Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti rí afurasí tó pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, Killaboy, gbé padà sí Nàìjíríà láti Qatar tó sálọ

Augusta Oseodion Onuwabhagbe àti Benjamin Best Nnayereugo

Oríṣun àwòrán, @AUSTA_XXO @KILLABOIGRAM/INSTAGRAM

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ní àwọn ti parí gbogbo ètò láti dá Benjamin Best Nnayereugo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí "Killaboi" tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pẹ ó ṣekúpa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, tó sì na papa bora lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, padà sí Nàìjíríà.

Láti Doha ní orílẹ̀-èdè Qatar ni wọ́n ti dá Benjamin, tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó ṣekúpa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, Augusta Oseodion Onuwabhagbe, padà sí Nàìjíríà ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2025.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà, Olumuyiwa Adejobi fi léde sọ pé àjọṣepọ̀ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdájọ́ Nàìjíríà, àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ òkèèrè, (INTERPOL) , National Central Bureau àtàwọn aláṣẹ ètò ìdájọ́ ní Qatar lo ṣokùnfà bí wọ́n ṣe rí Benjamin dá padà sí Nàìjíríà.

Adejobi sọ pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ láti dá Benjamin padà sí Nàìjíríà látàrí báwọn ẹbí Augusta ṣe kọ̀wé ìfisùn sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lọ́jọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2024.

Ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Keje ọdún 2023 ni wọ́n fẹ̀sùn kan Benjamin pé ó ṣokùnfà ikú Augusta Oseodion Onuwabhagbe, ẹni ọdún mọ́kànlélógún, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga fásitì Lead City, Ibadan ní ilé rẹ̀ tó wà ní Ajah, ìpínlẹ̀ Eko.

Ìròyìn sọ pé, ìjà ló wáyé láàárín àwọn méjéèjì kí Benjamin tó gbẹ̀mí lọ́rùn rẹ̀.

Lẹ́yìn náà ni Benjamin sákúró ní Nàìjíríà kó tó ṣe fídíò kan láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun lòun pa ọmọbìnrin náà ní tòótọ́.

Nínú fídíò náà tó fi sórí ìkànnì ayélujára Instagram rẹ̀, Benjamin sọ pé òun kábàámọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé àti pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ ló ṣokùnfà èdè àìyede tó mú ẹ̀mí Augusta lọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ó wù mí pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò wáyé rárá. Mi ò gbèrò nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí rárá. Ìbẹ̀rù tó mú mi lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló jẹ́ kí ń sá lọ."

Nínú fídíò náà, Benjamin sọ pé òun ti ṣetán láti kojú ìgbẹ́jọ́ tí yóò tẹ̀yìn rẹ̀ yọ kódà bó jẹ́ ikú náà, ó ní kí wọ́n fìyà ẹ̀ṣẹ̀ òun jẹ́ òun.

Àmọ́ lẹ́yìn tó ṣe fídíò ọ̀hún lọ sá kúrò Nàìjíríà tó sì ń forí pamọ́ sáwọn orílẹ̀ èdè káàkiri.

Ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko kéde Benjamin gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá, tí INTERPOL sì ní kí wọ́n nawọ́ gan níbikíbi tí wọ́n bá ti ri.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní Freetown, olú-ìlú orílẹ̀ èdè Sierra Leone, kọ́kọ́ mú un ní ogúnjọ́ oṣù Kẹwàá àmọ́ tó sá kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n nígbà táwọn ẹlẹ́wọ̀n sa lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Freetown nínú oṣù Kọkànlá ọdún 2023.

Àwọn aláṣẹ sọ pé onírúurú ìwé ìrìnnà ayédèrú ni Benjamin ń lò láti fi rìnrìn àjò káàkiri àwọn orílẹ̀èdè pẹ̀lú orúkọ tí kò jọra wọn.

Ní oṣù Kìíní ọdún 2025 ni wọn padà kẹ́ẹ́fín rẹ̀ ní Doha, Qatar níbi tó ti lo orúkọ, Toure Abdoulaye tó sì parọ́ pé ọmọ orílẹ̀ èdè Guinea ni oun.

‎Agbẹnusọ ọlọ́pàá ṣàlàyé pé ní oṣù Kejì ọdún 2025 ni ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá Qatar tẹ Benjamin tí wọ́n sì ṣètò láti da padà sí Nàìjíríà láti kojú ẹ̀sùn rẹ̀.