Akọrin tàkasúfèé, Terry Apala, di èèrò ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn pé ó tàbùkù owó náírà

Aworan Terry Apala

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Eko ti paṣẹ wi pe, ki wọn ju olorin takasufee Terry Alexander Ejeh ti ọpọ mọ sí Terry Apala si atimọle lọgba ẹwọn Ikoyi lori ẹsun pe o tabuku owo naira.

Onidajọ Akintayo Aluko paṣẹ pe ki olorin naa wa ni ahamọ titi di ọjọ karun un, oṣu Karun un ti igbẹjọ lori ati gba beeli rẹ yoo waye.

Ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria lo gbe Terry Apala lọ sile ẹjọ lori ẹsun kan to da lori ṣiṣe owo naira ni iṣekuṣe.

EFCC sọ fun ile-ẹjọ pe, olorin naa n tẹ owo naira mọlẹ nigba to n jo nibi ayẹyẹ kan to waye ni Madison Place, Oniru, niluu Eko.

Agbẹjọro EFCC, Sulaimon Sulaiman, rọ ile ẹjọ lati ka ẹsun naa si i leti.

Lẹyin naa ni Terry Apala sọ fun ile-ẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Agbẹjọro EFCC wa sọ fun ile-ẹjọ lati kede igba ti igbẹjọ yoo bẹrẹ.

Bakan naa ni Ọgbẹni Suleiman tun rọ ile-ẹjọ lati ju olujẹjọ si ahamọ lọgba ẹwọn.

Agbẹjọro fun olujẹjọ, Felix Nwakbudu, sọ fun ile-ẹjọ pe, oun ṣetan lati duro gẹgẹ bi agbẹjọro fun Terry Apala fun igbẹjọ beeli rẹ.

Nwakbudu ni oun ti fi ẹda iwe ibeere fun beeli onibaara oun sọwọ si igbimọ olupẹjọ.

O wa rọ ile-ẹjọ lati bẹrẹ igbẹjọ beeli naa.

Amọ, igbimọ olupẹjọ tako abaa lati bẹrẹ igbẹjọ beeli ọhun.

Agbẹjọro EFCC ni oun nilo lati kọkọ ka nnkan to wa ninu ipẹjọ beeli naa koun le mọ nnkan toun maa fesi.

Ninu idajọ rẹ, Onidajo Aluko paṣẹ pe ki wọn ju olujẹjọ si ahamọ lọgba ẹwọn ni Ikoyi titi ti igbẹjọ beeli rẹ yoo fi waye.

Adajọ tun paṣẹ pe igbẹjọ naa gbọdọ waye ni kiakia, ki o to sun igbẹjọ si ọjọ karun un oṣu, Karun un to n bọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post