Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ẹgbẹ́ agbébọn Mahmuda tó ń ṣoro nípìnlẹ̀ Kwara

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbebọn kan tun ti gbode bayii lorilẹede Naijiria. Orukọ ẹgbẹ naa ni Mahmuda.
Mahmuda ni iroyin ni wọn ti n sọṣẹ, ti wọn si n fa ijamba fun awọn eeyan ijọba ibilẹ Kaiama ati Baruten nipinlẹ Kwara.
Ọpọ eeyan lo ti farapa, ti awọn mii si padanu ẹmi sọwọ ẹgbẹ yii.
Iwadii ni, awọn agbebọn yii ni ibudo ni Kainji Lake National Park, to si jẹ pe lati ibẹ ni wọn ti n kọlu awọn agbegbe ni ijọba ibilẹ mejeeji ati ni awọn agbegbe kan nipinlẹ Niger.
Ni bayii, ọpọ awọn eeyan ti ọrọ yii kan ni wọn ti n kuro ni awọn agbegbe ti iṣẹlẹ ikọlu yii ti n waye ti wọn si n lọ si ibi ti alaafia wa lati bọ lọwọ ogun Mahmuda.
Awọn olugbe agbegbe naa sọ pe, saaju ni awọn ọmọ ẹgbẹ agbebọn yii ti ni ibudo si ijọba ibilẹ Kaiama ati Baruten, ti wọn ko si ṣe ohunkohun fun awọn eeyan.
Olugbe kan to ba awọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe ,laipẹ yii ni ẹgbẹ Mahmuda wa bẹrẹ si ni gbe ikọlu ka awọn eeyan mọle, ti wọn si n rin kiri ilu pẹlu ibọn ati awọn ohun ija.
Ni ṣe ni wọn tu n mu awọn araalu, ti wọn si n ṣekupa awọn kan.
"O ti to ọdun mẹta bayii ti wọn ti wa ni ayika wa."
O fikun pe, "nigba ti wọn bẹrẹ, ko si ẹnikẹni to le lọ si oko mọ. Ẹru n ba wa, ida aadọta awọn araalu lo ti ṣalọ kuro ni ilu."
Bakan naa, ohun ti a tun ri gbọ ni pe, ẹgbẹ yii ti fofin ọwọ ara wọn de araalu Kaiama ati Baruten pe wọn ko gbọdọ lọ si oko mọ.
"Ni bayii, ida 95 awọn eeyan wa ti wọn jẹ agbẹ ni wọn ni wọn ko gbọdọ lọ si oko. Bayii, a n koju iku, kii ṣe ebi."
Onimọ nipa eto aabo, Ọmọwe Kabir Adamu, ba BBC sọrọ, o ni pẹlu oye rẹ nipa igbesunmọmi, ẹgbẹ Mahmuda jẹ ẹya ẹgbẹ ISWAP.
"Igbagbọ wọn ati awọn nnkan ti wọn n ṣe lo jẹ nnkankan naa."
O ṣalaye pe ọpọ ẹgbẹ naa ti ileeṣẹ Ologun gbe ogun ti ninu igbo nipinlẹ Kwara, ni wọn ti n ṣarajọ dide pada.
"Ti ẹ ba ranti, ẹgbẹ kan wa ti wọn n pe ni Darussalam ko to di pe ileeṣẹ Ologun le wọn kuro ni agbegbe naa."
Onimọ nipa eto aabo ọhun, ni o ṣe koko lati dide si awọn agbebọn yii, ki wọn si fi iya ofin jẹ wọn ni kiakia.
Wo iye igba ti ikọlu ti waye ni Kwara ninu oṣu Kẹrin
Laipẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori awọn agbebọn to ṣe ikọlu si ibudokọ kan ni Ilesha Baruba, nijọba ibilẹ Baruten, ipinlẹ Kwara ti wọn si ṣekupa eeyan mẹfa.
Bakan naa ni awọn eeyan meji mii tun faragba ọta ibọn ninu ikọlu naa ti wọn si wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.
Agbẹnusọ ọlọpaa Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Iṣẹgun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Ejire-Adeyemi sọ pe ni nnkan bii aago mẹsan-an abọ alẹ ọjọ Aje, ọjọ kọkanlẹlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2025 lawọn agbebọn naa yawọ ibudokọ naa tí wọn sì ṣina ibọn bolẹ sawọn eeyan to n gbafẹ ni ile gbafẹ kan to wa ni ẹgbẹ ibudokọ naa.
Bakan naa, ni ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin ni ariwo tun sọ ni opopona Obbo-Aiyegunle si Osi, ijọba ibilẹ Ekiti ni ipinlẹ Kwara bawọn ajinigbe tun ṣe ṣọṣẹ ni opopona naa.
Ọkọ Sienna kan to ko ero lati ilu Abuja to n lọ si Offa ni awọn ajinigbe naa ṣe ikọlu si gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ.
Ọkan lara awọn olugbe ilu Obbo Aiyegunle to ba BBC News Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Layọde salaye pe awọn ajinigbe naa ko awọn agbalagba to wa ninu ọkọ naa lọ amọ ti wọn fi awọn ọmọde silẹ.
O ni awọn ọmọde to wa ninu ọkọ ọhun, amọ ti wọn ji awọn obi wọn gbe, lọ ọ sun lọdọ alaga ijọba ibilẹ Ekiti mọju ọjọ Aiku.















