Afurasí tó ń ṣagolo-ṣàgò gún ọmọ-ọmọ olórin Asiko, Comfort Omoge pa l'Ondo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iwadii lori iku OgoOluwa Omoge to jẹ ṣe ọmọ-ọmọ gbajugbaja olorin, Comfort Omoge, to ti di oloogbe.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Olayinka Ayanlade, fidi rẹ mulẹ fun BBC Yoruba pe, ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni afurasi naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Mohammed to n ṣagolo kaakiri gun OgoOluwa lọbẹ niluu Okitipupa ti o si gba ibẹ ku.
''Lopopona Ayeka si Igbokoda ni ede-ai-yede ti bẹ silẹ laarin oloogbe OgoOluwa ati Mohammed to n ṣagolo.
Amọ, ko si ẹni to le sọ koko nnkan ti wọn n ja lw lori titi di asiko yii.
Lasiko ti wọn ni ede-ai-yede yii ni Mohammed gun OgoOluwa lọbẹ ti wọn si gbe e digba digba lọ si ile iwosan.
Awọn dokita du ẹmi rẹ, amọ, ẹpa ko boro mọ, nile iwosan ni OgoOluwa ti dakẹ,'' alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ondo lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Ayanlade ni, Mohammed ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii, nigba ti iwadii si n lọ lori iṣẹlẹ naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹka ajọ ọlọpaa to n ri si iwadii ọtẹlẹmuyẹ niluu Akure ti tẹwọ gba iṣẹ iwadii iku OgoOluwa.
Ayanlade ni Mohammed to wa ni atimọle ọlọpaa bayii yoo foju ba ile ẹjọ, idajọ ododo yoo si waye lori iṣẹlẹ naa.
Iṣẹlẹ iku OgoOluwa niluu Okitipupa si n ṣe awọn eeyan ilu naa ni kayeefi titi di asiko yii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Ondo ti wa rọ awọn araalu lati ma fọwọ pa ida ofin loju.
O ni ki wọn ke pe ọlọpaa ti aawọ ba ṣẹlẹ laarin wọn ati ẹlomiran, ki wọn si yago fun idajọ atọwọda.
Ẹwẹ, alaga ijọba ibilẹ Okitipupa, Andrew Ogunsakin, ti sọ pe oun ti ba awọn olori ẹya Fulani ati Hausa to fi mọ awọn ọba alade atawọn ọdọ sọrọ lati maa gbe pọ ni alaafia pẹlu ara wọn.
Ọgbẹni Ogunsakin tun lu ileeṣẹ ọlọpaa lọgọ ẹnu lori bi wọn ṣe tete mu afurasi to gun OgoOluwa lọbẹ pa.
O tun fi da awọn araalu ilu Okitipupa loju pe ijọba oun ko ni kaarẹ lori ipese abo to peye fawọn eeyan ilu naa.
Taa ni Comfort Omoge?
Gbajumọ akọrin ni Comfort Omoge nigba aye rẹ. Ọpọ lo gbagbọ pe oun ni Iyalode ati oludasilẹ orin Asiko, ẹka orin kikọ to ma n lo awọn aalọ ati itan Yoruba .
Orin Asiko gbajumọ pupọ laarin awọn eeyan Ikale, nipinlẹ Ondo.
Nigba aye rẹ, o jẹ olori fun ọba alaye ilu Igbodigo, ilu kan nilẹ Ikalẹ. Ọkọ rẹ si ṣe atilẹyin fun orin kikọ rẹ.
Ẹgbẹ akọrin rẹ ti wọn pe ni Aboba Asiko, ma n lo awọn irinṣẹ orin ati ilu ibilẹ fun orin wọn.
Lọdun 1976, o gbe awo orin rẹ akọkọ to pe akọle rẹ ni Orogen rogen, jade.
Lọdun 1980, labẹ ileeṣẹ orin Afrodisia/Decca Records, Comfort Omoge tun gbe awọn orin mii jade. Eyi lo pe akọle rẹ ni, Irore re yi ran.
Ọdun 1999 lo dagbere faye.















