Ṣe ó ṣeéṣe kí wọ́n yan Póòpù tuntun láti Africa?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Lebo Diseko
- Role, Global Religion Reporter
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
To ba jẹ bi ijọ Aguda ṣe n dagba si ni wọn fi n yan Poopu ni, ilẹ adulawọ lo yẹ ki wọn ti yan Poopu to kan.
Ilẹ adulawọ ni ijọ Aguda ti n dagba julọ ni gbogbo agbaye.
Ni Afrika, ijọ ọhun pọ si ni ida 3.31% laarin ọdun 2022 si 2023, ti atẹjade lati Vatican si fi han pe pe 20% awọn ọmọ ijọ naa lo n gbe ni Afrika.
Ni Europe, idagbasoke ijọ Aguda nibẹ ko pọ rara nitori bi idagbasoke wọn ṣe jẹ ida 0.2% pere.
Laarin 1910 si 2010, awọn ọmọ ijọ naa dinku si i pẹlu ida 63% gẹgẹ bii atẹjade ajọ Pew Research Centre.
Eyi n tumọ si pe, agbegbe naa ti awọn Kristẹni pọ si tẹlẹ ti n ya kuro ninu ilana naa bayii.
Ni Latin America, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ko iyan ijọ Aguda kere nibẹ, awọn ijọ igbalode ti n gba ade mọ ijọ naa lọwọ nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Laipẹ ti awọn 'cardinals' to n yan Poopu ba bẹrẹ igbesẹ lati yan adari tuntun fun ijọ naa, ṣe ibi ti ẹni ti wọn yoo ti yan ẹni to kan ti wa ṣe pataki ninu igbesẹ wọn bi?
Alufaa Stan Chu Ilo, to jẹ ọmọ Naijiria ati ọjọgbọn ni fasiti Depaul gbagbọ bẹẹ.
O ni "Mọ ro pe yoo dara ti Poopu ba wa lati ilẹ Africa."
Lati akoko Pope Francis ni awọn alufaa lati ilẹ Africa ti pọ si lati ida 9% si 12% lọdun 2022.
Lara awọn alufaa naa, iyẹn 'cardinals' ni yoo yan Poopu tuntun.
Chu Ilo sọ pe eyii ko tumọ si pe wọn maa yan Poopu tuntun lati Africa amọ o ṣeeṣe ki wọn yan ẹni to gbajumọ daadaa ti ipo rẹ si ga lara awọn ti ipo naa tọ si.
O ni "iṣoro to wa nibẹ ni pe, ko si ẹnikankan to wa ni ipo agbara ni Vatican to jẹ ọmọ ilẹ Africa.
"Ti o ba wo awọn alufaa lati ilẹ adulawọ to ṣeeṣe ko de ipo Poopu, ko si ọmọ Africa kankan ninu wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọ ọrọ Chu Ilo yii tako ohun to ṣẹlẹ lọdun 2013 ti ọmọ orilẹede Ghana, Peter Turkson du ipo naa, ati igba ti ọmọ Naijiria, Francis Arinze du ipo ọhun lọdun 2005 ti wọn yan Pope Benedict XVI.
Chu Ilo sọ pe "Bo ṣe buru to bayii fun ilẹ Africa ninu ijọ Aguda ni ko ye wa, o jẹ ohun iyalẹnu fun gbogbo wa paapaa bi Pope Francis ṣe fẹran Africa to o.
Ṣe ibi ti Poopu yoo ti wa ṣe pataki?
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti yan Poopu mẹta ri lati Africa, Poopu to wa lati ilẹ naa kẹyin - Pope Gelasius I – ti jade laye lati ẹgbẹrun ọdun kan abọ sẹyin.
Ọpọ eeyan lo gbagbọ bayii pe asiko ti to ki Poopu mii wa lati Africa.
Ẹwẹ, awọn ọmọ ijọ kan nilẹ Africa n sọ pe, ko tọ bi awọn kan ṣe n tẹnumọ ibi ti Poopu to kan yoo ti wa.
Lara awọn to n sọrọ yii ni Alufaa Paulinus Ikechukwu Odozor, ọmọ Naijiria to jẹ ọjọgbọn ni fasiti Notre Dame ti oun naa tun jẹ alufaa ijọ Aguda.
