Mi ò kábàmọ́ọ̀ pé ìyàwó mi tó kú nigbà tó fẹ́ bímọ kò forúkọ sílẹ̀ nílé ìwòsàn - Folajimi

Oríṣun àwòrán, Others
Ọgbẹni Akinbobola Folajimi ti iyawo rẹ, Oluwakemi, ku laipẹ yii niluu Eko nigba to n rọbi lọwọ ti sọ pe oun o kabamo wi pe iyawo oun ko forukọ silẹ nile iwosan kankan ṣaaju ki ọjọ ibimọ rẹ to pe.
Ọgbẹni Folajimi sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Pidgin pe kii ṣe ile iwosan loun bi awọn ọmọ oun meji to bi ṣaaju si.
Folajimi tun sọ pe ki i ṣe ile iwosan lawọn obi oun naa bi oun gan an si, idi niyii toun ko fi kabamọọ pe Oluwakemi ko forukọ silẹ nile iwosan lasiko to wa ipo iloyun.
Ọkọ oloogbe naa ni oun n ṣafẹri iyawo oun ni gbogbo igba, o ni oun ko gbọ ki foonu rẹ maa dun mọ bo ṣe maa n dun tẹlẹ.
''Kii ṣe nnkan to rọrun rara, ni ṣe ni iku iyawo mi si n da bi ala fun mi.
Mi o tiẹ lero wi pe iyawo mi le ku lasiko to ku tori pe ko si nkankan to ṣe e ṣaaju akoko ti mo gbe e lọ si ile iwosan lati bimọ.
A ti jọ n gbero lati ṣe ayẹyẹ ọdun kẹwaa igbeyawo wa lọdun yii ki o to ṣalai si,'' Folajimi ṣalaye.
Naijiria wa lara awọn orilẹede tawọn alaboyun ti maa n ku julọ lagbaaye.
Ẹwẹ, dokita kan tọ jẹ onimọ nipa eto ilera awọn obinrin, Akinde Joseph, woye pe Folajimi ko ṣeto fun nọọsi kan tabi dokita lati maa ṣayẹwo fun iyawo rẹ lasiko to wa ni ipo iloyun.
Dokita Joseph ni igba ti ọwọ ti bọ sori tan ni Folajimi ṣẹṣẹ gbe iyawo rẹ lọ sile iwosan, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.
Ohun to ṣẹlẹ sẹyin
Oluwakemi ku ni nkan bi oṣu meji sẹyin niluu Eko lasiko to n rọbi lọwọ.
Folajimi ati iyawo rẹ Oluwakemi ko forukọ silẹ nile iwosan kankan, ọdọ iya agbẹbi abẹ ile kan to wa lagbegbe wọn ni Oluwakemi n lọ lasiko to wa ninu oyun.
Ọgbẹni Folajimi ni idi tawọn o fi lo ile iwosan ni pe o jinna sibi tawọn n gbe, ati pe awọn ti bi ọmọ meji sile agbẹbi tẹlẹ.
Agbẹbi abẹ ile yii naa lo fẹ gbẹbi fun Oluwakemi nigba ti o n rọbi ko to di pe apa rẹ ko ka a mọ.
Nkan ibanujẹ to ṣẹlẹ ni pe Oluwakemi ku pẹlu ọmọ to wa ninu rẹ, eyi si lo mu ki ọpọ eeyan maa sọ nipa iṣẹlẹ ọhun lori ayelujara.
Lẹyin ti ọrọ naa mi ori ayelujara titi ni ijọba ipinlẹ Eko paṣẹ pe ki iwadii kikun waye lori ohun to ṣokunfa iku obinrin pẹlu oyun inu rẹ.















