ẹbun ranṣẹ soun.

Ẹsẹkẹsẹ ni yoo maa beere owo ọhun, yoo ni ko wa gbogbo ọna lori ayelujara lati fi owo naa ṣọwọ kia.

Boya iyẹn wa fi owo naa ranṣẹ tabi bẹẹ kọ, onijibiti ayelujara yoo ju fọto naa si igboro ayelujara fun gbogbo aye.

Eyi yoo ba ẹni to ni fọto naa lọkan jẹ, itiju yoo dapọ mọ ibanujẹ ọkan, nigba naa ni wọn si maa n gba ẹmi lẹnu ara wọn.

Ọrọ yii kan awọn ọmọ Naijiria naa.

Loṣu Kẹsan-an ọdun 2024, ijọba America ran ọmọ iya kan naa meji lẹwọn lori ẹsun yii.

Samuel ati Samson Ogoshi ni awọn eeyan naa n jẹ, ẹwọn ọdun mẹtadinlogun ati aabọ ni wọn sọ wọn si.

Adajọ Judge Robert J. Jonker, ju wọn si ẹwọn naa lẹyin ti wọn ni wọn jẹbi iku ọmọkunrin ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan, Jordan DeMay, ẹni ti wọn tan lati fi fọto ihoho rẹ ranṣẹ.

Ijọba America lo gbe wọn wọ ilu naa lati jiya ẹṣẹ wọn.

Bí o ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ oníjìbìtì tó ń lo fọ́to ìhòhò

Amoran ti Jenn Buta ati ọpọ awọn ẹka ofin fun awọn eeyan nipa fọto ihoho wọn ni:

Maa ranti pe iwọ nikan kọ lo n ṣẹlẹ si, ko si ki n ṣe ẹbi rẹ pe o ṣẹlẹ si ọ.

  • Fi ẹjọ onijibiti naa sun loju opo naa.
  • Gbegidina abala to ti n ba ọ sọrọ, ma ba a ṣọrẹ nibẹ mọ.
  • Tọju atẹjiṣẹ idunkooko to fi ranṣẹ si ọ, o le ran awọn agbofinro lọwọ lati wa a.
  • Beere iranwọ lọwọ agbalagba ti o fọkan tan ki o too fowo ranṣẹ si I, tabi ki o too fi fọto mi-in ranṣẹ.
  • Bi o ba n sowọpọ pẹlu onijibiti, iṣoro to ko ọ si ko ni I lojutuu, awọn agbofinro ni ko o fọwọsowọpọ pẹlu.
  • Ma ṣe gba lati ba ẹni ti o ko mọ ṣe ọrẹ lori ayelujara, paapaa awọn ti aworan wọn ko fi otitọ han.
  • Ṣọra fun ọrẹ ti yoo ni ko o jẹ kẹ ẹ gbe ọrọ yin lọ si WhatsApp.
  • Ma ṣe fi foonu re ya fọto ihoho rẹ, ma ṣe fi fọto tabi fidio ihoho rẹ sori foonu rẹ.
  • Ṣọra fun ipe onifidio pẹlu awọn eeyan ti o ko mọ.
  • Ma ṣe pin fọto rẹ lori ayeluajara, boya fun gbogbo aye tabi nipa fifi ranṣẹ si ẹnikan.
  • Ṣọra fun awọn atẹjiṣẹ ti o ko mọbi to ti wa ṣugbọn to n ṣeleri owo tabi iṣẹ.