Odozor sọ pe "Emi o ro wi pe ipo Poopu tọ si ẹnikẹni nitori pe o jẹ ọmọ ilẹ Africa tabi ọmọ ilẹ Yuroopu.
"Ko ni i ṣe ibi ti eeyan ti wa, ni kete ti wọn ba ti yan ọ si ipo naa, iṣoro gbogbo aye ti di iṣoro ẹni naa niyẹn.
"Ohun kan ṣoṣo ni ẹni naa yoo gbajumọ, iyẹn bi idagbasoke yoo ṣe de ba ara Kristi lai ni nnkan lati ṣe pẹlu ibi ti eeyan ti wa tabi bi wọn ṣe pọ to.
O ni oun to ṣe pataki ni ki Poopu tuntun jẹ aṣaaju rere fun awọn ọmọ ijọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Odozor sọ pe o maa n dun oun ti awọn eeyan ba n bere lọwọ oun boya Africa lo yẹ ki Poopu tuntun ti wa.
O ni "o dabi kii eeyan sọ pe, ọmọ ijọ wa n pọ si ni Africa, nitori naa, ẹ jẹ ki Poopu wa lati ibẹ."
Niju iwoye rẹ, o yẹ ki ijọ gbe igbesẹ lati ran awọn eeyan rẹ ni Africa lọwọ dipo ki wọn maa ronu nipa iye ọmọ Africa to wa nipo giga ninu ijọ naa.
Alufaa ọhun sọ pe nigba mii, niṣe lo maa n dabi pe wọn ko ka Africa si, tabi pe igbagbọ wọn ko to nnkankan tabi pe wọn ko ja mọ nnkankan.
O ni "ti awọn eeyan Africa ba gbagbọ pe wọn ko ka ọrọ wọn si, nigba naa ni wọn yoo maa woye pe ko ni si apọnle kankan fun awọn ayaafi ti awọn naa ba ni eeyan loke.
Ẹlẹyamẹya ninu ijọ
Amọ alufaa Chu Ilo, gbagbọ pe bo tilẹ jẹ pe iye awọn ọmọ Africa to n jẹ cardinal pọ si, wọn ko ni agbara kankan ninu ijọ naa.
O ni "mi o fi ẹnu tẹmbẹlu awọn cardinal ti Poopu yan o amọ nigba ti o ba yan wọn, ṣe lori ẹnu lasan ni?
"Niṣe lo yẹ ki o fun awọn alufaa naa ni agbara, fun wọn ni iṣẹ ki o si gbagbọ pe wọn yoo ṣiṣẹ naa daadaa.
Awọn alufaa mejeji, Fr Chu Ilo ati Fr Odozor gbagbọ pe iwa ẹlẹyamẹya ṣi wa ninu ijọ Aguda.
Odozor sọ pe "ọrọ ẹlẹyamẹya ṣi wa nibẹ ti a ko ki n mẹnuba ninu ijọ.
"Ko si bi ẹni naa ṣe le gbiyanju to, wọn ṣi maa fi oju wo o pe Poopu alawọ dudu lasan ni.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹni to ṣeeṣe ko ja mọ lọwọ
Wayi o, ọrọ kan wa nilẹ to mu ko ṣoro lati le sọ ẹni to ṣeeṣe ki ipo naa ja mọ lọwọ.
Chu Ilo sọ pe "Ijọ Aguda gbagbọ ninu Ọlọrun, wọn gbagbọ ninu Ẹmi Mimọ pe oun ni yoo ba wọn yan ẹni ti ipo naa kan.
Eyi tumọ si pe, o ṣeeṣe ko jẹ ohun iyalẹnu nigba ti wọn yoo ba kede ẹni ti yoo jẹ Poopu tuntun.
Chu Ilo sọ pe nigba ti wọn yan Pope Francis lọdun 2013, kii ṣe oun ni ẹni ti ọpọ eeyan gbagbọ pe ipo naa yoo ja mọ lọwọ.
O pari ọrọ rẹ pẹlu adura pe ki Ọlọrun yan Poopu ti yoo tẹsiwaju iṣẹ rere Pope Francis ti ṣe silẹ ati pe yoo mu inu oun dun ti ẹni naa ba jẹ ọmọ Africa.








