Iléeṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ọ̀tun lóri ẹgbẹ́ agbébọn Mahmuda tó n ṣoro ní Kwara

Lt General Olufemi Oluyede

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọga agba fun ileeṣẹ Ologun lorilẹede Naijiria, Lt General Olufemi Oluyede, ti palaṣẹ fun awọn Ologun pe ki wọn le awọn agbebọn kuro ni ijọba ibilẹ Kaiama ati Baruten nipinlẹ Kwara ati awọn ipinlẹ ti awọn agbebọn naa ti n ṣọṣẹ.

Oluyede ni ileeṣẹ Ologun ni ohun to yẹ lati le awọn agbebọn naa kuro laarin oṣu kan ati pe orilẹede Naijiria ko le fi aaye silẹ fun ẹgbẹ agbebọn lati ma tan kaakiri.

O sọ eyi lasiko to n ba awọn Ologun sọrọ nigba to ṣe abẹwo si baraaki Ologun to wa ni Sobi niluu Ilorin, to jẹ olu-ilu ipinlẹ Kwara.

Abẹwo ọga Ologun si baraaki ologun lo da lori fifun awọn ọmọ Ologun ni iwuri bi wọn ṣe ti fẹ morile agbegbe ti ikọlu awọn agbebọn ti n waye lati le ẹgbẹ agbebọn, Mahmouda jade kuro ni buba wọn.

"A ko le faaye gba Boko Haram mi nibi kibi lorilẹede Naijiria.

"Ni bayii, ti ẹ ti wa ni ita, mo mọ pe ẹ o sa gbogbo agbara yin lati ri pe awọn agbebọn yii kuro ni agbegbe yẹn fun wa.

"Laarin oṣu kan, n ko fẹ gbọ nipa awọn ọdaran yii mọ ni Kainji Dam."

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Oluyede ni gbogbo iṣẹlẹ ti yoo da alaafia lamu lorilẹede Naijiria ni ijọba ko ni fi aaye gba.

"Mo n sọ fun yin pe laarin oṣu kan, nnkan yoo ti yi pada."

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Ni ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori awọn agbebọn to ṣe ikọlu si ibudokọ kan ni Ilesha Baruba, nijọba ibilẹ Baruten, ipinlẹ Kwara ti wọn si ṣekupa eeyan mẹfa.

Bakan naa ni awọn eeyan meji mii tun faragba ọta ibọn ninu ikọlu naa ti wọn si wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Agbẹnusọ ọlọpaa Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Iṣẹgun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Ejire-Adeyemi sọ pe ni nnkan bii aago mẹsan-an abọ alẹ ọjọ Aje, ọjọ kọkanlẹlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 lawọn agbebọn naa yawọ ibudokọ naa tí wọn sì ṣina ibọn bolẹ sawọn eeyan to n gbafẹ ni ile gbafẹ kan to wa ni ẹgbẹ ibudokọ naa.

Ikọlu naa waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn agbebọn ki gbogbo eero inu ọkọ kan gbe lọ.

Iroyin sọ pe, ilu Abuja ni ọkọ akero Sienna ọhun ti n bọ, ko to o bọ si ọwọ awọn oṣika ẹda naa nipinlẹ Kwara.

Wọn ko tii ri awọn eeyan ọhun gba jade.