Kí ni ọ̀nà àbáyọ bí ilé ìfowópamọ́ àgbáyé ṣe ní ìṣẹ́ àti òṣì máa pọ̀ si ní Nàìjíríà lọ́dún 2027?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilé ìfowópamọ́ àgbáyé, World Bank ti ní ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló tún máa wà nínú ìṣẹ́ àti òṣì nígbà tó bá fi máa di ọdún 2027.
Ìjábọ̀ ilé ìfowópamọ́ náà lórí ọjọ́ iwájú àwọn ilẹ̀ Africa sọ pé ìṣẹ́ àti òṣì tó wà ní Nàìjíríà máa lékún pẹ̀lú ìdá mẹ́ta (3.6%) tó bá fi máa di ọdún 2027.
Wọ́n ní èyí máa rí bẹ́ẹ̀ látàrí bí Nàìjíríà ṣe gbáralé epo rọ̀bì gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan gbòógì tó fi ń pawó wọlé, àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé àti ìpèníjà ètò ìṣèjọba tó dúró ire.
Ìjábọ̀ náà ní àwọn orílẹ̀ èdè tí wọn kò gbáralé epo rọ̀bì, tó jẹ́ pé nǹkan ọ̀gbìn ni wọ́n fi ń ṣagbára ṣeéṣe kí ètò ọrọ̀ ajé wọn rú gọ́gọ́ sí lọ́dún 2027.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbéga bá ẹ̀ka tí kìí ṣe tie po rọ̀bì ní Nàìjíríà bíi ètò ọ̀gbìn ní ìparí ọdún 2024, ilé ìfowópamọ́ náà ní kò tó láti gba Nàìjíríà lọ́wọ́ ìṣẹ́.
World Bank ní tí Nàìjíríà bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ́, ó gbọdọ̀ mú àlékún bá ètò tí yóò ti ọrọ̀ ajé rẹ̀ sókè bíi mínú àlékún bá ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn rẹ̀.
Báwo ni Nàìjíríà ṣe le mú àgbéga bá ẹ̀ka ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀?
Ọ̀jọ̀gbọ́n Jameelah Omolara Yaqub, onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Lagos State University, LASU wòye pé pẹ̀lú bí Ọlọ́run ṣe fi ilẹ̀ jíǹkí Nàìjíríà, ètò ọ̀gbìn jẹ́ ohun tó yẹ kí gbogbo èèyàn máa ṣe.
Ó ní Nàìjíríà ní ipa láti máa pèsè oúnjẹ tí yóò tó wa jẹ, tí a ó tùn máa pèsè fáwọn orílẹ̀ èdè mìíràn láti máa fi ṣe ọrọ̀ ajé.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Yaqub ní ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló máa ń fojú iṣẹ́ ìdọ̀tí wo iṣẹ́ àgbẹ̀, pé òun ló ń ṣokùnfà ìfàsẹ́yìn tó ń bá Nàìjíríà fínra lásìkò yìí.
Ó sọ pé ìjọba nílò láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn ọmọ Nàìjíríà pàápàá àwọn ọ̀dọ́ lórí àwọn ànfàní tó wà nínú iṣẹ́ àgbẹ̀ àtàwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe láti rí èrè tó pọ̀ jẹ níbẹ̀.
Ó fi kun pé ìjọba nílò láti ní àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ àti agbègbè tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lójùnà àti pèsè ìrànlọ́wọ́ tó péye fún wọn.
Ó ní ṣíṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ lode òní láti pèsè oúnjẹ tó máa tó, tó sì tún máa ṣẹ́kù nílò lílo àwọn irinṣẹ́ ìgbàlódé fún ètò ọ̀gbìn, bó ṣe ní ìjọba gbọdọ̀ pèsè èyí láti fi ran àwón àgbọ̀ lọ́wọ́ àti láti fi ṣe kóríyá fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n náà sọ pé ọ̀nà láti mójútó àwọn èrè oko jẹ́ ìpèníjà táwọn àgbè tún máa ń kojú lẹ́yìn tí wọ́n bá kó èrè àwọn nǹkan tí wọ́n gbìn tán.
Ó wòye pé ọ̀pọ̀ èrè oko ló máa ń bàjẹ́ káwọn àgbẹ̀ tó gbe dé ọjà àti pé ọ̀pọ̀ wọn ni kìí mọ ọ̀nà láti fi tọ́jú èrè oko wọn tó bá pọ̀ tí yóò sì bàjẹ́ kí ìgbà tí wọ́n fi máa kó èrè oko mìíràn.
"Ìjọba nílò láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn àgbẹ̀ lórí ọ̀nà tí wọ́n fi le máa pa èrè oko wọn mọ́, tí kò ní bàjẹ́, tí wọ́n sì máa ma ri tà lẹ́yìn tí àsìkò nǹkan ọ̀gbìn náà bá lọ tán.
Ìjọba nílò láti tún ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn èèyàn tí kìí ṣe àgbẹ̀ gan láti máa gbin ohun kékeré sí ilé wọn láti mú àdínkù bá bí oúnjẹ ṣe wọ́n gógó ní agbègbè wa.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Yaqub ní àwọn ètò ọ̀gbìn bíi kòkó tí Nàìjíríà fi ń ṣe ọrọ̀ ajé tẹ́lẹ̀ ló ṣì ń tà káàkiri àgbáyé, tí Nàìjíríà náà sì nílò padà mú ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn rú gọ́gọ́ si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Bí ọkàn aráàlú bá balẹ̀, ó máa rọrùn láti ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ dáadáa"
Nígbà tó sọ̀rọ̀ lórí ètò ààbò tó ń ṣokùnfà ìfàsẹ́yìn fún ọ̀pọ̀ àgbẹ̀ ní Nàìjíríà, ó ní ó ti yẹ kí ẹ̀rọ ayàwòrán CCTV ti pọ̀ káàkiri Nàìjíríà, tí yóò máa mójútó lílọ bíbọ̀ àwọn èèyàn káàkiri agbègbè.
Ó ní báwọn agbébọn ṣe lọ ń dá àwọn àgbẹ̀ lọ́nà nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ lóko ti yẹ kó di ohun ìgbàgbé nítorí ó ti yẹ káwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti wà láwọn ìgbèríkò tí iṣẹ́ àgbẹ̀ ti máa ń wáyé jù lójúnà àti dá ààbò bo àwọn àgbẹ̀ yìí.
"Tí àwọn ẹ̀rọ ayàwòrán bá wà káàkiri, àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò yóò tètè mọ̀, wọ́n á sì lè tọpinpin àwọn àjòjì ba wọ ìlú kan.
"Ìjọba níl]o láti mú ọ̀rọ̀ ààbò àwọn àgbẹ̀ ní nǹkan tó ṣe pàtàkì, kí wọ́n ní òkúnkúndùn nítorí ọ̀pọ̀ àgbẹ̀ ni wọ́n ti pa sóko, tó sì ń kó ìrẹ̀wẹ̀sí ọkàn bá àwọn mìíràn.
"Bí ọkàn aráàlú bá balẹ̀, ó máa rọrùn láti ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ dáadáa"
Bákan náà ló ní ìjọba nílò láti pèsè àwọn irinṣẹ́ àti ohun èèlò tó péye fáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò, kí wọ́n sì máa ṣe kóríyá fún wọn lóòrè kóòrè, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
Onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé náà ní gbogbo èèyàn ni ṣíṣe ìgbéga ètò ọ̀gbìn ní Nàìjíríà yẹ kó jẹ lógún nítorí bí ebi bá ti kúrò nínú ìṣẹ́, ìṣẹ́ yóò bùṣe.















