Ọwọ́ NDLEA tẹ àwọn tó ń fi ìwé ẹ̀sìn kó cocaine lọ sí Saudi Arabia

Iwe Stories of the Prophets

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọwọ ajọ to n gbogun ti egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, ti tẹ awọn kan ti wọn n ko egboogi oloro cocaine lọ si orilẹede Saudi Arabia.

NDLEA lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku.

Gẹgẹ bii ohun ti NDLEA sọ, inu awọn iwe ẹsin kan ni wọn ko awọn oogun oloro naa pamọ si lọna ati gbe lọ Saudi.

Agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi sọ pe cocaine naa ti iwọn rẹ jẹ 500g ni wọn fi pamọ sinu awọn iwe ẹsin ọhun.

O ni asiko ti awọn n ṣayẹwọ awọn ẹru to n lọ si Saudi Arabia lawọn ṣawari awọn oogun oloro naa ninu awọn iwe ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe NDLEA ko mẹnuba orukọ awọn to n ko oogun oloro naa lọ si Saudi ati ẹni to bẹ wọn lọwọ.

Oruko iwe naa ni "Stories of the Prophet" eyii ti Al Imam Ibn Kathir, kọ.

Yatọ si eyii, ọwọ NDLEA tun tẹ awọn to n gbe oogun oloro "loud" ati igbo ti iwọn rẹ jẹ 2.8KG wọ Naijiria elati orildeẹ Amẹrika.

NDLEA tun ni ọwọ awọn tẹ awọn mii to n gbe oogun oloro kaakiri Naijiria.

Lara aṣeyọri ajọ naa gẹgẹg bii atẹjade Babafemi ni awọn to n gbe oogun oloro ti wọn mu ni ipinlẹ Osun, Eko, Zaria, Bayelsa, Edo, ati bẹẹ bẹẹ lọ.