Ọmọ Ghana mẹ́sàn án tí wọ́n fi iṣẹ́ tàn kúrò nílé, bá ara wọn nígbèkùn ní Mowe, nípìnlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, So-Safe Corps
Ni ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2025, ni ikọ fijilante ipinlẹ Ogun, So-Safe, ṣawari ile kan ti wọn de awọn ọmọ orilẹede Ghana kan mọ, lẹyin ti wọn fi ileri iṣẹ tan wọn wa si Mowe, ipinlẹ Ogun.
Atẹjade ti So-Safe fi ṣọwọ si BBC, ṣalaye pe, inu ile oniyaara mẹta kan to wa lagbegbe Oke Sioni, ni Mowe ni wọn ti awọn ọmọ Ghana naa mọ.
Alukoro ikọ naa, Moruf Yusuf, lorukọ ọga agba, Soji Ganzallo, fi kun un pe mẹsan-an ni awọn ọmọ Ghana ọhun, ṣugbọn mẹwaa ni apapọ eeyan tawọn ko nibẹ.
Ọkunrin mẹta ati obinrin meje.
Wọn ni wọn ko jẹ ki awọn to wa nigbekun naa ni anfaani lati ba ẹnikẹni sọrọ nita.
"Wọn ko le jade kuro ninu ile naa pẹlu, bẹẹ ni wọn ko tu wọn sile tabi ba wọn waṣẹ ti wọn fi tan wọn wa."
Awọn eeyan to wa nigbekun naa bi So-Safe ṣe sọ ni :
Anita Otaibu, Frank Adjei, Emmanuel Agyapong, Adam Zakari, Benjamin Etuah, Asamoah Kwaku, Yusuf Kasim, Ogunle Damola, (aṣọgba to n ṣọ ile naa, ọmọ Naijiria loun) Gift Dzakpasu ati Susana Ampons.
Báwo ni àṣírí ilé náà ṣe tú?

Oríṣun àwòrán, So-Safe Corps
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe ṣalaye, aṣiri ọrọ naa tu si ọwọ ikọ alaabo yii lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin ọdun 2025, nipa ile ikọkọ ọhun ati ohun ti wọn n ṣe nibẹ.
Nnkan bii aago mẹwaa owurọ ọjọ keji ti i ṣe ogunjọ, oṣu Kẹrin ni ikọ fijilante ati awọn ọlọpaa agbegbe Redeem, balẹ sibudo ọhun, wọn si tu awọn to wa nigbekun silẹ.
Bakan naa ni wọn fi ọwọ ofin mu awọn ti wọn gbagbọ pe wọn wa nidii iwa ẹtan ati itinimọle lọna aitọ naa.
Gbogbo awọn ti wọn ko ninu ile naa ni So-Safe ni awọn ti fa le agọ ọlọpaa Redeemed lọwọ, fun itẹsiwaju iwadii ati ipenilẹjọ nibi to yẹ.
Kí ni ọlọ́pàá wí?
Titi di akoko ti a fi ko iroyin yii jọ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa.
Gbogbo igbiyanju BBC lati ba agbẹnusọ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, Omolola Odutola, sọrọ lori ipo ti awọn ajeji naa wa, ni ko so eso rere.














