Ǹ jẹ́ ò ń fọ nǹkan ìmumi rẹ dáadáa bó ṣe yẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Jessica Brown
- Role, BBC Future
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ni igbakugba ti o ba mu omi lati inu 'water bottle' rẹ, o n tu awọn kokoro ti a ko le fi oju ri Bacteria sinu rẹ, ti wọn si le di ọpọlọpọ laarin ọjọ kan. Eyi ni ohun ti awọn onimọ sayẹnsi ni o le ṣe nipa rẹ.
Carl Behnke ni oun ma n ro bi ''Water Bottle" ti oun ma n tun lo ṣe mọ to. O ni nigba ti oun gbiyanju lati fi pepa nu, ohun to jade ninu rẹ ya oun lẹnu.
"Pepa naa mọ funfun ṣugbọn nigba ti mo fi nu "Water bottle mi, o dọti," Behnke, onimọ nipa aabo ounjẹ ni fasiti Purdue ni Indiana lorilẹede US. "Mo ri pe yiyọ ti mo n ri pe o n yọ nibi oke kọpu naa ki n ṣe nitori nnkan to wa ninu rẹ ṣugbọn nitori awọn kokoro bacterial to ti sarajọ.
Igbesẹ rẹ to kan ni lati ṣe iwadii. Behnke ati akẹgbẹ bere fun ọpọ water bottle ti yoo wulo fun wọn fun iwadii lati mọ bi wọn ṣe mọ to.
"Ohun kan to da yatọ ninu iwadii naa ni pe ọpọ eeyan ko fẹ mọ abajade iwadii wọn, Behnke ranti. " Iwadii naa fihan pe ọpọ awọm 'Water Bottle' lo kun fun kokoro Bacteria.
Bo ti lẹ jẹ pe 'Water Bottle' jẹ ohun kan ti a ma di mu kiri, ti a si ma fi omi inu rẹ rẹngbẹ lorekore, o lewu si ilera wa. Ṣe ka ju wọn nu tabi a le mojuto awọn ewu rẹ.
Ki gan lo wa ninu awọn 'Water Bottle' ti a n tun lo yii?
Bi o se da bi pe o dara, omi lati inu ẹrọ omi ile idana wa le ko kokoro jọ. Eyi lo jẹ pe fifi omi silẹ ninu 'Water bottle' wa lẹ jẹ ki awọn kokoro yii ma ṣara jọ, Primrose ṣalaye, ọjọgbọn ni fasiti Leicester niluu UK.
Kokoro Bacteria le fa aisan si ara eeyan gẹgẹ bii Freestone ṣe ṣalaye, to si le di ilọpo ni yara to ba gbona ni iwọnba 20C (68F).
"Bi omi ba ṣe pẹ ninu 'Water Bottle' ti wọn gbe pamọ sinu yara naa ni Bacteria yoo ṣe ma dagba si.
Iwadii kan ti wọn ṣe ni Singapore, ti wọn lo omi taapu ti wọn gbe kana- to yẹ ko ṣekupa awọn kokoro naa- ṣugbọn o jẹ oun iyalẹnu pe awọn kokoro yii le ma pọ si ninu omi ti wọn ba ti wa fun igba pipẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọna kan ti eeyan fi le mu adikun ba idagbasoke awọn kokoro bacteria ni lati fi awọn omi yii pamọ sinu ẹrọ amu nnkan tutu. Freestone ni, eyi ko fi bẹ da igbasoke wọn duro.
Ẹwẹ ọpọ kokoro omi yii lo wa lati inu omi fun ra rẹ, ọpọ wọn lo jẹyọ lati ọwọ eeyan to n mu omi naa. Boya o mu lọ si ibi iṣẹ, ile ise ere idaraya, tabi o fi pamọ sile, ita 'Water bottle' rẹ kun ọpọ kokoro, pẹlu koko aifojuri to wa ni ẹnu ni gbakugba to ba mu omi, Freeston sọ.
Eeyan to n lo 'Water bottle' ti wọn ko ki n fọ ọwọ ni orekore ma n ko ọpọ kokoro bi E.cli kiri, Freestone ṣalaye.
