Èyí ni ìdí tí mo ṣe fi iṣẹ́ Fada sílẹ̀ nínú ìjọ Àgùda, tí mo sì di oníṣẹ̀ṣe

Aworan Echezona Obiagbaosogu,
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alufaa ijọba Aguda tẹlẹ ri, Echezona Obiagbaosogu, ti ṣalaye idi to ṣe fi ẹsin Kristẹni silẹ, to si di oniṣẹṣe.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Igbo, Obiagbaosogu sọ pe ki i ṣe nitori ki oun le ni anfaani lati maa ba obinrin ni ibalopọ l'oun ṣe fi iṣẹ ojiṣẹ Ọlọrun, ti a mọ si Fada, silẹ, gẹgẹ bi ọpọ eeyan ṣe ro.

O ni oun pinnu lati fi iṣẹ Fada ti oun ti n ṣe fun ọdun mẹrindinlogun silẹ nitori iṣẹ alufaa ko wu oun mọ.

Obiagbaosogu ni, awọn nnkan to ni i ṣe pẹlu aṣa ni oun fẹ maa ṣe bayii, eyi lo si jẹ ki oun pa iṣẹ alufaa ti.

''Ọpọ lo ro wi pe ki n le ni anfaani lati maa ba obinrin lopọ lo jẹ ki n fi iṣẹ Fada silẹ, ọrọ ko ri bẹẹ rara.

Mo kan ṣa a ri pe iṣẹ alufaa ko wu mi lati maa ṣe mọ ni, lẹyin naa ni mo sọ fun awọn aṣiwaju mii pe mi o ṣe fada mọ ti mo si fi ijọ Aguda silẹ,'' Obiagbaosogu ṣalaye.

Obiagbaosogu to jẹ olukọni nile ẹkọ Mahadu Nnamdi Azikiwe ti wọn ti n kẹkọọ nipa aṣa ilẹ Afirika niluu Awka nipinlẹ Anambra, sọ pe nnkan to da lori aṣa lo wu oun lọkan bayii.

Lẹyin to darapọ mọ ile-ẹkọ naa lo kọ iwe kan to da lori bi eeyan ṣe le pe ojo lati rọ.

Obiagbaosogu tun fi idi rẹ mulẹ pe, oun ṣe igbeyawo lẹyin ti oun fi iṣẹ fada silẹ, Eledua si ti fi ọmọ jinki igbeyawo naa.

Ọgbẹni Obiagbaosogu ṣalaye pe, ilẹ Afirika ni aṣa ati iṣe to ṣe e mu yangan ṣugbọn awọn oyinbo akonilẹru lo jẹ ki ọpọ aṣa yii sọnu.

O fikun ọrọ rẹ pe iṣẹṣe gan an ni iṣẹ ti ori ran oun nitori nipasẹ rẹ ni oun fi le sin awọn eeyan oun.

O ni lati kekere ni irinajo oun si ẹsin abalaye ti bẹrẹ pẹlu bi oun ṣe ni anfaani lati gbe pọ pẹlu baba iya oun to jẹ babalawo.

Bakan naa ni Obiagbaosogu sọ pe baba oun gan an gbagbọ ninu iṣẹṣe bo tilẹ jẹ Kristẹni ni.

O ni gbogbo awọn nnkan wọnyii wa lara oun to jẹ ki oun pada sidi iṣẹṣe lati ibi iṣẹ alufaa.

Ọgbẹni Obiagbaosogu rọ awọn onigbagbọ wi pe, ki wọn ma ri awọn oniṣẹṣe gẹgẹ bi ẹni to n bọ Eṣu mọ.

O ni Ọlọrun kan naa ni gbogbo eeyan n sin, bo ya Musulumi ni ọ tabi Kristẹni.