'Mò n fi èdè Ìjẹ̀bú kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi ní ìṣirò nítorí mo fẹ́ kó yé wọn dáàdáà'
Laipẹ yii ni ajọ agbaye, UNESCO, kede Ọgbẹni Kayode Adewale, gẹgẹ bi ọkan lara awọn aadọta olukọ to perege julọ ni agbaye.
Adewale, olukọ ile-ẹkọ girama nipinlẹ ogun, wa lara aadọta olukọ to pegede bọ si ipele aṣekagba idije fun ami ẹyẹ GEMS Education Global Teacher Prize to waye niluu Dubai.
Eyi ni ko ṣẹyin bi Adewale ṣe n fi ede ibilẹ, paapaa ede Ijẹbu, kọ awọn akẹkọọ rẹ ni iṣiro nile ẹkọ girama to ti n ṣiṣẹ nipinlẹ Ogun.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, Ọgbẹni Adewale sọ pe, ipele kẹrin ni oun wa nile ẹkọ girama, nigba ti oun gba iṣipaya lati ṣiṣẹ olukọ.

O ni lati asiko naa ni oun si ti pinnu pe, awọn ilana to yatọ, ati ọgbọn atinuda, ni oun yoo fi maa ṣiṣẹ olukọ ti akoko ba to.
Awọn ipinnu rẹ yii lo ṣe okunfa bo ṣe bẹrẹ si ni fi ede Ijẹbu kọ awọn akẹkọọ rẹ ni imọ iṣiro.
"Lootọ ni gbogbo aye n lo ede Gẹẹsi lati maa fi kọ iwe, amọ igbagbọ mi ni pe ti a ba n fi ede abinibi ṣe alaye awọn ẹkọ fun wọn, paapaa ni ede ti wọn fi n ronu, oye iṣẹ naa yoo ye wọn daadaa."
O ni eyi yoo jẹ ko rọrun fun wọn lati kọ idahun to yẹ lasiko idanwo, bo tilẹ jẹ pe, ede Gẹẹsi ni wọn o fi kọ idanwo wọn.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ti to bi ọdun marun un, ti oun ti n fi ede abinibi kọ iṣẹ iṣiro.
Diẹ lara awọn akẹkọọ Ọgbẹni Adewale ni ile-ẹkọ girama Imagbon/Imaka Comprehensive high School, to ba BBC Yoruba sọrọ, sọ pe, bi olukọ naa ṣe n fi ede abinibi kọ awọn ni iṣiro, n mu ko ye awọn daadaa, ti awọn si nifẹ si i.
Bi ajọ UNESCO ṣe kede rẹ gẹgẹ bi ara awọn olukọ to dara julọ ni agbaye, tun ṣi awọn ọna miran fun un.
Lootọ ni Kayode Adewale ko bi anfaani lati jẹ ẹbun miliọnu kan Dọla nibi idije UNESCO, amọ ijọba ipinlẹ Ogun fun ni owo ati awọn nnkan mi i.
Ẹwẹ, kọmisanna fun eto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Abayomi Arigbabu, sọ pe Ọgbẹni Kayode Adewale, jẹ ọkan lara awọn olukọ ijọba ipinlẹ Ogun, to n ṣiṣẹ takuntakun.
O ni lati kekere ni awọn apẹẹrẹ ti tayọ ti n han lara arakunrin naa, nitori pe oun paapaa ni anfaani lati jẹ olukọ iṣiro fun un nigba to wa nile ẹkọ.
"Nnkan to n ṣe yi naa jẹ ara awọn nnkan ti ijọba n gbeero, lati mu ki eto ẹkọ ko ni itumọ si i nipinlẹ Ogun.



