Fásitì UI kìlọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ́n obìnrin tí ìròyìn sọ pé, wọ́n n ta ẹyin ilé ọmọ wọn

Oríṣun àwòrán, Others
Ile-ẹkọ giga fasiti Ibadan ti gba awọn akẹkọọ obinrin ni ile-ẹkọ naa ni imọran lori sisọ tita ẹyin ile ọmọ wọn di okoowo lati fi pawo si apo wọn.
Ninu atẹjade kan ti awọn alaṣẹ fasiti UI sita, ẹka eto ilera ile-ẹkọ naa ṣekilọ pe bo ti lẹ jẹ pe fifun eeyan ni ẹyin ile ọmọ ti sọ ọpọ idile ti ko ni ọmọ di ọlọmọ, ko bujumu bi awọn kan ṣe sọ ọ di iṣẹ ti wọn n ṣe.
Aderonke Ajayi, oludari ẹka ilera Fasiti UI sọ pe, ọpọ awọn akẹkọọ wọn to jẹ obinrin ti sọ ara wọn di oniṣowo ẹyin ile ọmọ, ti ọpọ awọn ajọ tabi ileeṣẹ si n gba wọn siṣẹ lati ma ta ẹyin ile ọmọ.
"O ti de etiigbọ wa pe awọn akẹkọọ wa n ko pa ninu tita ẹyin ile ọmọ wọn pẹlu iṣẹ abẹ IVF fun owo.
"Botilẹ jẹ pe IVF ti mu idunnu ba ọpọ idile , ko yẹ ko yẹ iṣẹ oojọ ti awọn akẹkọọ yoo ma ṣe."
Aderonke ni igbesẹ yii lo le mu ọpọ aburu wa si ara obinrin bi, iṣalẹ inu dundun, ọyan dundun ati aisan kan ti wọn pe ni Ovarian Hyperstimulation Syndrome
"Tita ẹyin ile ọmọ le fa ki eeyan ma le bimọ mọ. Iwadii eto ilera ti ṣafihan awọn to le fun eeyan ni ẹyin ile ọmọ ati iye igba ti wọn le ṣe bẹẹ.
"Nipa ti aabo, obinrin ko gbọdọ fun eeyin ni ẹyin ile ọmọ ju igba mẹta lọdun lọ."
O wa gba awọn akẹkọọ ni imọran ki wọn ri pe wọn lo ojulowo ile iwosan lati fi ṣe eyi.
"O ṣe koko ki awọn akẹkọọ wa mọ aleebu to wa ninu tita ẹyin ile ọmọ wọn.
"A n gba awọn eeyan ni imọran pe ki wọn ma sọ eyi di iṣẹ olojọ nitori o ni ewu."
Ilẹ-ẹkọ naa wa rọ gbogbo araalu pe ki wọn pin iroyin nipa tita ẹyin ile ọmọ kiri gbogbo igberiko lati le da bobo awọn ọdọmọbinrin lọwọ awọn onijibiti to le fẹ fa wọn sinu okoowo naa.
Dokita Aderonke ni ọpọ nnkan to le ṣẹlẹ si obinrin lẹyin to ba fun obinrin ẹgbẹ rẹ ni ẹyin ile ọmọ
Aderonke ni o ṣeeṣe ki iru obinrin bẹẹ ko aarun mi, ki ẹjẹ ma da lati inu, ijamba si awọn ẹya ara inu ati bẹbẹ lọ















