Wo ojú, orúkọ àti àwòrán àwọn afurasí ọmọ Naijiria tó ṣe agbódegbà fún CBEX

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCc, ti gbe aworan ati orukọ eeyan mẹjọ, ti wọn lo ṣe agbatẹru eto idokowo ori ayelujara, Cbex, to foriṣanpọn laipẹ yii.
Ninu ikede kan ti EFCC fi si oju opo ayelujara X rẹ lọjọ Ẹti, lo ti kede pe oun n wa awọn eeyan naa fun ipa ti wọn ko ninu bi ileeṣẹ Cbex ṣe raaye fidi mulẹ, to si gba obitibiti owo lọwọ awọn to ba wọn dowo pọ.
Ọsẹ meji sẹyin ni oju opo ayelujara Cbex da iṣẹ silẹ, ti awọn onibaara ko si ri owo wọn gba jade.
Kete ti ileeṣẹ CBEX ko owo awọn eeyan ni awọn ọdọ kan yawọ ọfisi wọn niluu Ibadan, ti wọn si bẹrẹ si ni ko gbogbo ẹru wọn lọ.
Fọnran kan to lu sita lori ayelujara safihan bi awọn ọdọ kan ṣe binu yawọ ọfisi naa to wa niluu Ibadan, ti wọn si n da gbogbo nnkan ru, koda wọn ji ọpọlọpọ awọn nnkan ini wọn lọ.
Saaju asiko yii ni awọn to da CBEX silẹ ti n sọ fun awọn oludokoowo wọn pe awọn fẹ mu adinku ba oṣi ati iṣẹ nilẹ adulawọ ni iwọn ida ọgbọn, 30%.
Ileri mii tun ni wi pe ẹni to ba ko ọpọlọpọ ero wa, to si gba oye VIP 9, yoo ni anfani lati rin irinajo lọ si orilẹede ti o ba wuu, yoo si tun mu mọlẹbi rẹ meji dani.
EFCC sọ pe owo to to Trilliọnu kan ati biliọnu lọna ọọdunrun Naira, ni awọn ọmọ Naijiria padanu sinu eto idokowo ori ayelujara CBEX.
Awọn wo ni EFCC n wa?
Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2025, ni iroyin kọkọ sọ pe, ile-ẹjọ giga to wa ni ilu Abuja, ti kọkọ fun EFCC ni aṣẹ lati fi ofin mu, ko si ti eeyan mẹfa kan mọle fun bi wọn ṣe ṣe agbetẹru eto sogun-dogoji.
Amọ nigba ti yoo di ọjọ Ẹti, aworan eeyan mẹjọ ni ajọ naa fi si ori ayelujara rẹ, gẹgẹ bi awọn ti wọn n wa lati ṣe iwadii wọn.
Awọn onitọhun lo jẹ ọmọ orilẹede Naijiria ni EFCC pe ni afurasi to ṣe iranwọ fun bi awọn ọmọ ilẹ okeere to da ileeṣẹ ọhun silẹ, ṣe raaye wọle si araalu lara.
Awọn eeyan naa ni:
- Adefowora Abiodun Olaonipekun
- Adefowora Oluwanisola
- Emmanuel Uko
- Seyi Oloyede
- Johnson Okiroh Otieno
- Israel Nbaluka
- Joseph Michiro
- Serah Michiro
Gẹgẹ bi ikede ti agbẹnusọJimoh Odutola, Ogunpa, niluu Ibadan, ni Adefowora Abiodun Olaonipekun ati Adefowora Oluwanisola, n wa ṣaaju gbogbo rogbodiyan yii.
Ni ti Emmanuel Uko ati Seyi Oloyede, Idimu Egbeda nipinlẹ Eko, ni adirẹsi ti wọn ti ri wọn gbẹyin.
Amọ wọn ko fi adirẹsi awọn eeyan mẹrin yooku sita.
Ajọ naa wa rọ gbogbo ẹni to ba mọ ibi ti awọn afurasi naa wa, lati fi to o leti.

