Yàrá tí wọ́n ti ń ṣàkóso ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n jóná dèérú nílé ẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ Osun, ariwo sọ

Ile ẹjọ ipinle Osun

Oríṣun àwòrán, Gold Ewa Ipinle Osun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ina ti ṣẹyọ nile ẹjọ giga to wa nipinlẹ Osun.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abiodun Ojelabi, lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC Yoruba.

Ojelabi ṣalaye fun BBC pe lootọ ni ina kan ṣẹyọ nile ẹjọ naa ati pe inu yara ti awọn to n ṣakoso awọn ẹlẹwọn n lo nibẹ ni ina naa pa lara julọ, to fi mọ awọn ọọfisi mii.

O ni ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa amọ o ṣoro lati sọ pe awọn eeyan kan lo mọọmọ sọ ina sile ẹjọ ọhun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, iwadii nikan lo le ṣọ boya niṣe lawọn eeyan kan mọọmọ sọ ina naa sibẹ ni tabi ina mọnamọna lo ṣokunfa ijamba naa.

O ni "A ko le sọ pe niṣe ni wọn mọọmọ dana si ile ẹjọ naa ayafi ti a ba ṣe iwadii tan.

"Alukoro ọlọpaa fi kun pe awọn ko tii fi ṣikun mu ẹnikẹni lori ọrọ naa latari pe wọn ko le sọ boya iṣe ọwọ araalu ni tabi ina ijọba to n ṣẹju.

O fi kun pe "Ti ẹ ba de ibẹ bayii, ẹ maa ri awọn ọlọpaa nibẹ ti wọn n ṣe ọfintoto ohun to ṣokunfa ina ọhun amọ o ṣoro lati sọ ohun to fa a lai kọkọ pari iwadii."

Kii ṣe igba akọkọ ti wọn yoo sọ ina si ile ẹjọ naa ree - Ẹgbẹ oṣiṣẹ ile ẹjọ

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ ni Naijiria, JUSUN, ẹka ti ipinlẹ Osun ti juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyii ti awọn kan mọọmọ ṣe.

Alaga ẹgbẹ ọhun, Idris Adedayo Adeniran, lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi lede.

JUSUN ni niṣe ni awọ n kọlọrọsi ẹda kan mọomọ dana sun ile ẹjọ naa nibi ti wọn ti jo awọn iwe ile ẹjọ to ṣe pataki.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn eeyan kan yoo dan sun ile ẹjọ naa, koda, igba kẹta ti irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ yoo waye ree.

JUSUN ni "Irufẹ ikọlu bayii n gbogun ti agbara ofin ati idajọ ododo nipinlẹ Osun.

"Kii ṣe igba akọkọ ti wọn yoo dojukọ ile ẹjọ yii ree, igba kẹta irufẹ ikọlu yii ree lẹyin iru rẹ to waye ninu oṣu Keji ọdun 2017 ati eyii to waye lọdun 2021.

"Iṣẹlẹ yii n kọ wa lominu fun alaafia ile ẹjọ atawọn oṣiṣẹ ile ẹjọ naa."

Lẹyin naa lo ke si gomina Ademola Adeleke ko wa nnkan ṣe si ọrọ ọhun.