Ẹ fura o! Èèyàn 135,000 ló ní HIV l'Eko nìkan - Wo bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọdun 2022, ajọ NACA ni kaka ko san lara orilẹede Naijiria nipa aarun HIV, nise ni iye awọn to n ko aarun naa n pọ sii.
Ajọ ọhun ni kaakiri Naijiria ni aarun naa ti peleke si i.
Ṣugbọn o fẹ da bi pe ipinlẹ Eko ni nọmba to pọ diẹ ninu iye eeyan to ni aisan HIV lara.
Kọmisanna fun eto ilera nipinlẹ Eko, Akin Abayomi ni, eeyan to le ni 135,000 lo n gbe pẹlu aarun HIV nipinlẹ Eko.
Abayomi sọ eyi nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ọfisi ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Alausa, Ikeja.
"Eeyan 135,224 lo ni aisan HIV nipinlẹ Eko ," o ṣalaye.
Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni Aarẹ ilẹ America, Donald Trump pẹlu oludamọran pataki rẹ lorii bi wọn yoo ṣe maa ṣọ owo America na, Elon Musk, kede pe awọn yoo fagile ajọ Oluranlọwọ agbaye, USAID.
Ajọ naa lo wa fun iranwọ ọlọkan-o-jọkan, paapaa lẹka ilera fun awọn orilẹede agbaye.
Ọkan pataki lara ibi ti ọwọ aanu USAID si de ni ọdọ awọn to n gbe ile aye pẹlu aarun ko gboogun, HIV.
Awọn eeyan naa n ri oogun ati itọju ọfẹ gba ni irọrun nipasẹ USAID ti Trump fagile.
Eyi lo tu mọ si pe, o ṣeeṣe ki ẹnikẹni to ba lugbadi aisan naa lọwọ yii ma ni anfaani si itọju ọfẹ gẹgẹ bii o ṣe ti wa tẹlẹ.
Ọna lati ko aarun yii ati lati da bobo ara rẹ
Lati pese aabo fun ara rẹ lọwọ aisan HIV, yiyago fun ibalopọ lai lo rọba idaabo bo jẹ ohun to ṣe pataki.
Ọpọ alaye ati iwadii lo ti fidi rẹ mulẹ pe, ọpọ iṣẹlẹ kiko aisan HIV lo wa lati ibi ibalopọ lai lo rọba idaabo bo, ti a tun mọ si kọndọọmu.
Awọn onimọ tun gba awọn eeyan ni imọran pe ki wọn yago patapata fun ibalopọ ti wọn ko ba finu tan ẹnikeji wọn.
Ona to fi le lugbadi aisan HIV
- Ibalopọ: Bi ba eeyan to ni HIV sun lia lo ruba idabobo le ṣokunfa kiko aisan HIV
- Pinpin abẹrẹ lo: Pinpin abẹrẹ lo pẹlu eeyan to ni aarun HIV le fa ki eeyan naa ni aisan naa.
- Iya si Ọmọ :Iya to aisan HIV le fun ọmọ to ṣẹṣẹ bi HIV latara ibi, fifun ni ọyan ati lasiko oyun nini.
- Ẹjẹ didapọ: Ti eeyan to ni HIV ba dapọ mọ eeyan ti ti ko ni, irufẹ eeyan bẹẹ yoo ni aarun kokor HIV.
Ohun to jẹ iyanilẹnu nipa aisan yii ni pe, kii ṣe ibi ibalopọ nikan ni ẹ ti le ko aisan yii, ọpọ ọna miiran lo wa ti eeyan fi le lugbadi aarun HIV.
Pinpin abẹrẹ lo jẹ ọna miiran ti eeyan fi le ko HIV.
Awọn onimọ ijinle sayẹnsi, ni ọdun 2017 kede pe, awọn ti ṣawari oogun Antibody to n gbe oogun ti Kokoro HIV ninu ara .
Ẹyi jẹ ọna tuntun ti iwosan fi n de ba awọn eeyan to ni aarun yii lara.
Awọn onimọ ni awọn ni n dan oogun yii wo ni ara ọbọ ki wọn to gbe sita fun lilo awọn eeyan.
Bi o ba wa ri pe o ti lugbadi HIV, o ṣe koko ki o tete gba ọdọ dokita lọ lati bẹrẹ itọju.
O ṣe koko ki eeyan to ba ṣẹṣẹ nii tete bẹrẹ itọju lati ma ṣokunfa awọn ijamba miiran to dirọ mọ aisan naa.