Oríṣun àwòrán, EFCC/X

Oríṣun àwòrán, EFCC/X
Ilé ẹjọ́ fún EFCC lágbára láti mú èèyàn mẹ́fà tó ṣe ìgbélárugẹ CBEX

Oríṣun àwòrán, Other
Ile-ẹjọ giga to n jokoo niluu Abuja ti fun ajọ to n gbe ogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ni aṣẹ lati fi ofin mu, ki wọn si tun ti eeyan mẹfa ti wọn jẹ agbatẹru ileeṣẹ sogun-ogoji, CBEX, to lu awọn eeyan ni jibiti biliọnu kan owo dọla laipẹ yii.
Adajọ Emeka Nwite lo gbe idajọ yii kalẹ ni Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 lẹyin ti ajọ EFCC gbe ẹjọ naa wa si ile-ẹjọ.
Ohun ti EFCC beere fun ni pe ki ile-ẹjọ fun awọn ni aaye lati mu awọn afurasi naa, ki wọn si wa ni ahamọ titi iwadii yoo fi pari .
Agbẹjọro EFCC, Fadila Yusuf, sọ pe, ninu oṣu Kẹrin ni iroyin nipa CBEX tẹ ajọ EFCC lọwọ, ti iwadii si fihan pe awọn afurasi naa lọwọ ninu bi CBEX ṣe lu awọn eeyan ni jibiti.
Awọn afurasi ọhun ni EFCC sọ pe o lo ileeṣẹ ST Technologies International Limited, lati ṣe igbelarugẹ CBEX, ti wọn si n pe awọn araalu pe ki wọn wa ko owo si pẹlu ileri pe owo naa yoo di ilọpo.
"Awọn afurasi yii ti fẹsẹfẹ, ti a si nilo iwe ofin lati mu wọn fun iwadii to yanranti," Yusuf sọ fun ile ẹjọ.
Adajọ Nwite ninu idajọ rẹ sọ pe oun buwọlu u gẹgẹ bii wọn ṣe beere fun.
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju pẹlu CBEX?
Ninu oṣu kẹrin ni ọpọ eeyan pariwo sita nipa okoowo sogun di ogoji kan ti wọn se lori ayelujara CBEX.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo fi ika hanu lasiko yii lori ayelujara nitori wọn ko ọpọlọpọ owo sinu ileeṣẹ yii.
Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ ni ọsẹ to kọja, nigba ti oju opo ayelujara ileeṣẹ naa dẹnu kọlẹ, ti wọn si ko owo gbogbo awọn onibara wọn lọ.
Bi owo naa se n sọ ogun di ogoji ni ko ye ọpọlọpọ eeyan sugbọn ọrọ nipa CBEX bayii ti n gba omije loju ọpọ eeyan.
BBC Yoruba ba eeyan mẹta ọtọọtọ sọrọ, lẹyin ti owo wọn di awati, wọn si sọ ohun ti oju wọn ri lori ọrọ naa.
Ẹni akọkọ to ba wa sọrọ, Arakunrin Musiliu (kii ṣe orukọ rẹ gangan) ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe, ọkan lara awọn ọrẹ oun lo fi CBEX lọ oun, ni nnkan bii oṣu mẹrin sẹyin.
O ni ẹẹdẹgbẹta Dollar, $500 ni oun si fi bẹrẹ okoowo naa nitori wọn ṣe ileri fun oun pe owo naa yoo di ẹgbẹrun mọkanla Dollar, $11,00 laarin oṣu mẹfa.
Musiliu ni, "Ọrẹ mi to ṣi CBEX fun mi ti n gba ọpọlọpọ owo jade nibẹ lati ọdun kan sẹyin.
O ti gba oju owo ati ọpọlọpọ ere nibẹ.
Eyii lo mu ki emi naa lọ wa owo ya lati le jẹ ere gẹgẹ bii ọrẹ mi."
Owo Arakunrin yii ti le ni ẹgbẹrun meji Dollar, $2,000 ko to di pe ọrọ bẹyin yọ.















