Bí o ṣe le lo Etí Erin (Aloe Vera) fún ìṣaralóge àti ìwòsàn àgọ́ ara

Aworan Aloe vera, ewe Eti Erin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Eweko ti Yoruba n pe ni Eti Erin, ti oyinbo n pe ni Aloe vera, gbajumọ pupọ kaakiri agbaye, nitori iwulo rẹ.

Bi wọn ṣe n lo o fun iṣaraloge lo tun wulo fun ilera.

Oje rẹ to maa n yọ̀, wulọ pupọ fun awọ ara, bẹẹ naa lo ṣe wulo fun oogun pipo ati fun awọn ileeṣẹ to n ṣe nnkan jijẹ.

Obinrin kan, Hélène Ahonssou, to ti bimọ mẹta, ṣalaye fun BBC pe, gbẹrẹbi gba gbogbo inu ati ẹsẹ oun tan lawọn igba ti oun loyun.

O ni iya oun agba to maa n ni Aloe vera nile lo gba oun kalẹ, pẹlu bi oun ṣe n lo oje eweko naa ti gbogbo ibi ti gbẹrẹbi wa tẹlẹ si ti waa n dan gbinnrin.

"Ti ẹ ba wo ikun mi bayii ati ẹsẹ mi, wọn jọlọ daadaa, pẹlu bi mo ṣe ti bimọ mẹta to. Iru nnkan bẹẹ ko si wọpọ laaarin awon obinrin asiko yii, inu wọn ti maa n hunjọ lẹyin ọmọ bibi".

Hélène, ẹni ọdun mọkandinlogoji lo sọ bẹẹ.

Kí ni Aloe vera?

Aworan Aloe vera ti wọn ti ge

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orukọ nla ni awọn onimọ sayẹnsi fun Aloe vera, oun naa ni barbadensis Miller.

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan gbagbọ pe orilẹede Egypt tabi Middle East lo ti wa, wọn ti n gbin in kaakiri aye bayii.

O maa n gun, yoo ni ewe to nipọn, ninu ewe naa ni oje to mọ lolo to si n yọ, wa. Eyi ni eroja pataki inu Aloe vera.

Dokita Mathieu Kponou Tobossi, onimọ nipa ounjẹ ati imọtoto, ṣalaye pe ninu ewe to gun ni iwọn 30-50 cm ni agbara rẹ wa.

Eweko yii tun ni oje alawọ pupa rẹsurẹsu kan to maa n jade lati ara ewe naa.

Bi eeyan ṣe le gbin in sita naa lo si le gbin Aloe vera sinu ile.

Èròjà inú Aloe vera

Oje Aloe vers

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nnkan meji pataki wa ninu Aloe vera. Awọn eroja meji naa ni wọn n lo fun iwosan.

Akọkọ ni eyi ti a mọ si latex, to wa nita ewe yii. Oun ni alawọ pupa rẹserẹsu. O maa n koro.

Ikeji ni ni eroja to wa ninu ewe nla Aloe vera, oje inu rẹ lo maa n mu awọ ara rọ̀ ti yoo si maa dan.

Gẹgẹ bi Dokita Mathieu Tobossi ṣe ṣalaye, o ni ọpọ eroja vitamin lo wa ninu ewe Aloe vera.

O ni awọn ti a mọ si mineral wa nibẹ pẹlu, ati amino acids, pẹlu awọn eyi ti a mọ si phenolics ati polysaccharides.

Aloe vera ni vitamin A, C ati E ninu, awọn nnkan wọnyi lo maa n ro ṣọja ara lagbara lati koju aisan.

Awọn eroja mii to tun wa nibẹ bo ṣe sọ ni :calcium, magnesium, zinc ati selenium.

Lysine, valine ati isoleucine ti wọn jẹ eroja amino acid naa ko gbẹyin.

Eweko kan to kun fun ọpọ nnkan aṣaraloore ni.

Ìwúlò Aloe vera fún àisàn

Aworan ọwọ to n fun oje Aloe vera

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iwosan ti ewe Aloe vera le kapa pọ, ṣugbọn marun-un kan wa to han julọ.

  • Pipa egbo patapata, didena kokoro ati mimu oju ọgbẹ dan pada.

Dokita Tobossi ṣalaye pe awọn eroja inu Aloe vera daa fun nnkan wọnyi.

O ni iṣẹ iwadii fi han pe Aloe vera maa n tete jinna oju ọgbẹ ina laaarin ọjọ mẹsan-an, to si jẹ pe ti oogun lilo maa n pẹ ju bẹẹ lọ.

