Ojúlówó ọmọ ijọ Celestial ni mí, kódà, mo kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì CCC kan fúnra mi - K1 De Ultimate

Oríṣun àwòrán, K1 De Ultimate/Instagram
Ọrọ ti agbaọjẹ olorin Fuji n ni, Alhaji Wasiu Ayinde K1 De Ultimate, sọ pe ojulowo ọmọ ijọ ''Celestial'' loun ti di nnkan ti ọpọ eeyan gbe kiri lori ayelujara.
Ni Ọjọru ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹrin ti a wa yii ni K1 fidi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlifisan Agbaletu.
Ọpọ lo gbagbọ wi pe ẹlẹsin musulumi pọnbele ni K1 pẹlu bi o ti n jẹ orukọ musulumi ti o si tun ti lọ si Mecca lai mọ iye igba fun iṣẹ Hajj.
Eyi gan an lo jẹ ko jẹ iyalẹnu fun ọpọ eeyan nigba K1 tu kẹkẹ ọrọ silẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe naa wi pe ọmọ ijọ CCC loun, ati pe oun gan an gẹgẹ bi ẹnikan kọ odidi ṣọọṣi Sẹlẹ kan.
Ninu fidio ọhun to wa lori Instagram ni K1 ti sọ pe jijẹ ọmọ ijọ CCC jẹ nnkan imuyangan ati nnkan imoriya foun.
''Mo wa ẹsin, mo wa Ọlọrun gan an ni ilana musulumi ati ilana Kristẹni.
Ko si ibi ti n ko wa Ọlọrun de,'' K1 lo sọ bẹẹ.
Ọro yii jade lẹyin iṣẹlẹ kan to waye loṣu Kinni ọdun yii laarin gbajugbaja olorin Fuji naa atawọn aafa kan nibi eto isinku mama rẹ niluu Ijebu Ode.
K1 De Ultimate n ba ẹnikan sọrọ lọwọ lori foonu nigba ti o ṣadeedee da aṣa kan pe ''wọn wa ganusi sibi'' eyi to ni ṣe pẹlu awọn afaa kan ti wọn wa sibi oku iya rẹ.
Bayii ni awọn eeyan bẹrẹ si ni da aṣa ''Ganusi'' lori ayelujara, koda, ọpọ ninu awọn olorin lo fi ''Ganusi'' kọrin.
Ọpọ eeyan lo tumọ aṣa ''Ganusi'' wi pe awọn afaa to fẹ tọrọ owo ni Alhaji Wasiu Ayinde n ba a wi.
Bayii ni ọpọ awọn afaa bẹrẹ si ni ṣe waasi tako Wasiu lori ọrọ to sọ sawọn afaa naa.
Koda, awọn ọmọ Naijiria mii naa ti wọn kii ṣe afaa naa fara ya wi pe ọrọ ti K1 sọ sawọn afaa ọhun kudiẹ kaato.
Amọ, ilumọọka olorin Fuji naa ya ọpọ eeyan lẹnu nigba to sọ pe ọrọ toun sọ ko ju ẹnu oun lọ.
K1 tun sọ fawọn to ni ko tọrọ aforijin pe oun ko ni tọrọ aforijin tori oun ko ṣẹ ẹnikankan.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post















