'Gbèsè ni mo fi tọ́ àwọn ìbejì tó gba First Class, tayọ jù lọ ní UI'
Nigba ti ọkọ Arabinrin Felicia Busoye ku, to fi oun nikan silẹ pẹlu ọmọ mẹrin, o ro pe opin ti de ni.
Eyi lo ni ko ṣẹyin ironu lori bi oun yoo ṣe gbọ bukaata ọmọ mẹrin – meji lara wọn w ani ile-ẹkọ giga, meji yoo ku to jẹ ibeji ṣi w ani ile-ẹkọ girama.
Ṣugbọn laipẹ yii ni awọn ọmọde ọjọ naa to jẹ ibeji, Matthias ati Matthew kẹkọọ jade ni Fasiti Ibadan, ti awọn mejeeji si gba ami ẹyẹ gẹgẹ bi akẹkọọ to pagede julọ ni ẹka ti wọn ti n kọ nipa imọ ẹrọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti BBC ṣe pẹlu Arabinrin Busoye ati awọn ọmọ rẹ, lo ti jẹ ko di mimọ pe, owo yiya ni oun fi tọ awọn ọmọ naa dagba.
O ni, ọmọ ọdun mejila ni awọn ibeji naa wa nigba ti baba wọn ku, ti ẹnikan lara ẹbi oloogbe si gbiyanju lati gba awọn ọmọ naa lọwọ oun.

Oríṣun àwòrán, Matthias Busoye
Arabinrin Busoye ṣalaye pe oun kọ̀ lọjọ naa, nitori pe o san ki oun maa fi gaari bọ wọn, ju ki ẹlomiran gba awọn ọmọ to jẹ aṣọ lara oun lọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun fẹran lati maa yawo ju ki oun tọrọ owo lọ nitori awọn ọmọ oun.
"Lootọ owo yiya le fun eeyan ni ipaya, amọ o pe mi ju ki n maa tọrọ owo kiri."
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe, awọn banki da oun mọ daadaa nitori owo yiya.
"Lootọ lo nira pupọ lati da tọ awọn ọmọ naa, amọ mo dupẹ pe Ọlọrun sọ igbiyanju mi di ogo."
Nigba ti awọn ibeji naa w ani Fasiti ilu Ibadan, wọn tayọ laarin awọn ẹgbẹ wọn. Matthias jẹ olori ile aṣofin awọn akẹkọọ, ti ikeji rẹ, Matthew si jẹ aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ ni ẹka eto ẹkọ wọn.
Awọn ọmọ naa ṣalaye pe awọn fun ẹkọ awọn ni gbogbo nnkan to gba, ti awọn si tun ni ọrẹ ti wọn jọ ma n kawe papọ. Awọn nnkan yii lo jẹ ko rọrun fun wọn lati ṣe daadaa, ti awọn mejeeji si fi sẹ aṣeyọri pẹlu ami ẹyẹ kan naa
Nnkan iyalẹnu to wa nibẹ ni pe, maaki CGPA kan naa, 3.94/4.00, ni awọn ọmọ mejeeji mu jade ni Fasiti. Eyi tumọ si pe, First Class ni wọn gbe jade.



