Ìdí pàtàkì tí àwọn pápákọ̀ ọkọ̀ òfurufú ṣe n gbẹ́kẹ̀lé àjọ tó ń wòye ojú ọjọ́

Aworan baalu loju ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Priya Sippy
    • Role, BBC News Africa
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ eeyan ni ko le rinrin ajo lawọn papakọ ofurufu lorilẹede Naijiria laarin ọsẹ yii, lẹyin táwọn oṣiṣẹ ajọ Nimet to n woye oju ọjọ gunle iyanṣẹlodi lati fi ẹhonu han lori owo oṣu ti wọn ni ijọba n jẹ wọn.

Ọpọ baalu lo ni idaduro lati fo nigba t'awọn mii ko tiẹ le fo rara lawọn papakọ ofurufu ilu Eko, Kano ati Abuja.

Awọn oṣiṣẹ Nimet ṣe iwọde niluu Eko nbi ti wọn ti gbe awọn beba dani ti wọn kọ oriiṣiriṣii ọrọ si lara bíi "Láì mọ bi oju ọjọ ṣe rí, baalu kò le fo."

Bi ileeṣẹ ọkọ ofurufu United Nigeria ṣe ni awọn yoo lo ọna mii lati mọ bí oju ọjọ ṣe rí, ileeṣẹ ọkọ ofurufu Airpeace paṣẹ idaduro Irinajo ọkọ ofurufu nile iṣẹ naa l'Ọjọbọ.

Awọn oṣiṣẹ Nimet ti fopin si iyanṣẹlodi ọhun lẹyìn ti minisita to n ri ileeṣẹ ọkọ ofurufu, Festus Keyamo, ṣe ipade pẹlu wọn l'Ọjọbọ.

Wọnyii ni koko mẹta ti ileeṣẹ to n woye oju ọjọ fi ṣe pataki fún irinna ọkọ ofurufu:

Aabo

Bo tilẹ jẹ pe baalu le fo ti oju ọjọ ko ba dara to, amọ, ajọ to n woye bi oju ọjọ ṣe rí lo le sọ fawọn awakọ baalu awọn ewu to le wa bii kurukuru, yinyin, ara ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Yinyin pẹlu kurukuru ma le l'agbara lati ja baalu lulẹ, amọ, o le jẹ k'awọn ero inu baalu ni ipalara koda ẹlòmíràn le gba ibẹ ku.

Awọn awakọ baalu maa n lo nkan t'awon ajọ to n woye oju ọjọ ba sọ fun wọn lati kọja ti ewu le wa tabi ki wọn tiẹ fagile Irinajo wọn patapata.

Ojo to n san ara wọpọ lorilẹede Naijiria, eyi lo jẹ ki itọsọna ajọ to n woye oju ọjọ ṣe pataki fawọn awakọ baalu.

George Delanjian to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa iwoye oju ọjọ l'Amerika sọ pe ara le san ko ṣakoba fun ọkọ ofurufu, awọn onwoye oju ọjọ lo mọ asiko ti eyi yoo ṣẹlẹ gan.

Aworan awọn oṣiṣẹ Nimet to n ṣewọde l"Eko.

Lilọ deedee irinajo

Ohun tí ajọ to n woye oju ọjọ ba sọ ṣe pataki fun awakọ baalu to n mura silẹ lati fo.

Bi oju ọjọ ṣe gbona sí, kurukuru at'awọn nnkan mii le sọ iye epo ti baalu yoo nilo lati de ibi to n lo.

Ọrọ tí ajọ to n woye oju ọjọ ba sọ lori iji le wulo fun awakọ baalu lati le de ibi to n lọ ni kiakia.

Eyi tun le sọ papakọ ofurufu mii ti baalu tun le ba lasiko pajawiri.

Simon King to jẹ onwoye oju ọjọ pẹlu BBC sọ pe ajọ to n sọ bi oju ọjọ ṣe rí maa sọ fun awọn papakọ ofurufu ni wakati kọọkan iyatọ to ti wà loju ọjọ.

Nítorí naa, gbogbo awakọ baalu lo nilo lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ to n woye oju ọjọ lati le rinrin ajo.

Imurasilẹ Irinajo ọkọ ofurufu

Bi ọrọ oju ọjọ ti ṣe pataki fáwọn awakọ baalu loju ofurufu naa lo se pataki fun imurasilẹ wọn lori ilẹ ni papakọ ofurufu.

Ajọ to n woye oju ọjọ maa n sọ fawọn awakọ baalu ohun ti wọn nilo lati mọ nipa oju ọjọ fun ati gbera ati lati balẹ bakan naa.

Nnkan ti awọn oṣiṣẹ to ni woye oju ọjọ ba sọ lawọn awakọ baalu maa n lo lati mọ bi wọn ṣe lè sare tó ki wọn to gbera.

Ohun tawon oṣiṣẹ to n woye oju ọjọ ba sọ naa ni awọn awakọ baalu yoo fi mọ igba ti wọn ni lati da epo mii sinu baalu.

Fun àpẹẹrẹ, ti ara ba n san ti mọnamọna si n kọ loju ọrun, wọn o gbọdọ da epo sinu baalu lasiko naa.