Bí ètò ìsìnkú Pope Francis yóò ṣe wáyé àti àwọn èèyàn tí yóò wà níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eto isinku Pope Francis yoo waye ni Vatican ni owurọ ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin.
Ọjọ Aje ni Pope Francis ku, lẹni ọdun mejidinlọgọrin.
Saaju ni Vatican fi aworan oloogbe naa ninu poosi sita ati awọn eto mi nipa isinku naa.
Ni Ọjọru, oku oloogbe yoo wa ni St Peter Basilica fun ọpọ lati ri .
Wọn yoo sin Pope Francis si St Mary Major Basilica (Santa Maria Maggiore), gẹgẹ bi o ṣe beere fun nigba to wa laye.
"Mo ni igbagbọ nla ninu St Mary Major, koda ki n to di Poopu," Francis sọ ninu iwe rẹ to kọ lọdun 2024, El Sucessor.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Iwe Iroyin Times, olori fun liturgy, Fada Ivan Ricupero ni, Pope Francis ti wa si St Mary ni ọpọ igba (125) lati igba to ti di Poopu, to si n wa pẹlu ododo.
Wọn da ile ijọsin naa silẹ ni 432, ọdun kan lẹyin ti igbimọ Ephesus kede Mary gẹgẹ bi iya Ọlọrun. O wa ni bii kilomita mẹrin si Vatican.
Francis ni ẹni akọkọ lẹyin Leo XIII, ẹni to ku ni ọdun 1903, ti wọn yoo sin sita Vatican.
Adura Rosary yoo waye ni aṣalẹ yii ni Rome ati Vatican
Adura rosary yoo waye lonii ni Vatican ni gbọngan St Peter lati ṣe iranti Pope Francis, eto naa yoo bẹrẹ ni ago meje abọ (18:30 BST, 17:30 GMT).
Adura mii yoo waye ni ago mẹsan an ni Basilica ni St Mary Major ni Rome, ti akọwe Vatican, Cardinal Pietr Parolin yoo lewaju fun.
Bawo ni iṣẹlẹ Ọjọru yoo ṣe waye?

Vatican ni oku Pope Francis yoo gbera lọ si St Peter Basilica ni Ọjọru.
Eyi awọn nnkan ti yoo ṣẹlẹ:
Poosi to n gbe Poopu yoo gbera kuro ni Casa Santa Martato lọ si St Peter Basilica ni ago mẹsan an.
Cardinal Kevin Farrell ni yoo lewaju adura ki wọn to gbe oku naa.
Wọn yoo rin gba Piazza Santa Marta ati Piazza dei Protomartiri Romani ko to wọ St Peter Basilica.
Cardinal Farrell ni yoo lewaju fun ọrọ liturgy, ti yoo si tun ma a ka ọrọ lati inu Bibeli.
Poosi Poopu yoo wa ni ita fun awọn eeyan lati bu ọla ikẹyin fun un, titi eto isinku yoo fi waye ni ọjọ Abamẹta.
Ta ni yoo wa nibi eto isinku naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn olori kaakiri agbaye ni wọn ti kede pe awọn yoo wa nibi eto isinku Pope ni ọjọ Ṣatide, eyi ti yoo waye ni St Peter Basilica.
Ọmọọba William yoo wa nibi eto isinku naa lati soju Ọba Charles III.
Donald Trump, Emmanuel Macron ati Volodymyr Zelensky naa pẹlu awọn eeyan ti yoo waye nibi eto isinku naa.
Eyi ni awọn eeyan mii ti wọn ni yoo w ani bi eto isinku naa:
- German Chancellor Olaf Scholz wa lara awọn ti wọn n reti
- Aarẹ Brazil, Luiz Inácio Lula da Silva, ẹni ti wọn ni o ni ajọsepọ nla pẹlu Pope, naa yoo wa ni Vatican City fun ayẹyẹ naa
- Aarẹ Poland, Andrzej Duda naa yoo wa nibi eto isinku naa, to si tun ti kede ọjọ Ṣatide gẹgẹ bii ọjọ idaro ni orilẹede rẹ.
- Aarẹ EU, Ursula von der Leyen naa ti fidi rẹ mulẹ pe oun yoo wa nibi eto isinku naa.
- Aarẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky naa yoo farahan.
- Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ati Aarẹ France, Emmanuel Macron naa ti kede pe awọn yoo wa nibi eto isinku naa.
- Javier Milei, Aarẹ Argentina – ilu ibi Pope Francis – kede pe oun yoo wa nibi ayẹyẹ naa.
- Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Keir Starmer naa yoo pẹlu awọn olori agbaye ti yoo wa nibi ayẹyẹ naa.
- Ọba Felipe VI ati Olori Letizia ti orilẹede Spain naa yoo wa nibi ayẹyẹ naa.
- Ọmọọba Wales yoo ṣoju Ọba Charles III ni bi ayẹyẹ eto isinku naa.


Oríṣun àwòrán, EPA

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, EPA

Oríṣun àwòrán, Reuters











