'Ebi kọ́ ló mú kí àwọn ọmọ mi máa bá mi ṣiṣẹ́ fọga, kí ọjọ́ ọ̀la wọn le dára ni'
Ọmọ ti yoo ba jẹ aṣamu, Yoruba sọ pe lati kekere ni yoo ti maa ṣe ẹnu ṣamu-ṣamu.
Ki awọn ọmọ rẹ obinrin mejeeji, Khadijat ati Balkis a ma ba a ma rin irinkurin, lo mu ki Ọgbẹni Olatunji Ore, to n ṣiṣẹ fọga niluu Ilorin, ṣe n ko wọn lọ si ṣọọbu rẹ.
Amọ iyalẹnu lo jẹ fun un, nigba to deedee ri awọn ọmọdebinrin meji ọhun, to ti n pọ taya ọkọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC Yoruba, Ọgbẹni Olatunji sọ pe, nitori ki ọjọ ọla awọn ọmọ ọhun ma ba a bajẹ lo mu ki oun ni ki wọn o maa dari si ṣọọbu oun ti wọn ba kuro nile ẹkọ wọn.
Ile-ẹkọ girama ni awọn ọmọbinrin mejeeji ọhun wa, eyi ti ko fi bẹẹ jina si ibi ti baba wọn ti n ṣiṣẹ fọga.

Ọgbẹni Olatunji ṣalaye pe, oun ko mọ pe awọn ọmọ naa ti mọ iṣẹ ṣe titi di ọjọ kan ti oun de lati ode.
"Iyalẹnu lo jẹ nigba t imo de, t imo ba awọn mejeeji nibi ti wọn ti n tun taya ọkọ ṣe lai si iranlọwọ ẹnikẹni.
"Taya ọkọ bii meji mii ni wọn tun ṣe lẹyin rẹ loju mi,"
Baba wọn sọ pe kii ṣe nitori ebi ni wọn ṣe n ba oun ṣiṣẹ, amọ nitori ki ọjọ iwaju wọn o ma baa bajẹ ni.

Gẹgẹ bi nnkan ti baba ati awọn ọmọ rẹ sọ, iṣẹ fọga ti wọn n ṣe, ko ṣe idiwọ fun eto ẹkọ wọn rara.
Eyi to dagba ju ninu awọn ọmọbinrin mejeeji, Balkis, sọ pe iṣẹ oluṣiro owo lo wu oun lati ṣe, nigba ti eyi aburo fẹ ẹ ṣe iṣẹ dokita.
Ọgbẹni Olatunji sọ pe nnkan to wu oun ni pe ki awọn ọmọ mejeeji lọ ka iwe giga wọn niluu London, orilẹede United Kingdom.





