Yeye Olokun of Lagos Omolara Fasola Fanimokun: Ọkọ mi kìí bọ òkun, "Elder" ni ní ṣọ́ọ̀ṣì àmọ́ ìdí nìyí tó fi bọ̀wọ̀ fún ìpè mi

Àkọlé fídíò, 'Pásítọ̀ ló sọ fún mi pé Ọlọ́run pè mí láti di Olokun tó ń bọ omi'

"Ipe mi ni Oloriṣa olokun, iṣẹ ti mo si yan laayo ni iṣẹ Amofin lorilẹede Naijiria".

"Lati kekere ni mo ti maa n ri ara mi ti mo maa n wẹ, ṣere ninu omi"

Yeye Olokun

Wolii ni Yeye Olokun tẹlẹ fun ogun ọdun ni ṣọọṣi. Ọmọ Eko ni baba rẹ amọ ọmọ ipinlẹ Edo ni iya rẹ.

Yeye Omolara Fashola to tun jẹ amofin nipa ọrọ oju omi ṣalaye bo ṣe yan lati di yeye Olokun leti okun eyi ti ọpọlọpọ maa n pe ni Yemoja nilẹ Yoruba.

Yeye Olokun

Ohun to yan laayo bayii dabii pe aṣa diran ni tori gẹgẹ bi Yeye ṣe sọ fun BBC Yoruba, ati ile baba ati ile iya rẹ ni wọn.

Yeye Olokun

Lasiko ọkan lara ijọsin rẹ leti okun, o ba BBC Yoruba sọrọ lorii bi o ṣe jẹ ọmọ Musulumi to tun lo ogun ọdun ni ṣọọṣi gẹgẹ bii Kristẹni ati Wolii ijọ kan ko to wa gba ibi to ni ori da a lọ eyi tii ṣe bibọ okun.

Bakan naa o ṣalaye awọn nkan to gbagbọ ninu rẹ nipa aṣa ati iṣẹṣe Yoruba fun idagbasoke orilẹede pẹlu igbelẹyin imọ ofin.

Yeye Olokun

Produced by Yemisi Oyedepo, Funmi Jokotade & Damilola Oduolowu