CCTV ṣàfihàn bí àwọn agbébọn ṣe yìnbọn pa ọmọ Naijiria tó ń ṣiṣẹ́ awakọ̀ ní America

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ̀rọ ayàwòrán CCTV kan ti ṣàfihàn báwọn agbébọn ṣe yìnbọn, tí wọ́n sì pa ọmọ Nàìjíríà, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tó ń ṣiṣẹ́ awakọ̀ Uber ní Philadelphia orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà.
Lásìkò tí awakọ̀ náà fẹ́ lọ gbé èrò ní ilé ìgbafẹ́ kan ní Center City hookah lounge lọ́jọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kẹrin.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Philadelphia ti fìdí fọ́nrán tó ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ṣekúpa awakọ̀ kan náà, tó gba orí ayélujára múlẹ̀.
Fídíò náà ṣàfihàn bí wọ́n ṣe yìnbọn pa ọkùnrin náà àti èrò tó gbé ní ooru ọjọ́rú, ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Kẹrin.
Iléeṣẹ́ ìròyìn CBS News sọ pé lásìkò tí awakọ̀ ọmọ Nàìjíríà náà, Olatunji Bolaji tó ń gbé ní Norristown wà nínú ọkọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ṣekúpa á.
Ní nǹkan bíi aago méjì òru ló páàkì ọkọ̀ rẹ̀ síwájú 18th Street gẹ́gẹ́ bí nǹkan tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ.
Àwọn agbébọn náà yìnbọn mọ́ Bolaji lórí tí wọ́n sì gbìyànjú láti wa ọkọ̀ rẹ̀ lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan 18th Street. Lẹ́yìn náà ni wọ́n yà sí Chestnut Street tí wọ́n sì fi ọkọ̀ náà kọlu òpó iná ojúpópó.
Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera sọ pé ojú ẹsẹ̀ tí wọ́n ti yìnbọn fun ló ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí èrò tó gbé?
Àwọn agbébọn náà ṣe ìkọlù sí èrò tí Bolaji gbé, ẹni ọdún méjìlélógún, ní apá, ẹsẹ̀ àti ikùn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ni, wọ́n gbe lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nítorí ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run ni òun náà wà.
Ẹ̀rọ ayàwòrán kan tó wà nílé ẹnìkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ṣàfihàn bí Olatunji Bolaji ṣe páàkì ọkọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ ní nǹkan bíi aago méjì òru.
Àwọn èèyàn mẹ́rin kan jáde láti ilé ìgbáfẹ́, tí wọ́n sì rìn lọ síbi ọkọ̀ rẹ̀.
Lẹ́yìn náà ni ọkùnrin kan, ẹni ọdún méjìlélógún, ṣílẹ̀kùn tó wọnú ọkọ̀ Bolaji táwọn ọkùnrin méjì kan sì sáré lọ bá a, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ṣíná ìbọn bolẹ̀ fun.
Àwọn olùwádìí sọ pé kò sí ìfaǹfà tàbí àjọsọ kankan láàárín èrò náà àtàwọn agbébọn náà ṣáájú kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé.
Àwọn olólùfẹ́ Bolaji ṣelédè lẹ́yìn rẹ̀
Àwọn alábàágbé Bolaji sọ fún NBC10 sọ pé ohun ìbànújẹ́ ló jẹ́ fún àwọn láti gbọ́ nípa ikú Olatunji Bolaji, tí wọ́n sì júwe rẹ̀ àtàwọn ẹbí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kìí fa wàhálà.
Bákan náà ni wọ́n júwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akínkanjú èèyàn.
Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ ẹbí Bolaji tó ti ń gbé pẹ̀lú Bolaji fún ọdún pípẹ́ sọ pé èèyàn tó máa ń fẹ́ ran ẹlòmíràn lọ́wọ́ ni Bolaji jẹ́ kó tó jáde láyé.
Ó ní Bolaji máa ń ṣiṣẹ́ kárakára gidi, tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹbí rẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé àdánù ńlá ni ikú Bolaji jẹ́ fáwọn ẹbí rẹ̀ àti pé wọ́n ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú rẹ̀.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ Uber, nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde ní, ọkàn àwọn gbọgbẹ́ pàápàá fáwọn ẹbí Bolaji lórí àdánù ńlá wọn.
"A ti kàn sáwọn ọlọ́pàá láti ṣàfihàn àtìlẹyìn wa pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ láti fojú àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi náà hàn."
Bákan náà ni wọ́n sọ pé àwọn ti ṣí ètò ìkówójọ, GoFundMe láti fi ṣàtìlẹyìn fáwọn ẹbí Bolaji àti pé wọ́n máa lo owó náà láti fi ṣètò ìsìnkú rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ní àwọn máa fún ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ lára owó náà láti fi máa ṣètọ́jú ìgbé ayé pàápàá lásìkò yìí ti Bolaji ti jáde láyé.
Ẹ̀ka tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣekúpani ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Philadelphia ń ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀. Wọn ò tíì nawọ́ gán ẹnikẹ́ni lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Wọ́n ń bẹ ẹnikẹ́ni tó bá ní ìmọ̀ lórí bí wọ́n ṣe le nawọ́ gán àwọn olè náà láti fi tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá létí.
Bákan náà ni wọ́n kéde ẹ̀bùn $20,000 fún ẹnikẹ́ni tó bá le ran àwọn lọ́wọ́ láti fi porp òfin gbé àwón tó ṣiṣẹ́ ibi ọ̀hún.















