Ṣé lóòtọ́ ni Gómìnà Adeleke ń gbèrò láti bẹ́ kìjà kúrò ní PDP lọ sí APC?

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, ademola adeleke/x

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọwọja afẹfẹ iṣipopada ẹgbẹ oṣelu n fẹ lu awọn eekan oloṣelu kaakiri Naijiria bayii ti ọpọ awọn oloṣelu n yọ foki lati ẹgbẹ oṣelu kan si omiran.

Nibayii ariwo to tun n kaakiri ni pe boya lara awọn gomina to n gbero lati fi ẹgbẹ oṣelu wọn silẹ ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke.

Amọṣa awọn ọmọ igbimọ iṣejọba ni ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ọrọ apar ani irufẹ ọrọ bẹẹ nitori pe gomina Adeleke ko nibi re rara ju ẹgbẹ oṣelu PDP to wa.

Nibi ipade pẹlawọn akọroyin kan ti wọn ṣe lọ̀jọ Aje ni ilu Oṣogbo, awọn ọmọ igbimọ iṣakoso ijọba ni ipinlẹ Ọṣun ṣalaye pe irọ nla ni ọrọ to n ja ranyinranyin kaakiri pe o ṣeeṣe ki Gomina Ademọla Adeleke naa bẹ kija kuro lẹgbẹ oṣelu PDP lọ dara pọ mọ Aarẹ Tinubu lẹgbẹ oṣelu APC.

Wọn ni koda ko si eto kankan to n lọ labẹnu layika gomina naa lati gbe iru igbesẹ bẹẹ

Awọn ọmọ igbimọ iṣakoso naa tun ṣalaye pe awọ̀n pẹlu duro digbi lẹyin gomina Adeleke lati le mu awọn ileri iṣejọba tiwantiwa to ṣe fun awọn eeyan ipinlẹ naa ṣẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Họnọrebu Dosu Babatunde to duro gẹgẹbi akọwe fun awọn ọmọ igbimọ iṣakoso ijọba ipinlẹ naa ṣalaye pe awọn ti ko ni arojinlẹ ninu irinajo oṣelu lo le sọ pe awọn n fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ l si ẹgbẹ oṣelu miran.

Ẹgbẹ Oṣelu APC ni Gomina Adeleke pẹlu ti kuro wa si ẹgbẹ oṣelu PDP lẹyin iku ẹgbọn rẹ, Isiaka Adeleke to jẹSẹnetọ lẹgbẹ oṣelu naa nigba naa lọhun.

Ṣaaju ni gomina ipinlẹ Delta, Sheriff Oborevwori atawọn ololufẹ rẹ ti fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ gba APC lọ.