"O ni eroja to n gbogun ti ara hihunjọ, o si maa n pese eroja collagen, to ma n mu ki awọ ara gbamuṣe, si i ninu ara. "

Dokita tẹsiwaju pe, Aloe vera tun ni eroja antifungal ati antibacterial ninu, eyi to le dena eṣiṣi ori, ti yoo mu ki ẹjẹ maa rin daadaa , ti irun yoo si maa pọ si i.

Bi irun ba n re tabi tu lori, Aloe vera le kapa rẹ.

  • O maa n ro ara lagbara

Eroja Acemannan to wa ninu Aloe vera n ṣiṣẹ fun kokoro ati ki ara maa wu. Awọn vitamin A, C, E, minerals ati polyphenols inu rẹ ko si kẹrẹ ninu awọn anfaani to ni.

  • O wulo fun egbo ẹnu

Awọn dokita fidi rẹ mulẹ, pe Aloe Vera n ṣiṣẹ fun itọju ọgbẹ ẹnu (mouth ulcer), eyi to maa n mu eeyan nisalẹ ete, inu ẹnu lọhun-un, to si le wa nibẹ fun ọjọ meje si mẹwaa.

  • O wulo fun ki ounjẹ tete da ninu

Ohun ti a mọ si Aloin tabi barbaloin, to wa ninu Aloe vera, wa fun ki eeyan le ṣegbonsẹ wọọrọwọ, wọn si maa n ni ki awọn ti ko ba ri igbọnsẹ ṣe, lo o.

Bakan naa ni yiyọ to maa n yọ yii n gbọ iṣoro inu bi inu rirun, bi dokita ṣe sọ.

  • Aloe vera maa n ṣakoso ṣuga ati ọra ara

Nigba mii, wọn maa n lo Aloe vera fun itọju aisan itọ ṣuga nilana ibilẹ.

Dokita Tobossi lo sọ eyi.

O ni eweko yii maa n tun Insulin to n ri si ṣuga ninu ara ṣe.

Dokita Tobossi ṣalaye pe, ọpọ eeyan ni wọn ti lo Aloe vera fun itọju aisan itọ ṣuga, ti alaafia si de si wọn.

Bakan naa lo ni Aloe vera daa fun itọju LDL cholesterol, iyẹn ọra buruku to maa n ba ara ja.

Ewu tó wà nínú lílo Aloe vera

Aworan Dokita Mathieu Kponou Tobossi

Oríṣun àwòrán, Dr. Mathieu Kponou Tobossi

Àkọlé àwòrán, Aworan Dokita Mathieu Kponou Tobossi

Bo ṣe jẹ pe ko sohun to dara ti ko ni abawọn, bẹẹ naa ni Aloe vera naa ni tiẹ.

Dokita Mathieu Tobossi, ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe anfaani Aloe vera pọ, sibẹ, o ni awọn ewu kan to rọ mọ lilo rẹ

Latex (Aloin): Ohun ti a pe ni Aloin yii ni oró.

O le fa ki isalẹ ikun maa dun eeyan, o le fa ki eeyan maa yagbẹ gbuuru, o si le fa ki oyun walẹ lara alaboyun.

O le ṣakoba fun ẹdọ: Dokita Tobossi sọ pe awọn ti ri awọn eeyan ti wọn lugbadi aisan ẹdọ, nitori wọn lo Aloe vera ju bo ṣe yẹ lọ.

O le ṣakoba fun awọ ara awọn eeyan miran

Bi Aloe vera ṣe daa fun awọ ara naa lo lewu fu awọn ẹlomiran.

Awọ ara ẹlomiran yoo pọn bii ẹjẹ to ba fi Aloe vera para, bẹẹ ni ara yoo maa yun awọn ẹlomiran.

Ewu jẹjẹrẹ: Bi eeyan ba ti n lo eweko yii ju fun igba to pẹ, wọn ni o ṣee ṣe ko wa ninu ewu a ti ni aisan jẹjẹrẹ.

'Group 2B, ẹka International Agency for Research on Cancer,' lo sọ eyi di mimọ.

Gẹgẹ bi iwọ naa ṣe ri i, Aloe vera ti fi han pe oun ni ọpọ iwosan ninu.

Ṣugbọn lilo rẹ gba ọgbọn pupọ, gẹgẹ bi Dokita Mathieu Kponou Tobossi ṣe sọ.

O lo ṣe pataki lati :

  • Lo oje ti ko ni eroja aloin ninu fun iwosan inu ati tode
  • Yago fun ohun to ni latex, kan si dokita to ba pẹ to o ti n lo o
  • Ṣọra fun lilo rẹ bi o ba loyun, ti o ba jẹ ọmọde, ti o ba ni iṣoro kidinrin tabi ti ẹdọ.

Akiyesi:

Ayọka yii ki i ṣe idi kan fun ọ lati maa lo Aloe vera fun itọju dipo ti wa a fi lọ sile iwosan, kan si dokita rẹ ki o to lo o.