"Kokoro igbẹ bi E.coli wa lati ọwọ wa, to si ma de ẹnu wa, ti a ko ba fọwọ wa lẹyin igbọnsẹ,; O sọ.
Ọna miiran ti o le fi fa kokoro Bacteria ni ki o fi nnkan miiran sinu omi 'Water bottle' rẹ yatọ si omi to mọ- ohunkohun to ba ni suga le fa kokoro yii, Freestone sọ
"Nnkan ti ko ba ki n ṣe omi to ba fi sinu ''Water Bottle' rẹ jẹ ọrun fun kokoro bacteria ati fungi.
"Ti o ba mu miliki ku sinu kọpu, to si fi silẹ fun ọpọ wakati, o ri awọn nnkan nibẹ ti o ba danu. Kokoro Bacteria fẹ milki pupọ, Freestone sọ.
Bawo ni Bacteria ṣe le ṣe akoba fun wa?
Kokoro bacteria yii wa ka, ninu ilẹ, ninu atẹgun ati ninu ara ṣugbọn o ṣe koko lati mọ pe ọpọ awọn kokoro yii ni wọn ko ni ijamba tabi iranlọwọ.
Ẹw wọn ni awọn ero kan ninu to le jẹ ki eeyan ṣe aisan.
Ọpọ Kokoro microbes ni ko le ṣe ijamba fun eeyan ṣugbọ agọ ara wa le tan si awọn aisan kan lati ara wọn, Freestone ṣalaye
Ti kokoro funji ati mould ba n dagba ninu 'Water bottle' rẹ, o le ṣokunfa awọn apẹrẹ aisan kọkan
Bawo le ṣe le fọ 'Water bottle' wa mọ ka le tun lo
Fun Behnke, o ni gbogbo igba ni oun ma fọ 'water bottle' oun pẹlu omi gbona ṣugbọn ko fi bẹ se nkankan.
Lẹyin iwadii fifi pepa nu ike omi naa eyi to ṣafihan bi inu ike naa ṣe dọti to, ọpọ ṣo Behnke pe awọn ma n pin Water bottle wọn pẹlu ọpọ eeyan, ti ida ogoji wọn si ni awọn ko ki n fọ ike omi naa lẹyin lilo.
Freestone ni awọn eeyan to ma n fi saka fọ ike omi water bottle wọn ni wọn ko ki ni kokoro Bacteria.
Freestone ati awọn akẹgbẹ gba ni imọran pe lilo ọsẹ ifọ abọ le pa ọpọ awọn kokoro yii
Iwadii Freestone tun ṣafihan pe ọpọ ike omi to n tii ninu ati awọn ohum mimu to ni suga ma ni ọpọ kokoro Bacteria ju ti omi lasan lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Freestone ni fifọ ike omi 'Water Bottle' lorekore le jẹ ki adikun ba kokoro bacteria ninu ike.
Fifọ ike pẹlu omi tutu ko le to lati pa awọn kokoro yii, o gba ni imọran pe ki awọn eeyan ma lo omi gbigbona nitori o le ṣekupa awọn kokoro pẹlu ọsẹ, ti wọn si jẹ ko gbẹ fun isẹju mẹta.
"Fọ ike omi water bottle naa lẹyin to ba lo tan- ni ọpọ igba ni ọsẹ. Freestoneṣalaye ki awọn eeyan ma duro ti ike omi wọn ba run.
"Ti ike omi rẹ ba ti n ru, o ti asiko lati sọ ike naa nu," o sọ.
N jẹ ike omi kan Water Bottle wa to yẹ ko yago?
Bo ti lẹ jẹ pe iwadii fihan pe awọn kokoro bacteria kun ninu ike ju ti onirin lọ.
Freestone ni ike omi to ba ṣe fọ ni kiakia lo da ju lati lo.
O ṣe koko ki eeyan fọ gbogbo ara ike pata .
To si gba awọn eeyan ni imọran pe ki wọn lo water bottle oni irin.
"Ike omi onike ni wọn fi ọpọ kẹmika pelo, to si n fa ki awọn ki kokoro naa ṣarajọ," Amit Abraham, ọjọgbọn ni ile ẹkọ iṣegun ni Qater.












