Àwọn agbébọn tún jí èrò inú ọkọ̀ méjì gbé lọ ní Kwara, ọlọ́pàá dóòlà méjì nínú wọn

Aworan awọn agbebon

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti fidi iṣẹlẹ ijinigbe kan to waye lọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2025, mulẹ.

Abule Eleyin, lagbegbe Isanlu-Isin, ipinlẹ Kwara ni wọn sọ pe awọn ajinigbe kan ti dabuu awọn ero ọkọ adani meji.

Nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ku iṣeju mẹẹdogun ọjọ naa ni awọn ọlọpaa ṣalaye pe ifisun de ọdọ awọn.

Wọn ni awọn agbebọn naa di oju ọna, wọn si fipa gbe gbogbo ero to wa ninu awọn ọkọ naa lọ.

A ti gba méjì kalẹ̀ nínú wọn- ọlọ́pàá Kwara

Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Kwara, SP Adetoun Ejire-Adeyemi, fi sita, ṣalaye pe ọlọpaa, awọn ṣọja ati fijilante sowọpọ, wọn si gba meji kalẹ ninu awọn to bọ sọwọ ajinigbe naa.

Ganiyu Ajayi ati Kolawole Adeyemi ni wọn pe orukọ awọn ti wọn gba kalẹ naa.

Atẹjade naa sọ pe iṣẹ ṣi n lọ lọwọ lati ri awọn to ṣẹku nigbekun gba kalẹ.

Bakan naa ni wọn ni ọwọ yoo ba awọn ajinigbe ọhun pẹlu.

Ileeṣẹ ọlọpaa Kwara fi kun un pe oun ti so okun aabo le si I lagbegbe naa, titi to fi mọ fifọ igbo lati ri awọn to wa nigbekun ati awọn to ji wọn gbe.

Ọlọpaa Kwara ni awọn fi da ara ilu loju, pe eto to nitumọ wa nilẹ lati da aabo bo wọn.

Wọn ni ki awọn eeyan Kwara ma ṣe ko aya soke, ki wọn wa lojufo, ki wọn si maa fi iṣẹlẹ ifura ti wọn ba ri to ọlọpaa leti.

Ẹ o ranti pe ọjọ Abamẹta to kọja ni awọn ajinigbe da awọn ero okọ kan naa lọna lopopona Obbo-Aiyegunle si Osi, nijọba ibilẹ Ekiti, ni ipinlẹ Kwara.

Ọkọ Sienna kan to ko ero lati ilu Abuja to n lọ si Offa ni awọn ajinigbe naa ṣe ikọlu si gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ.

Ọkan lara awọn olugbe ilu Obbo Aiyegunle to ba BBC News Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Layọde salaye pe awọn ajinigbe naa ko awọn agbalagba to wa ninu ọkọ naa lọ amọ ti wọn fi awọn ọmọde silẹ.

O ni awọn ọmọde to wa ninu ọkọ ọhun, amọ ti wọn ji awọn obi wọn gbe, lọ ọ sun lọdọ alaga ijọba ibilẹ Ekiti mọju ọjọ Aiku.